Diutarónómì 12:1-32
12 “Èyí ni àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé ẹ̀ ń pa mọ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín pé kó di tiyín.
2 Gbogbo ibi tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ máa lé kúrò bá ti sin àwọn ọlọ́run wọn ni kí ẹ pa run pátápátá,+ ì báà jẹ́ lórí àwọn òkè tó ga tàbí lórí àwọn òkè kéékèèké tàbí lábẹ́ igi èyíkéyìí tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.
3 Kí ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, kí ẹ fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn túútúú,+ kí ẹ dáná sun àwọn òpó òrìṣà* wọn, kí ẹ sì gé ère àwọn ọlọ́run wọn+ tí wọ́n gbẹ́ lulẹ̀, kí orúkọ wọn lè pa rẹ́ kúrò níbẹ̀.+
4 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run yín lọ́nà yẹn.+
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+
6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+
7 Ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin àti àwọn agbo ilé yín ti jẹun níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì máa yọ̀ nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé,+ torí Jèhófà Ọlọ́run yín ti bù kún yín.
8 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe bí a ṣe ń ṣe níbí lónìí, tí kálukú ń ṣe ohun tó dáa lójú ara rẹ̀,*
9 torí pé ẹ ò tíì dé ibi ìsinmi,+ ẹ ò sì tíì gba ogún tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín.
10 Tí ẹ bá ti sọdá Jọ́dánì,+ tí ẹ sì wá ń gbé ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kó di tiyín, ó dájú pé ó máa mú kí ẹ sinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tó yí yín ká, ẹ ó sì máa gbé láìséwu.+
11 Gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ mú wá sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run yín yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà,+ ìyẹn àwọn ẹbọ sísun yín, àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín àti gbogbo ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà.
12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ẹrúkùnrin yín, àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, torí kò bá yín ní ìpín tàbí ogún kankan.+
13 Kí ẹ rí i pé ẹ ò rú àwọn ẹbọ sísun yín níbòmíì tí ẹ bá rí.+
14 Ibi tí Jèhófà yàn nínú ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ti ẹ̀yà yín nìkan ni kí ẹ ti rú àwọn ẹbọ sísun yín, ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti ṣe gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.+
15 “Àmọ́ ìgbàkígbà tó bá wù yín* lẹ lè pa ẹran kí ẹ sì jẹ ẹ́,+ bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó ní gbogbo ìlú* yín. Ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́, bí ẹ ṣe máa ń jẹ egbin tàbí àgbọ̀nrín.
16 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí ẹ dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+
17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn nǹkan yìí nínú àwọn ìlú* yín: ìdá mẹ́wàá ọkà yín, wáìnì tuntun yín, òróró yín, àwọn àkọ́bí lára ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín,+ èyíkéyìí lára àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá yín àti ọrẹ látọwọ́ yín.
18 Iwájú Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ ti jẹ ẹ́, níbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn,+ ẹ̀yin àti ọmọkùnrin yín, ọmọbìnrin yín, ẹrúkùnrin yín àti ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín; kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín nínú gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé.
19 Kí ẹ rí i pé ẹ ò gbàgbé ọmọ Léfì+ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi ń gbé lórí ilẹ̀ yín.
20 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú kí ilẹ̀ rẹ fẹ̀ sí i,+ bó ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́,+ tí o wá ń sọ pé, ‘Mo fẹ́ jẹ ẹran,’ torí pé ẹran ń wù ọ́ jẹ,* o lè jẹ ẹ́ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.*+
21 Tí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí+ bá jìnnà sí ọ, kí o pa lára ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran rẹ tí Jèhófà fún ọ, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, kí o sì jẹ ẹ́ nínú àwọn ìlú* rẹ nígbàkigbà tó bá wù ọ́.*
22 Kí o jẹ ẹ́ bí o ṣe máa ń jẹ egbin àti àgbọ̀nrín;+ ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ àti ẹni tó mọ́ lè jẹ ẹ́.
23 Ṣáà ti pinnu pé o ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀,+ má sì yẹ ìpinnu rẹ, torí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀mí* pọ̀ mọ́ ẹran.
24 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. Ṣe ni kí o dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+
25 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, torí ò ń ṣe ohun tó tọ́ ní ojú Jèhófà.
26 Àwọn ohun mímọ́ tó jẹ́ tìrẹ àti àwọn ọrẹ tí o jẹ́jẹ̀ẹ́ nìkan ni kí o mú wá tí o bá wá sí ibi tí Jèhófà máa yàn.
27 Ibẹ̀ ni kí o ti rú àwọn ẹbọ sísun rẹ, ẹran àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,+ lórí pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì da ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹbọ rẹ sára pẹpẹ+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ṣùgbọ́n o lè jẹ ẹran rẹ̀.
28 “Rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ yìí, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ nígbà gbogbo, torí pé ò ń ṣe ohun tó dáa tó sì tọ́ ní ojú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí o máa lé kúrò run,+ tí o sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn,
30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+
31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
32 Gbogbo ọ̀rọ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín ni kí ẹ rí i pé ẹ tẹ̀ lé.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi kún un, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ yọ kúrò nínú rẹ̀.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ohun tó rò pé ó tọ́.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè.”
^ Tàbí “gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn yín.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Tàbí “ó wu ọkàn rẹ pé kó jẹ ẹran.”
^ Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”
^ Ní Héb., “ẹnubodè.”
^ Tàbí “ní gbogbo ìgbà tó bá wu ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn.”