Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 6:1-20

  • Àwọn ará ń gbéra wọn lọ sílé ẹjọ́ (1-8)

  • Àwọn tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run (9-11)

  • Ẹ máa yin Ọlọ́run lógo nínú ara yín (12-20)

    • “Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!” (18)

6  Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú yín tó ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan+ gbójúgbóyà lọ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìṣòdodo, tí kì í sì í ṣe níwájú àwọn ẹni mímọ́?  Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ló máa ṣèdájọ́ ayé?+ Tó bá sì jẹ́ pé ẹ̀yin lẹ máa ṣèdájọ́ ayé, ṣé ẹ ò mọ bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan ni?  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé àwa la máa ṣèdájọ́ àwọn áńgẹ́lì ni?+ Kí ló wá dé tí a ò lè yanjú àwọn ọ̀ràn ti ayé yìí?  Tí ẹ bá wá ní àwọn ọ̀ràn ayé yìí tí ẹ fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀,+ ṣé àwọn ọkùnrin tí ìjọ ń fojú àbùkù wò ló yẹ kí ẹ yàn ṣe onídàájọ́?  Mò ń sọ̀rọ̀ kí ojú lè tì yín. Ṣé kò sí ọlọ́gbọ́n kankan láàárín yín tó lè ṣèdájọ́ láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀ ni?  Arákùnrin wá ń gbé arákùnrin lọ sí ilé ẹjọ́, ó tún wá jẹ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́!  Ní tòótọ́, ẹ ti pa ara yín láyò bí ẹ ṣe ń pe ara yín lẹ́jọ́. Ẹ ò ṣe kúkú gbà kí wọ́n ṣe àìtọ́ sí yín?+ Ẹ ò ṣe kúkú jẹ́ kí wọ́n lù yín ní jìbìtì?  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń ṣe àìtọ́, ẹ sì ń lu jìbìtì, ó tún wá jẹ́ sí àwọn arákùnrin yín!  Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10  àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+ 11  Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ a ti wẹ̀ yín mọ́;+ a ti yà yín sí mímọ́;+ a ti pè yín ní olódodo+ ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run wa. 12  Ohun gbogbo ló bófin mu* lójú mi, àmọ́ kì í ṣe ohun gbogbo ló ṣàǹfààní.+ Ohun gbogbo ló bófin mu lójú mi, àmọ́ mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun máa darí mi.* 13  Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ, àmọ́ Ọlọ́run máa sọ àwọn méjèèjì di asán.+ Ara kò wà fún ìṣekúṣe,* Olúwa ló wà fún,+ Olúwa sì wà fún ara. 14  Àmọ́ Ọlọ́run gbé Olúwa dìde,+ yóò sì gbé àwa náà dìde kúrò nínú ikú+ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.+ 15  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni ara yín ni?+ Ṣé ó wá yẹ kí n mú ẹ̀yà ara Kristi kúrò, kí n sì dà á pọ̀ mọ́ ti aṣẹ́wó? Ká má ri! 16  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ẹni tó bá ní àṣepọ̀ pẹ̀lú aṣẹ́wó á di ara kan pẹ̀lú rẹ̀ ni? Nítorí Ọlọ́run sọ pé “àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+ 17  Àmọ́ ẹni tó bá dara pọ̀ mọ́ Olúwa jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ nínú ẹ̀mí.+ 18  Ẹ máa sá fún ìṣekúṣe!*+ Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ míì tí èèyàn lè dá wà lóde ara rẹ̀, àmọ́ ẹni tó bá ń ṣe ìṣekúṣe ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.+ 19  Ṣé ẹ ò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ńpìlì+ ẹ̀mí mímọ́ tó wà nínú yín, èyí tí ẹ gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run?+ Bákan náà, ẹ kì í ṣe ti ara yín,+ 20  nítorí a ti rà yín ní iye kan.+ Nítorí náà, ẹ máa yin Ọlọ́run lógo+ nínú ara yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀.” Ní Grk., “àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin sùn.”
Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”
Tàbí “tàn yín jẹ.”
Tàbí “ẹlẹ́rẹ̀kẹ́ èébú.”
Tàbí “làyè gbà.”
Tàbí “mú mi wá sábẹ́ àṣẹ.”
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.