Àwọn Ọba Kejì 5:1-27
5 Ọkùnrin olókìkí kan wà tó ń jẹ́ Náámánì, òun ni olórí ọmọ ogun ọba Síríà, ẹni ńlá ni lójú olúwa rẹ̀ nítorí pé ipasẹ̀ rẹ̀ ni Jèhófà fi mú kí Síríà ṣẹ́gun.* Jagunjagun tó lákíkanjú ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé adẹ́tẹ̀ ni.*
2 Ìgbà kan wà tí àwọn ará Síríà lọ kó ohun ìní àwọn èèyàn, wọ́n mú ọmọbìnrin kékeré kan lẹ́rú láti ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì di ìránṣẹ́ ìyàwó Náámánì.
3 Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé: “Ká ní olúwa mi lè lọ rí wòlíì+ tó wà ní Samáríà ni! Ó máa wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn.”+
4 Torí náà, ó* lọ fi ohun tí ọmọbìnrin ará Ísírẹ́lì náà sọ tó olúwa rẹ̀ létí.
5 Nígbà náà, ọba Síríà sọ pé: “Ó yá, gbéra! Màá fi lẹ́tà kan rán ọ sí ọba Ísírẹ́lì.” Nítorí náà, ó lọ, ó kó tálẹ́ńtì* fàdákà mẹ́wàá àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ẹyọ wúrà àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá dání.
6 Ó mú lẹ́tà náà wá fún ọba Ísírẹ́lì, lẹ́tà náà kà báyìí pé: “Mo rán ìránṣẹ́ mi Náámánì sí ọ pẹ̀lú lẹ́tà yìí, kí o lè wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn.”
7 Gbàrà tí ọba Ísírẹ́lì ka lẹ́tà náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọ pé: “Ṣé Ọlọ́run ni mí, tí màá lè pani, tí màá sì lè dáni sí?+ Nítorí ọba Síríà rán ọkùnrin yìí sí mi pé kí n wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn! Àbí ẹ̀yin náà ò rí i pé wàhálà ló ń wá.”
8 Àmọ́ nígbà tí Èlíṣà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ gbọ́ pé ọba Ísírẹ́lì ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ní kíá, ó ránṣẹ́ sí ọba pé: “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Jọ̀ọ́, jẹ́ kó wá sọ́dọ̀ mi, kó lè mọ̀ pé wòlíì kan wà ní Ísírẹ́lì.”+
9 Nítorí náà, Náámánì wá, tòun ti àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Èlíṣà.
10 Àmọ́, Èlíṣà ní kí ìránṣẹ́ kan lọ sọ fún un pé: “Lọ wẹ̀ nígbà méje+ ní odò Jọ́dánì,+ ara rẹ á pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, wàá sì mọ́.”
11 Náámánì bá bínú, ó sì yíjú pa dà, ó ní: “Ohun tí mo rò ni pé, ‘Á jáde wá bá mi, á dúró níbí yìí, á sì pe orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ síwá-sẹ́yìn lórí ẹ̀tẹ̀ náà láti wò ó sàn.’
12 Ṣé Ábánà àti Fápárì, àwọn odò Damásíkù,+ kò dára ju gbogbo omi Ísírẹ́lì ni? Ṣé mi ò lè wẹ̀ nínú wọn kí n sì mọ́ ni?” Bó ṣe yíjú pa dà nìyẹn, ó sì ń bínú lọ.
13 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ pé: “Bàbá mi, ká ní ohun ńlá kan ni wòlíì náà sọ fún ọ pé kí o ṣe, ṣé o ò ní ṣe é ni? Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ohun kékeré tó sọ fún ọ yìí pé, ‘Wẹ̀, kí o sì mọ́’?”
14 Ni ó bá lọ síbẹ̀, ó sì ri* ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ti sọ.+ Lẹ́yìn náà, ara rẹ̀ pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ó rí bí ara ọmọ kékeré,+ ó sì mọ́.+
15 Lẹ́yìn náà, ó pa dà lọ sọ́dọ̀ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́,+ òun pẹ̀lú gbogbo àwọn tó tẹ̀ lé e,* ó dúró níwájú rẹ̀, ó sì sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé kò sí Ọlọ́run níbikíbi láyé, àfi ní Ísírẹ́lì.+ Jọ̀ọ́, gba ẹ̀bùn* yìí lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”
16 Àmọ́ Èlíṣà sọ pé: “Bí Jèhófà tí mò ń sìn* ti wà láàyè, mi ò ní gbà á.”+ Ó ń rọ̀ ọ́ pé kó gbà á, ṣùgbọ́n ó kọ̀ ọ́.
17 Níkẹyìn, Náámánì sọ pé: “Tí o kò bá gbà á, jọ̀ọ́, jẹ́ kí wọ́n bu erùpẹ̀ ilẹ̀ yìí tí ó tó ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* méjì fún ìránṣẹ́ rẹ, torí ìránṣẹ́ rẹ kò ní rú ẹbọ sísun tàbí ẹbọ sí ọlọ́run kankan mọ́, àfi Jèhófà.
18 Àmọ́, kí Jèhófà dárí ji ìránṣẹ́ rẹ nínú ohun kan ṣoṣo yìí: Nígbà tí olúwa mi bá lọ sí ilé* Rímónì láti forí balẹ̀ níbẹ̀, ó máa ń fara tì mí, torí náà mo ní láti forí balẹ̀ ní ilé Rímónì. Kí Jèhófà jọ̀ọ́ dárí ji ìránṣẹ́ rẹ nígbà tí mo bá forí balẹ̀ ní ilé Rímónì.”
19 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Máa lọ ní àlàáfíà.” Lẹ́yìn tó ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì ti rìn jìnnà díẹ̀,
20 Géhásì,+ ìránṣẹ́ Èlíṣà èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé bí ọ̀gá mi á ṣe jẹ́ kí Náámánì ará Síríà+ yìí lọ láìgba ohun tó mú wá nìyẹn? Bí Jèhófà ti wà láàyè, màá sá tẹ̀ lé e, màá sì gba nǹkan kan lọ́wọ́ rẹ̀.’
21 Torí náà, Géhásì sá tẹ̀ lé Náámánì. Nígbà tí Náámánì rí i pé ẹnì kan ń sáré tẹ̀ lé òun, ó sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni?”
22 Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Ọ̀gá mi ló rán mi, ó ní, ‘Wò ó! Àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì lára àwọn ọmọ wòlíì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sọ́dọ̀ mi láti agbègbè olókè Éfúrémù. Jọ̀ọ́, fún wọn ní tálẹ́ńtì fàdákà kan àti ìpààrọ̀ aṣọ méjì.’”+
23 Náámánì wá sọ pé: “Ó yá, kó tálẹ́ńtì méjì.” Ó ń rọ̀ ọ́,+ ó sì di tálẹ́ńtì fàdákà méjì sínú àpò méjì pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó gbé wọn fún méjì lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń gbé e lọ níwájú rẹ̀.
24 Nígbà tó dé Ófélì,* ó gbà á lọ́wọ́ wọn, ó kó wọn sínú ilé, ó sì ní kí àwọn ọkùnrin náà máa lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ,
25 ó wọlé, ó sì dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀gá rẹ̀. Èlíṣà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo lo ti ń bọ̀, Géhásì?” Àmọ́, ó dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ò lọ síbì kankan.”+
26 Èlíṣà bá sọ fún un pé: “Ṣé o rò pé mi ò máa fọkàn bá ọ lọ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀ kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ló yẹ kéèyàn gba fàdákà tàbí àwọn aṣọ tàbí àwọn oko ólífì tàbí àwọn ọgbà àjàrà tàbí àgùntàn tàbí màlúù tàbí àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin?+
27 Ní báyìí, ẹ̀tẹ̀ Náámánì+ yóò lẹ̀ mọ́ ìwọ àti àtọmọdọ́mọ rẹ títí láé.” Lójú ẹsẹ̀, ó di adẹ́tẹ̀, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ funfun bíi yìnyín,+ ó sì jáde kúrò níwájú rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “rí ìgbàlà.”
^ Tàbí “àìsàn kan ń ṣe é nínú awọ ara rẹ̀.”
^ Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí Náámánì.
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “tẹ.”
^ Ní Héb., “ìbùkún.”
^ Ní Héb., “ibùdó rẹ̀.”
^ Ní Héb., “tí mo dúró níwájú rẹ̀.”
^ Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka.
^ Tàbí “tẹ́ńpìlì.”
^ Ibì kan ní Samáríà tó ṣeé ṣe kó jẹ́ òkè tàbí ibi tó láàbò.