Òwe 6:1-35
6 Ọmọ mi, tí o bá ti ṣe onídùúró* fún ọmọnìkejì rẹ,+Tí o bá ti bọ àjèjì lọ́wọ́,*+
2 Tí ìlérí rẹ bá ti dẹkùn mú ọ,Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ bá ti mú ọ,+
3 Ohun tí wàá ṣe nìyí, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ sílẹ̀,Nítorí o ti kó sọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ:
Lọ rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì tètè bẹ ọmọnìkejì rẹ.+
4 Má ṣe jẹ́ kí oorun kun ojú rẹ,Má sì jẹ́ kí ìpéǹpéjú rẹ tòògbé.
5 Gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tó bọ́ lọ́wọ́ ọdẹ,Àti bí ẹyẹ tó bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
6 Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;+Kíyè sí àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì gbọ́n.
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, aláṣẹ tàbí alákòóso,
8 Ó ń ṣètò oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn,+Ó sì ń kó oúnjẹ rẹ̀ jọ nígbà ìkórè.
9 Ìgbà wo ni ìwọ ọ̀lẹ máa dùbúlẹ̀ dà?
Ìgbà wo lo máa dìde lójú oorun rẹ?
10 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,+
11 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+
12 Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá ń rìn kiri tòun ti èké ọ̀rọ̀;+
13 Bó ṣe ń ṣẹ́jú,+ bẹ́ẹ̀ ló ń fi ẹsẹ̀ sọ̀rọ̀, tó sì ń nàka.
14 Pẹ̀lú ọkàn burúkú,Ó ń gbèrò ibi ní gbogbo ìgbà,+ ó sì ń dá awuyewuye sílẹ̀.+
15 Torí náà, àjálù rẹ̀ yóò dé lójijì;Ojú ẹsẹ̀ ni yóò wó lulẹ̀, kò sì ní ṣeé wò sàn.+
16 Ohun mẹ́fà wà tí Jèhófà kórìíra;Bẹ́ẹ̀ ni, ohun méje tó jẹ́ ohun ìríra fún un:*
17 Ojú ìgbéraga,+ ahọ́n èké+ àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+
18 Ọkàn tó ń gbèrò ìkà+ àti ẹsẹ̀ tó ń sáré tete láti ṣe ibi,
19 Ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́+Àti ẹni tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+
20 Ọmọ mi, pa àṣẹ bàbá rẹ mọ́,Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+
21 So wọ́n mọ́ ọkàn rẹ nígbà gbogbo;Dè wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
22 Nígbà tí o bá ń rìn, á máa darí rẹ;Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, á máa ṣọ́ ẹ;Nígbà tí o bá sì jí, á máa bá ẹ sọ̀rọ̀.*
23 Nítorí àṣẹ jẹ́ fìtílà,+Òfin jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè.+
24 Wọ́n máa dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ obìnrin burúkú,+Lọ́wọ́ ahọ́n obìnrin oníṣekúṣe* tó ń sọ ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra.+
25 Má ṣe jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́+Tàbí kí o jẹ́ kó fi ojú rẹ̀ tó ń fani mọ́ra mú ọ,
26 Ní tìtorí aṣẹ́wó, èèyàn á di ẹni tí kò ní ju búrẹ́dì kan ṣoṣo lọ,+Ní ti obìnrin alágbèrè, ẹ̀mí* tó ṣeyebíye ló fi ń ṣe ìjẹ.
27 Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí àyà rẹ̀, kí ẹ̀wù rẹ̀ má sì jó?+
28 Tàbí ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyin iná, kó má sì jó o lẹ́sẹ̀?
29 Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún ẹni tó bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀;Kò sí ẹni tó fọwọ́ kàn án tó máa lọ láìjìyà.+
30 Àwọn èèyàn kì í pẹ̀gàn olèTó bá jẹ́ pé ebi tó ń pa á ló mú kó jalè kó lè tẹ́ ọkàn* rẹ̀ lọ́rùn.
31 Síbẹ̀, tí wọ́n bá rí i, á san án pa dà ní ìlọ́po méje;Gbogbo ohun tó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ló máa kó sílẹ̀.+
32 Ẹni tó bá bá obìnrin ṣe àgbèrè kò ní làákàyè;*Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń fa ìparun bá ara* rẹ̀.+
33 Ọgbẹ́ àti àbùkù ló máa gbà,+Ìtìjú rẹ̀ kò sì ní pa rẹ́.+
34 Nítorí owú máa ń mú kí ọkọ bínú;Kò ní ṣojú àánú nígbà tó bá ń gbẹ̀san.+
35 Kò ní gba àsandípò;*Láìka bí ẹ̀bùn náà ṣe pọ̀ tó, kò ní tù ú lójú.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìyẹn, nínú ẹ̀jẹ́.
^ Tàbí “onígbọ̀wọ́.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
^ Tàbí “òfin.”
^ Tàbí “kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ara.”
^ Ní Héb., “jẹ́ ẹni tí ọkàn kù fún.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ìràpadà.”