Òwe 5:1-23
5 Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n mi.
Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí òye mi,+
2 Kí o bàa lè dáàbò bo làákàyè rẹKí o sì fi ètè rẹ dáàbò bo ìmọ̀.+
3 Nítorí ètè obìnrin oníwàkiwà* ń kán tótó bí afárá oyin,+Ọ̀rọ̀* rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ.+
4 Àmọ́, nígbẹ̀yìn ó korò bí iwọ*+Ó sì mú bí idà olójú méjì.+
5 Àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ikú.
Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí Isà Òkú.*
6 Kì í ronú nípa ọ̀nà ìyè.
Ó ti ṣìnà, kò mọ ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí.
7 Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí miẸ má sì kúrò nínú ohun tí mò ń sọ.
8 Jìnnà réré sí i;Má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀,+
9 Kí o má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíì+Tàbí kí o fi ọ̀pọ̀ ọdún kórè ohun tó burú;+
10 Kí àwọn àjèjì má bàa fa ọrọ̀* rẹ gbẹ,+Kí àwọn ohun tí o ṣiṣẹ́ kára fún sì lọ sí ilé àjèjì.
11 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹNígbà tí okun rẹ bá tán, tí ẹran ara rẹ sì gbẹ+
12 Tí o sì sọ pé: “Ẹ wo bí mo ṣe kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
Ẹ wo bí ọkàn mi ti ṣàìka ìbáwí sí!
13 Mi ò fetí sí ohùn àwọn tó ń kọ́ miMi ò sì tẹ́tí sí àwọn olùkọ́ mi.
14 Mo ti dé bèbè ìparunNí àárín ìjọ lápapọ̀.”*+
15 Mu omi látinú àmù rẹÀti omi tó ń sun* látinú kànga rẹ.+
16 Ṣé ó yẹ kí ìsun omi rẹ tú síta,Kí ìṣàn omi rẹ sì tú sí àwọn ojúde ìlú?+
17 Jẹ́ kí wọ́n wà fún ìwọ nìkan,Kì í ṣe fún ìwọ àti àwọn àjèjì.+
18 Kí orísun omi* rẹ ní ìbùkún,Kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ,+
19 Abo àgbọ̀nrín tó fani mọ́ra, ewúrẹ́ rírẹwà orí òkè.+
Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ máa dá ọ lọ́rùn* nígbà gbogbo.
Kí ìfẹ́ rẹ̀ máa gbà ọ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+
20 Torí náà, ọmọ mi, kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí obìnrin oníwàkiwà* gbà ọ́ lọ́kànTàbí tí wàá fi gbá àyà obìnrin oníṣekúṣe* mọ́ra?+
21 Nítorí àwọn ọ̀nà èèyàn wà níwájú Jèhófà;Ó ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+
22 Àwọn àṣìṣe ẹni burúkú ló ń dẹkùn mú un,Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ á sì wé mọ́ ọn bí okùn.+
23 Ó máa kú nítorí kò gba ìbáwíÁ sì ṣìnà nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “Dẹ etí rẹ.”
^ Ní Héb., “Ẹnu.”
^ Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “agbára.”
^ Ní Héb., “Ní àárín àpéjọ àti ìjọ.”
^ Tàbí “omi tó mọ́ lóló.”
^ Tàbí “ìsun omi.”
^ Tàbí “pa ọ́ bí ọtí.”