Diutarónómì 7:1-26
7 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o fẹ́ wọ̀ tí o sì máa gbà,+ ó máa mú àwọn orílẹ̀-èdè tí èèyàn wọn pọ̀ kúrò níwájú rẹ:+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ.+
2 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, wàá sì ṣẹ́gun wọn.+ Kí o rí i pé o pa wọ́n run pátápátá.+ O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ ṣojúure sí wọn rárá.+
3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+
4 Torí wọn ò ní jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ tọ̀ mí lẹ́yìn mọ́, wọ́n á mú kí wọ́n máa sin àwọn ọlọ́run míì;+ Jèhófà máa wá bínú gidigidi sí ọ, kíákíá ló sì máa pa ọ́ run.+
5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+
6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+
7 “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín,+ ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn.+
8 Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín+ pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú,+ kúrò lọ́wọ́* Fáráò ọba Íjíbítì.
9 O mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run tó ṣeé fọkàn tán, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn títí dé ẹgbẹ̀rún ìran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+
10 Àmọ́ ó máa fi ìparun san ẹ̀san fún àwọn tó kórìíra rẹ̀ ní tààràtà.+ Kò ní jáfara láti fìyà jẹ àwọn tó kórìíra rẹ̀; ó máa san wọ́n lẹ́san lójúkojú.
11 Torí náà, rí i pé o pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, kí o máa tẹ̀ lé wọn.
12 “Tí ẹ bá ń tẹ́tí sí àwọn ìdájọ́ yìí, tí ẹ̀ ń tẹ̀ lé wọn, tí ẹ sì ń pa wọ́n mọ́, Jèhófà Ọlọ́run yín máa pa májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá yín dá mọ́, ó sì máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn bó ṣe ṣèlérí.
13 Ó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó máa bù kún ọ, ó sì máa sọ ọ́ di púpọ̀. Àní, ó máa fi ọmọ púpọ̀ bù kún ọ,*+ ó máa fi èso ilẹ̀ rẹ bù kún ọ, ó sì máa fi ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ,+ àwọn ọmọ màlúù nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn nínú agbo ẹran rẹ bù kún ọ ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ pé òun máa fún ọ.+
14 Ìwọ lo máa gba ìbùkún jù nínú gbogbo èèyàn;+ kò ní sí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan láàárín rẹ tí kò ní bímọ, ẹran ọ̀sìn rẹ ò sì ní wà láìbímọ.+
15 Jèhófà máa mú gbogbo àìsàn kúrò lára rẹ; kò sì ní jẹ́ kí ìkankan nínú gbogbo àrùn burúkú tí o ti mọ̀ ní Íjíbítì ṣe ọ́.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó kórìíra rẹ ló máa fi àrùn náà ṣe.
16 Kí o run gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́.+ O* ò gbọ́dọ̀ káàánú wọn,+ o ò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run wọn,+ torí ìdẹkùn ló máa jẹ́ fún ọ.+
17 “Tí o bá sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Àwọn orílẹ̀-èdè yìí pọ̀ jù wá lọ. Báwo ni màá ṣe lé wọn lọ?’+
18 o ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù wọn.+ Rán ara rẹ létí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sí Fáráò àti gbogbo Íjíbítì,+
19 àwọn ìdájọ́* tó rinlẹ̀ tí o fojú ara rẹ rí, àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu+ àti ọwọ́ agbára àti apá tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nà jáde tó fi mú ọ kúrò.+ Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa ṣe sí gbogbo àwọn tí ò ń bẹ̀rù nìyẹn.+
20 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì* títí àwọn tó ṣẹ́ kù+ àti àwọn tó ń fara pa mọ́ fún ọ fi máa pa run.
21 Má gbọ̀n rìrì nítorí wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,+ Ọlọ́run tó tóbi ni, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+
22 “Ó dájú pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú rẹ.+ Kò ní jẹ́ kí o pa wọ́n run kíákíá, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́.
23 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ títí o fi máa ṣẹ́gun wọn tí o sì máa pa wọ́n run pátápátá.+
24 Ó máa fi àwọn ọba wọn lé ọ lọ́wọ́,+ o sì máa pa orúkọ wọn run kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Kò sẹ́ni tó máa dìde sí ọ+ títí o fi máa pa wọ́n run tán.+
25 Kí ẹ dáná sun ère àwọn ọlọ́run wọn tí wọ́n gbẹ́.+ Má ṣe jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tó wà lára wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ mú un fún ara rẹ,+ kó má bàa jẹ́ ìdẹkùn fún ọ, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+
26 O ò gbọ́dọ̀ mú ohun ìríra wọnú ilé rẹ, tí wàá fi di ohun tí a máa pa run bí ohun ìríra náà. Kí o kà á sí ẹ̀gbin, kí o sì kórìíra rẹ̀ pátápátá, torí ohun tí a máa pa run ni.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ara yín.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “tó ṣeyebíye.”
^ Tàbí “lábẹ́ agbára.”
^ Ní Héb., “ó máa bù kún èso ikùn rẹ.”
^ Ní Héb., “Ojú rẹ.”
^ Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”
^ Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”