Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?
Ṣé o rò pé . . .
-
ìfẹ́ ni?
-
àbí owó?
-
àbí nǹkan míì?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ
Wàá rí ìfẹ́ tòótọ́.—Éfésù 5:28, 29.
Wàá gbádùn ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.—Éfésù 5:33.
Ọkàn rẹ á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.—Máàkù 10:6-9.
ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:
-
Ọlọ́run ló dá ìdílé sílẹ̀. Bíbélì sọ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni “gbogbo ìdílé . . . ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:14, 15) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa?
Rò ó wò ná: Tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn kan, tó o sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n fi sè é, ọwọ́ ta ló yẹ kó o ti béèrè? Ṣebí ọwọ́ ẹni tó sè é ni?
Bákan náà, tá a bá fẹ́ mọ àwọn ohun tó máa mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí, torí pé òun ló dá ìdílé sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24.
-
Ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún. Àwọn ìdílé tó bá jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. ‘Nítorí ó ń bójú tó wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Ohun tó dáa ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sì máa ń wúlò nígbà gbogbo!—Òwe 3:5, 6; Àìsáyà 48:17, 18.
RÒ Ó WÒ NÁ
Báwo lo ṣe lè jẹ́ ọkọ rere, aya rere tàbí òbí rere?
Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé ÉFÉSÙ 5:1, 2 àti KÓLÓSÈ 3:18-21.