Diutarónómì 20:1-20
20 “Tí o bá lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jagun, tí o sì rí àwọn ẹṣin, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ jù ọ́ lọ, má bẹ̀rù wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì wà pẹ̀lú rẹ.+
2 Tí ẹ bá fẹ́ lọ sójú ogun, kí àlùfáà lọ bá àwọn èèyàn náà, kó sì bá wọn sọ̀rọ̀.+
3 Kó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọ̀tá yín lẹ fẹ́ lọ bá jagun. Ẹ má ṣojo. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà, ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín nítorí wọn,
4 torí Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín lọ kó lè jà fún yín láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yín, kó sì gbà yín là.’+
5 “Bákan náà, kí àwọn olórí sọ fún àwọn èèyàn náà pé, ‘Ta ló ti kọ́ ilé tuntun àmọ́ tí kò tíì ṣí i? Kó pa dà sí ilé rẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ẹlòmíì á sì ṣí ilé náà.
6 Ta ló sì ti gbin àjàrà, àmọ́ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn rẹ̀? Kó gbéra, kó sì pa dà sí ilé rẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ẹlòmíì á sì máa gbádùn àjàrà rẹ̀.
7 Ta ló sì ti ń fẹ́ obìnrin kan sọ́nà, àmọ́ tí kò tíì gbé e níyàwó? Kó gbéra, kó sì pa dà sí ilé rẹ̀.+ Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè kú sójú ogun, ọkùnrin míì á sì fi obìnrin náà ṣaya.’
8 Kí àwọn olórí náà bi àwọn èèyàn náà pé, ‘Ta ni ẹ̀rù ń bà, tí àyà rẹ̀ sì ń já?+ Kó pa dà sí ilé rẹ̀, kó má bàa mú kí ọkàn àwọn arákùnrin rẹ̀ domi bíi tirẹ̀.’*+
9 Tí àwọn olórí bá ti bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ tán, kí wọ́n yan àwọn tó máa ṣe olórí àwọn ọmọ ogun láti darí àwọn èèyàn náà.
10 “Tí o bá sún mọ́ ìlú kan láti bá a jà, kí o fi ọ̀rọ̀ àlàáfíà ránṣẹ́ sí i.+
11 Tó bá fún ọ lésì àlàáfíà, tó sì ṣí ọ̀nà fún ọ, gbogbo èèyàn tí o bá rí níbẹ̀ máa di tìẹ, wàá máa kó wọn ṣiṣẹ́, wọ́n á sì máa sìn ọ́.+
12 Àmọ́ tó bá kọ̀, tí kò fún ọ lésì àlàáfíà, tó wá fẹ́ bá ọ jagun, kí o gbógun tì í,
13 ó sì dájú pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi í lé ọ lọ́wọ́, kí o sì fi idà pa gbogbo ọkùnrin tó bá wà níbẹ̀.
14 Àmọ́ kí o kó àwọn obìnrin tó bá wà níbẹ̀ fún ara rẹ, àtàwọn ọmọdé, ẹran ọ̀sìn, gbogbo nǹkan tó bá wà nínú ìlú náà àti gbogbo ẹrù ibẹ̀,+ wàá sì máa lo gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi lé ọ lọ́wọ́.+
15 “Ohun tí wàá ṣe sí gbogbo ìlú tó jìnnà gan-an sí ọ nìyẹn, àwọn ìlú tí kò sí nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí yìí.
16 Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ dá ohun eléèémí kankan sí ní ìlú àwọn èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.+
17 Ṣe ni kí o pa wọ́n run pátápátá, ìyẹn àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe pa á láṣẹ fún ọ gẹ́lẹ́;
18 kí wọ́n má bàa kọ́ yín láti máa ṣe gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kí wọ́n wá mú kí ẹ ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín.+
19 “Tí o bá gbógun ti ìlú kan, tí o sì gbà á lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí o ti ń bá a jà, o ò gbọ́dọ̀ yọ àáké ti àwọn igi rẹ̀ láti pa wọ́n run. O lè jẹ lára èso wọn, àmọ́ má ṣe gé wọn lulẹ̀.+ Ṣé ó yẹ kí o gbógun ti igi inú igbó bí ẹni ń gbógun ti èèyàn ni?
20 Igi tí o bá mọ̀ pé èso rẹ̀ kò ṣeé jẹ nìkan lo lè pa run. O lè gé e lulẹ̀, kí o sì fi ṣe àwọn ohun tí wàá fi gbógun ti ìlú tó fẹ́ bá ọ jagun títí o fi máa ṣẹ́gun rẹ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “kó ìpayà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ bíi tirẹ̀.”