Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 9:1-15

  • Ó fún wọn níṣìírí láti máa fúnni (1-15)

    • Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú (7)

9  Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ kò pọn dandan kí n kọ̀wé sí yín,  torí mo mọ bó ṣe ń yá yín lára, mo sì fi ń yangàn lójú àwọn ará Makedóníà, pé ó ti pé ọdún kan báyìí tí Ákáyà ti múra tán, ìtara yín sì ti mú kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn gbára dì.  Àmọ́ mò ń rán àwọn arákùnrin náà sí yín, kí gbogbo bí a ṣe ń fi yín yangàn má bàa já sí asán nínú ọ̀ràn yìí, kí ẹ sì lè múra tán lóòótọ́, bí mo ṣe sọ pé ẹ máa ṣe.  Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí àwọn ará Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì rí i pé ẹ ò múra sílẹ̀, ìtìjú á bá wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ẹ̀yin, torí pé a fọkàn tán yín.  Nítorí náà, mo wò ó pé ó ṣe pàtàkì láti fún àwọn arákùnrin náà ní ìṣírí pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ yín ṣáájú àkókò, kí wọ́n sì múra ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣèlérí sílẹ̀, kí èyí lè wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí èèyàn fipá gbà.  Àmọ́ ní ti èyí, ẹni tó bá ń fúnrúgbìn díẹ̀ máa kórè díẹ̀, ẹni tó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu máa kórè yanturu.+  Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe,*+ nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.+  Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run lè mú kí gbogbo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ pọ̀ gidigidi fún yín, kí ẹ lè máa ní ànító ohun gbogbo nígbà gbogbo, kí ẹ sì tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fún iṣẹ́ rere gbogbo.+  (Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri,* ó ti fún àwọn aláìní. Òdodo rẹ̀ wà títí láé.”+ 10  Ẹni tó ń pèsè irúgbìn lọ́pọ̀ yanturu fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún jíjẹ máa pèsè irúgbìn, ó máa sọ ọ́ di púpọ̀ fún yín láti gbìn, á sì mú èso òdodo yín pọ̀ sí i.) 11  Ọlọ́run ti bù kún yín ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ lè máa fúnni lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí sì ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; 12  nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn èèyàn kì í ṣe láti fún àwọn ẹni mímọ́ ní ohun tí wọ́n nílò nìkan,+ ó tún máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. 13  Ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ yìí ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí, èyí sì ń mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run lógo torí pé ẹ̀ ń ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Kristi, bí ẹ ṣe kéde fún àwọn èèyàn, tí ẹ sì jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún wọn àti fún gbogbo èèyàn.+ 14  Wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí yín bí wọ́n ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ tó wà lórí yín. 15  Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí kò ṣeé ṣàpèjúwe.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àìfẹ́ṣe.”
Tàbí “fàlàlà.”