Àìsáyà 63:1-19

  • Jèhófà máa gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè (1-6)

  • Bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nígbà àtijọ́ (7-14)

  • Àdúrà ìrònúpìwàdà (15-19)

63  Ta ló ń bọ̀ láti Édómù+ yìí,Tó ń bọ̀ láti Bósírà,+ tó wọ aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn yòò,*Tó wọ aṣọ tó dáa gan-an,Tó ń yan bọ̀ nínú agbára ńlá rẹ̀? “Èmi ni, Ẹni tó ń fi òdodo sọ̀rọ̀,Ẹni tó lágbára gan-an láti gbani là.”   Kí ló dé tí aṣọ rẹ pọ́n,Kí ló sì dé tí ẹ̀wù rẹ dà bíi ti ẹni tó ń tẹ àjàrà ní ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì?+   “Èmi nìkan ni mo tẹ wáìnì nínú ọpọ́n. Ìkankan nínú àwọn èèyàn náà ò sí lọ́dọ̀ mi. Mò ń fi ìbínú tẹ̀ wọ́n ṣáá,Mo sì ń fi ìrunú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.+ Ẹ̀jẹ̀ wọn ta sára ẹ̀wù mi,Ó sì ti yí gbogbo aṣọ mi.   Torí pé ọjọ́ ẹ̀san wà lọ́kàn mi,+Ọdún àwọn tí mo tún rà sì ti dé.   Mo wò, àmọ́ kò sẹ́ni tó ṣèrànwọ́;Ẹnu yà mí pé kò sẹ́ni tó tì mí lẹ́yìn. Apá mi wá mú ìgbàlà* wá fún mi,+Ìbínú mi sì tì mí lẹ́yìn.   Mo fi ìbínú tẹ àwọn èèyàn mọ́lẹ̀,Mo mú kí wọ́n mu ìrunú mi yó,+Mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sórí ilẹ̀.”   Màá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ṣe torí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ ká yìn,Torí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa,+Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tó ti ṣe fún ilé Ísírẹ́lì,Nínú àánú rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ tó lágbára.   Torí ó sọ pé: “Ó dájú pé èèyàn mi ni wọ́n, àwọn ọmọ tí kò ní di aláìṣòótọ́.”*+ Ó wá di Olùgbàlà wọn.+   Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.+ Ìránṣẹ́ òun fúnra rẹ̀* sì gbà wọ́n là.+ Ó tún wọn rà nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìyọ́nú rẹ̀,+Ó gbé wọn sókè, ó sì rù wọ́n ní gbogbo ìgbà àtijọ́.+ 10  Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.+ Ó wá di ọ̀tá wọn,+Ó sì bá wọn jà.+ 11  Wọ́n rántí àwọn ìgbà àtijọ́,Àwọn ọjọ́ Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀: “Ẹni tó mú wọn jáde látinú òkun dà,+ àwọn àti àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?+ Ẹni tó fi ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀ sínú rẹ̀ dà,+ 12  Ẹni tó mú kí apá Rẹ̀ ológo bá ọwọ́ ọ̀tún Mósè lọ,+Ẹni tó pín omi níyà níwájú wọn,+Kó lè ṣe orúkọ tó máa wà títí láé fún ara rẹ̀,+ 13  Ẹni tó mú kí wọ́n rìn gba inú omi tó ń ru gùdù,*Tó fi jẹ́ pé wọ́n rìn láìkọsẹ̀,Bí ẹṣin ní ìgbèríko?* 14  Bí ìgbà tí ẹran ọ̀sìn bá ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀,Ẹ̀mí Jèhófà mú kí wọ́n sinmi.”+ Bí o ṣe darí àwọn èèyàn rẹ nìyí,Kí o lè ṣe orúkọ tó gbayì* fún ara rẹ.+ 15  Wo ilẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí iLáti ibùgbé rẹ mímọ́ àti ológo* tó ga. Ìtara rẹ àti agbára rẹ dà,Ìyọ́nú rẹ tó ń ru sókè*+ àti àánú rẹ dà?+ A ti fà wọ́n sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi. 16  Torí ìwọ ni Bàbá wa;+Bí Ábúráhámù ò tiẹ̀ mọ̀ wá,Tí Ísírẹ́lì ò sì dá wa mọ̀,Ìwọ Jèhófà, ni Bàbá wa. Olùtúnrà wa látìgbà àtijọ́ ni orúkọ rẹ.+ 17  Jèhófà, kí ló dé tí o gbà ká* rìn gbéregbère kúrò ní àwọn ọ̀nà rẹ? Kí ló dé tí o gbà kí* ọkàn wa le, tí a ò fi bẹ̀rù rẹ?+ Pa dà, torí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,Àwọn ẹ̀yà ogún rẹ.+ 18  Ó jẹ́ ti àwọn èèyàn mímọ́ rẹ fúngbà díẹ̀. Àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.+ 19  Ó pẹ́ gan-an tí a ti dà bí àwọn tí o kò ṣàkóso wọn rí,Bí àwọn tí a ò fi orúkọ rẹ pè rí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “aṣọ rẹ̀ pọ́n yòò.”
Tàbí “ìṣẹ́gun.”
Tàbí “já sí èké.”
Tàbí “Áńgẹ́lì iwájú rẹ̀.”
Tàbí “ibú omi.”
Tàbí “nínú aginjù?”
Tàbí “tó lẹ́wà.”
Tàbí “ẹlẹ́wà.”
Ní Héb., “Inú rẹ lọ́hùn-ún tó ń ru sókè.”
Tàbí “mú ká.”
Ní Héb., “mú kí.”