Diutarónómì 1:1-46
1 Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ ní agbègbè Jọ́dánì nínú aginjù, ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú níwájú Súfù, láàárín Páránì, Tófélì, Lábánì, Hásérótì àti Dísáhábù.
2 Ìrìn ọjọ́ mọ́kànlá (11) ni láti Hórébù sí Kadeṣi-bánéà+ tí wọ́n bá gba ọ̀nà Òkè Séírì.
3 Ní ọjọ́ kìíní, oṣù kọkànlá, ọdún ogójì,+ Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* sọ gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó sọ fún wọn.
4 Èyí jẹ́ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tó ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì àti Ógù+ ọba Báṣánì, tó ń gbé ní Áṣítárótì, ní Édíréì.+
5 Ní agbègbè Jọ́dánì ní ilẹ̀ Móábù, Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé Òfin+ yìí, pé:
6 “Jèhófà Ọlọ́run wa sọ fún wa ní Hórébù pé, ‘Ẹ ti pẹ́ tó ní agbègbè olókè yìí.+
7 Ẹ ṣẹ́rí pa dà, kí ẹ sì máa lọ sí agbègbè olókè àwọn Ámórì,+ kí ẹ forí lé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí wọn ká ní Árábà,+ agbègbè olókè, Ṣẹ́fẹ́là, Négébù àti etí òkun, + ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì àti Lẹ́bánónì,*+ títí dé odò ńlá, ìyẹn odò Yúfírétì.+
8 Ẹ wò ó, mo ti fi ilẹ̀ náà síwájú yín. Ẹ wọ inú rẹ̀ lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn bàbá yín, Ábúráhámù, Ísákì,+ Jékọ́bù+ àti àwọn àtọmọdọ́mọ* wọn lẹ́yìn wọn.’+
9 “Mo sọ fún yín nígbà yẹn pé, ‘Mi ò lè dá ẹrù yín gbé.+
10 Jèhófà Ọlọ́run yín ti mú kí ẹ pọ̀, ẹ̀yin sì nìyí lónìí tí ẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+
11 Kí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín mú kí ẹ pọ̀ ju báyìí lọ+ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, kí ó sì bù kún yín bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.+
12 Báwo ni màá ṣe dá ru àjàgà yín àti ẹrù yín pẹ̀lú gbogbo bí ẹ ṣe máa ń fa wàhálà?+
13 Ẹ yan àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye, tí wọ́n sì ní ìrírí látinú àwọn ẹ̀yà yín, màá sì fi wọ́n ṣe olórí yín.’+
14 Ẹ fèsì pé, ‘Ohun tí o ní ká ṣe dáa.’
15 Torí náà, mo mú àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, tí wọ́n sì ní ìrírí, mo yàn wọ́n ṣe olórí yín, olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta, olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá àti àwọn aṣojú nínú àwọn ẹ̀yà yín.+
16 “Nígbà yẹn, mo sọ fún àwọn onídàájọ́ yín pé, ‘Tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, kí ẹ máa fi òdodo ṣèdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.+
17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbè sápá kan nínú ìdájọ́.+ Bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó kéré ni kí ẹ ṣe gbọ́ ti ẹni ńlá.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn dẹ́rù bà yín,+ torí Ọlọ́run ló ni ìdájọ́;+ tí ẹjọ́ kan bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì gbọ́ ọ.’+
18 Nígbà yẹn, mo sọ gbogbo ohun tó yẹ kí ẹ ṣe fún yín.
19 “Lẹ́yìn náà, a kúrò ní Hórébù, a sì kọjá ní gbogbo aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù yẹn,+ èyí tí ẹ rí lójú ọ̀nà tó lọ sí agbègbè olókè àwọn Ámórì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe pàṣẹ fún wa gẹ́lẹ́, a sì wá dé Kadeṣi-bánéà.+
20 Mo wá sọ fún yín pé, ‘Ẹ ti dé agbègbè olókè àwọn Ámórì, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa.
21 Wò ó, Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti fún ọ ní ilẹ̀ náà. Gòkè lọ, kí o sì gbà á bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe sọ fún ọ gẹ́lẹ́.+ Má bẹ̀rù, má sì fòyà.’
22 “Àmọ́ gbogbo yín wá bá mi, ẹ sì sọ pé, ‘Jẹ́ ká rán àwọn ọkùnrin lọ ṣáájú wa, kí wọ́n lè bá wa wo ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì pa dà wá jábọ̀ fún wa, ká lè mọ ọ̀nà tí a máa gbà àtàwọn ìlú tó wà lọ́nà.’+
23 Àbá yẹn dáa lójú mi, mo sì yan ọkùnrin méjìlá (12) lára yín, ẹnì kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.+
24 Wọ́n gbéra, wọ́n sì gòkè lọ sí agbègbè olókè náà,+ wọ́n dé Àfonífojì Éṣíkólì, wọ́n sì ṣe amí ilẹ̀ náà.
25 Wọ́n mú lára èso ilẹ̀ náà, wọ́n sì kó o wá fún wa, wọ́n pa dà wá jábọ̀ fún wa pé, ‘Ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run wa fẹ́ fún wa dáa.’+
26 Àmọ́ ẹ kọ̀ láti gòkè lọ, ẹ sì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
27 Ẹ̀ ń ráhùn ṣáá nínú àwọn àgọ́ yín, ẹ sì ń sọ pé, ‘Torí Jèhófà kórìíra wa ló ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi wá lé àwọn Ámórì lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá run.
28 Báwo ni ibi tí à ń lọ ṣe rí? Àwọn arákùnrin wa mú kí ẹ̀rù bà wá,*+ wọ́n sọ pé: “Àwọn èèyàn náà lágbára, wọ́n sì ga jù wá lọ, àwọn ìlú wọn tóbi, wọ́n sì mọ odi rẹ̀ kan ọ̀run,*+ a sì rí àwọn ọmọ Ánákímù+ níbẹ̀.”’
29 “Mo wá sọ fún yín pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò yín, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín.+
30 Jèhófà Ọlọ́run yín máa lọ níwájú yín, ó sì máa jà fún yín,+ bó ṣe jà fún yín ní Íjíbítì tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.+
31 Ẹ sì rí i bí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe gbé yín nínú aginjù, bí bàbá ṣe ń gbé ọmọ rẹ̀, tó sì ń gbé yín kiri gbogbo ibi tí ẹ lọ títí ẹ fi dé ibí yìí.’
32 Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo èyí, ẹ ò gba Jèhófà Ọlọ́run yín gbọ́,+
33 ẹni tó ń ṣáájú yín lójú ọ̀nà, láti wá ibi tí ẹ lè pàgọ́ sí. Ó ń fara hàn yín nípasẹ̀ iná ní òru àti nípasẹ̀ ìkùukùu* ní ọ̀sán, láti fi ọ̀nà tí ẹ máa gbà hàn yín.+
34 “Ní gbogbo ìgbà yẹn, Jèhófà gbọ́ ohun tí ẹ̀ ń sọ, inú sì bí i gidigidi, ó wá búra pé,+
35 ‘Ìkankan nínú àwọn èèyàn yìí tí wọ́n wà lára ìran búburú yìí kò ní rí ilẹ̀ dáradára tí mo búra pé màá fún àwọn bàbá yín,+
36 àfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè. Òun máa rí i, mo sì máa fún òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ilẹ̀ tó rìn lórí rẹ̀, torí pé ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà.*+
37 (Torí yín ni Jèhófà tiẹ̀ ṣe bínú sí mi, ó ní, “Ìwọ náà ò ní wọ ibẹ̀.+
38 Jóṣúà ọmọ Núnì, tó máa ń dúró níwájú rẹ+ ló máa wọ ilẹ̀ náà.+ Sọ ọ́ di alágbára,*+ torí òun ló máa mú kí Ísírẹ́lì jogún rẹ̀.”)
39 Àmọ́, àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé wọ́n máa kó lẹ́rú+ àti àwọn ọmọ yín tí wọn ò mọ rere yàtọ̀ sí búburú lónìí ni wọ́n máa wọ ibẹ̀, àwọn ni màá sì fún ní ilẹ̀ náà kó lè di tiwọn.+
40 Ní tiyín, ẹ ṣẹ́rí pa dà, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sí aginjù.’+
41 “Ẹ wá sọ fún mi pé, ‘A ti ṣẹ Jèhófà. A máa gòkè lọ bá wọn jà báyìí, bí Jèhófà Ọlọ́run wa ṣe pa á láṣẹ fún wa gẹ́lẹ́!’ Kálukú yín wá múra ogun, ẹ sì rò pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa rọrùn tó láti gun òkè náà lọ.+
42 Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé, ‘Sọ fún wọn pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ gòkè lọ jà, torí mi ò ní bá yín lọ.+ Tí ẹ bá lọ, àwọn ọ̀tá yín máa ṣẹ́gun yín.”’
43 Mo wá bá yín sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ kẹ̀yìn sí àṣẹ Jèhófà, ẹ sì ṣorí kunkun* pé ẹ máa gun òkè náà lọ.
44 Àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní òkè náà sì jáde wá pàdé yín, wọ́n lé yín dà nù bí oyin ṣe máa ń ṣe, wọ́n sì tú yín ká láti Séírì títí lọ dé Hóómà.
45 Ẹ wá pa dà, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún níwájú Jèhófà, àmọ́ Jèhófà kò fetí sí yín, kò sì dá yín lóhùn.
46 Ìdí nìyẹn tí iye ọjọ́ tí ẹ fi gbé ní Kádéṣì fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
^ Ó ṣe kedere pé, agbègbè olókè Lẹ́bánónì ló ń sọ.
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “mú kí ọkàn wa pami.”
^ Ìyẹn ni pé odi rẹ̀ rí gàgàrà.
^ Tàbí “àwọsánmà.”
^ Ní Héb., “tọ Jèhófà lẹ́yìn délẹ̀délẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run ti fún un lágbára.”
^ Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”