Diutarónómì 17:1-20
17 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù tàbí àgùntàn tó ní àbùkù lára tàbí tí ohunkóhun ṣe, rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí pé ohun ìríra ló máa jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
2 “Ká sọ pé ọkùnrin tàbí obìnrin kan wà láàárín rẹ, nínú èyíkéyìí lára àwọn ìlú rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tó sì ń tẹ májẹ̀mú rẹ̀ lójú,+
3 tó wá yà bàrá, tó sì lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì, tó ń forí balẹ̀ fún wọn tàbí tó ń forí balẹ̀ fún oòrùn tàbí òṣùpá tàbí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ.+
4 Tí wọ́n bá sọ fún ọ tàbí tí o gbọ́ nípa rẹ̀, kí o wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa. Tó bá jẹ́ òótọ́ ni+ ohun ìríra yìí ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì,
5 kí o mú ọkùnrin tàbí obìnrin tó ṣe ohun burúkú yìí jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ ọkùnrin tàbí obìnrin náà ní òkúta pa.+
6 Ẹni méjì tàbí mẹ́ta ni kó jẹ́rìí sí i,*+ kí ẹ tó pa ẹni tí ikú tọ́ sí. Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa á tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló jẹ́rìí sí i.+
7 Ọwọ́ àwọn ẹlẹ́rìí náà ni kó kọ́kọ́ bà á tí wọ́n bá fẹ́ pa á, lẹ́yìn náà kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ láti pa á. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ.+
8 “Tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, tí ẹjọ́ náà sì ṣòroó dá, bóyá ọ̀rọ̀ nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ẹnì kan fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ tàbí àwọn kan hùwà ipá tàbí àwọn ẹjọ́ míì tó jẹ mọ́ fífa ọ̀rọ̀, kí o gbéra, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn.+
9 Lọ bá àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti adájọ́+ tó ń gbẹ́jọ́ nígbà yẹn, kí o ro ẹjọ́ náà fún wọn, wọ́n á sì bá ọ dá a.+
10 Ìdájọ́ tí wọ́n bá ṣe ní ibi tí Jèhófà yàn ni kí o tẹ̀ lé. Kí o rí i pé o ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún ọ.
11 Kí o tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá fi hàn ọ́, kí o sì tẹ̀ lé ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ.+ O ò gbọ́dọ̀ yà kúrò lórí ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+
12 Ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó bá ṣorí kunkun,* tó kọ̀ láti fetí sí àlùfáà tó ń bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣiṣẹ́ tàbí sí adájọ́ náà.+ Kí o mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+
13 Gbogbo èèyàn á wá gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, wọn ò sì ní ṣorí kunkun mọ́.+
14 “Tí o bá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tí o gbà á, tí o ti ń gbé ibẹ̀, tí o wá sọ pé, ‘Jẹ́ kí n yan ọba lé ara mi lórí, bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí mi ká,’+
15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ.
16 Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ní kí àwọn èèyàn náà pa dà lọ sí Íjíbítì láti lọ kó ẹṣin sí i wá,+ torí Jèhófà ti sọ fún yín pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún forí lé ọ̀nà yìí mọ́.’
17 Kò sì gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀, kí ọkàn rẹ̀ má bàa yí pa dà;+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ kó fàdákà àti wúrà rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀.+
18 Tó bá ti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kó fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin yìí sínú ìwé* kan, látinú èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà tọ́jú.+
19 “Ọwọ́ rẹ̀ ni kó máa wà, kó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ kó lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí àti àwọn ìlànà yìí, kí o máa pa wọ́n mọ́.+
20 Èyí ò ní jẹ́ kó gbé ọkàn rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kó yà kúrò nínú àṣẹ náà, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kó lè pẹ́ lórí oyè, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ láàárín Ísírẹ́lì.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “fi ẹnu sí i.”
^ Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
^ Tàbí “àkájọ ìwé.”