Àwọn Ọba Kìíní 4:1-34
4 Ọba Sólómọ́nì ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+
2 Àwọn ìjòyè* rẹ̀ nìyí: Asaráyà ọmọ Sádókù+ ni àlùfáà;
3 Élíhóréfì àti Áhíjà, àwọn ọmọ Ṣíṣà ni akọ̀wé;+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù ni akọ̀wé ìrántí;
4 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ló ń bójú tó àwọn ọmọ ogun; Sádókù àti Ábíátárì+ sì jẹ́ àlùfáà;
5 Asaráyà ọmọ Nátánì+ ni olórí àwọn alábòójútó; Sábúdù ọmọ Nátánì jẹ́ àlùfáà àti ọ̀rẹ́ ọba;+
6 Áhíṣà ló ń bójú tó agbo ilé; Ádónírámù+ ọmọ Ábídà ni olórí àwọn tí ọba ní kí ó máa ṣiṣẹ́ fún òun.+
7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+
8 Àwọn alábòójútó náà ni: Ọmọ Húrì tó ń bójú tó agbègbè olókè Éfúrémù;
9 ọmọ Dékérì tó ń bójú tó Mákásì, Ṣáálíbímù,+ Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Eloni-bẹti-hánánì;
10 ọmọ Hésédì tó ń bójú tó Árúbótì (tirẹ̀ ni Sókọ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Héfà);
11 ọmọ Ábínádábù tó ń bójú tó gbogbo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì (ó fi Táfátì, ọmọ Sólómọ́nì ṣe aya);
12 Béánà ọmọ Áhílúdù tó ń bójú tó Táánákì, Mẹ́gídò+ àti gbogbo Bẹti-ṣéánì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì nísàlẹ̀ Jésírẹ́lì, láti Bẹti-ṣéánì sí Ebẹli-méhólà títí dé agbègbè Jókíméámù;+
13 ọmọ Gébérì tó ń bójú tó Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọ Mánásè, tó wà ní Gílíádì;+ òun ló tún ni agbègbè Ágóbù,+ tó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta [60] ìlú tó tóbi, tó sì ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà);
14 Áhínádábù ọmọ Ídò tó ń bójú tó Máhánáímù;+
15 Áhímáásì tó ń bójú tó Náfútálì (ó fi Básémátì, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Sólómọ́nì, ṣe aya);
16 Béánà ọmọ Húṣáì, tó ń bójú tó Áṣérì àti Béálótì;
17 Jèhóṣáfátì ọmọ Párúà tó ń bójú tó Ísákà;
18 Ṣíméì+ ọmọ Ílà tó ń bójú tó Bẹ́ńjámínì;+
19 Gébérì ọmọ Úráì tó ń bójú tó ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ Síhónì+ ọba àwọn Ámórì àti ti Ógù+ ọba Báṣánì. Alábòójútó kan tún wà tó ń bójú tó gbogbo àwọn alábòójútó yòókù ní ilẹ̀ náà.
20 Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.+
21 Sólómọ́nì ṣàkóso gbogbo àwọn ìjọba láti Odò*+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+
22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun,
23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra.
24 Ó ń bójú tó gbogbo ohun tó wà lápá Odò+ níbí,* láti Tífísà dé Gásà,+ títí kan gbogbo àwọn ọba tó wà lápá Odò níbí; ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo agbègbè tó yí i ká.+
25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.
26 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000)* ilé ẹṣin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin.*+
27 Àwọn alábòójútó yìí ń pèsè oúnjẹ fún Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àwọn tó ń jẹun ní tábìlì Ọba Sólómọ́nì. Kálukú ní oṣù tirẹ̀ tó ń pèsè oúnjẹ, á sì rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ló wà.+
28 Wọ́n á tún mú ọkà bálì àti pòròpórò wá níbikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀ fún àwọn ẹṣin títí kan àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, bí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú wọn bá ṣe gbà.
29 Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an àti ìjìnlẹ̀ òye tó pọ̀* bí iyanrìn etí òkun.+
30 Ọgbọ́n Sólómọ́nì pọ̀ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn àti gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+
31 Ó gbọ́n ju èèyàn èyíkéyìí lọ, ó gbọ́n ju Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì àti Hémánì,+ Kálíkólì+ àti Dáádà, àwọn ọmọ Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+
32 Ó kọ* ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe,+ àwọn orin rẹ̀+ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé márùn-ún (1,005).
33 Ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, látorí kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù+ tó ń hù lára ògiri; ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko,+ àwọn ẹyẹ,*+ àwọn ohun tó ń rákò*+ àti àwọn ẹja.
34 Àwọn èèyàn ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, títí kan àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé tí wọ́n ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “olórí.”
^ Tàbí “owó òde.”
^ Ìyẹn, odò Yúfírétì.
^ Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.
^ Ìyẹn, ìwọ̀ oòrùn odò Yúfírétì.
^ Iye yìí wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan àti ní àwọn apá míì tí ìtàn yìí ti fara hàn nínú Bíbélì. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì pe iye yìí ní ọ̀kẹ́ méjì (40,000).
^ Tàbí “agẹṣin.”
^ Ní Héb., “ọkàn tó gbòòrò.”
^ Tàbí “pa.”
^ Tàbí “àwọn ẹ̀dá tó ń fò.”
^ Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko afàyàfà àti àwọn kòkòrò wà lára wọn.