Sí Àwọn Ará Éfésù 6:1-24
6 Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu+ nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.
2 “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ,”+ èyí ni àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí:
3 “Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ,* kí o sì lè pẹ́ láyé.”
4 Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa mú àwọn ọmọ yín bínú,+ kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa tọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí+ àti ìmọ̀ràn* Jèhófà.*+
5 Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn ọ̀gá yín* lẹ́nu,+ pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nínú òótọ́ ọkàn, gẹ́gẹ́ bíi sí Kristi,
6 kì í ṣe nígbà tí wọ́n bá ń wò yín nìkan, torí kí ẹ lè tẹ́ èèyàn lọ́rùn,*+ àmọ́ bí ẹrú Kristi, tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn.*+
7 Ẹ máa hùwà rere bí ẹ ṣe ń ṣẹrú, bíi pé fún Jèhófà,*+ kì í ṣe fún èèyàn,
8 nítorí ẹ mọ̀ pé, ohun rere èyíkéyìí tí kálukú bá ṣe, ó máa gbà á pa dà lọ́dọ̀ Jèhófà,*+ onítọ̀hún ì báà jẹ́ ẹrú tàbí òmìnira.
9 Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa hùwà sí wọn lọ́nà kan náà, ẹ má ṣe máa halẹ̀ mọ́ wọn, torí ẹ mọ̀ pé Ọ̀gá wọn àti tiyín wà ní ọ̀run,+ kì í sì í ṣojúsàájú.
10 Paríparí rẹ̀, ẹ máa gba agbára+ nínú Olúwa àti nínú títóbi okun rẹ̀.
11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun+ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ lè dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè* Èṣù;
12 nítorí a ní ìjà* kan,+ kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, àmọ́ ó jẹ́ pẹ̀lú àwọn alákòóso, pẹ̀lú àwọn aláṣẹ, pẹ̀lú àwọn alákòóso ayé òkùnkùn yìí, pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú+ ní àwọn ibi ọ̀run.
13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra ogun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀,+ kí ẹ lè jà ní ọjọ́ burúkú náà, lẹ́yìn tí ẹ bá sì ti ṣe ohun gbogbo parí, kí ẹ lè dúró gbọn-in.
14 Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ fi òtítọ́ di inú yín lámùrè,+ kí ẹ sì gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀,+
15 pẹ̀lú ẹsẹ̀ yín tí a wọ̀ ní bàtà, kí ẹ lè fi ìmúratán kéde ìhìn rere àlàáfíà.+
16 Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan yìí, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́,+ tí ẹ ó fi lè paná gbogbo ọfà* oníná ti ẹni burúkú náà.+
17 Bákan náà, ẹ gba akoto* ìgbàlà+ àti idà ẹ̀mí, ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,+
18 pẹ̀lú onírúurú àdúrà + àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, ẹ máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo nítorí gbogbo àwọn ẹni mímọ́.
19 Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere,+
20 èyí tí mo torí rẹ̀ jẹ́ ikọ̀+ tí a fi ẹ̀wọ̀n dè, kí n lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bó ṣe yẹ.
21 Kí ẹ lè mọ̀ nípa mi àti bí mo ṣe ń ṣe sí, Tíkíkù,+ arákùnrin ọ̀wọ́n, tó tún jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́ nínú Olúwa, yóò sọ gbogbo rẹ̀ fún yín.+
22 Torí èyí ni mo ṣe ń rán an sí yín, kí ẹ lè mọ bí a ṣe ń ṣe sí, kí ó sì lè tu ọkàn yín lára.
23 Kí àwọn ará ní àlàáfíà àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ Baba àti Jésù Kristi Olúwa.
24 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tó ní ìfẹ́ tí kò lè ṣá fún Olúwa wa Jésù Kristi.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Kí o lè láásìkí.”
^ Tàbí “ẹ̀kọ́; ìtọ́sọ́nà.” Ní Grk., “fífi ọkàn sí.”
^ Ní Grk., “ọ̀gá yín nípa tara.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Ní Grk., “kì í ṣe àrójúṣe bíi ti àwọn tó máa ń fẹ́ wu èèyàn.”
^ Tàbí “ètekéte.”
^ Ní Grk., “gídígbò.”
^ Tàbí “ohun ọṣẹ́.”
^ Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.