Jẹ́nẹ́sísì 27:1-46
27 Nígbà tí Ísákì darúgbó, tí ojú rẹ̀ ò sì ríran dáadáa mọ́, ó pe Ísọ̀+ ọmọ rẹ̀ àgbà, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọ mi!” Ísọ̀ fèsì pé: “Èmi nìyí!”
2 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo ti darúgbó báyìí. Mi ò mọ ọjọ́ tí màá kú.
3 Torí náà, ní báyìí, jọ̀ọ́ lọ mú àwọn nǹkan tí o fi ń ṣọdẹ, mú apó rẹ àti ọfà* rẹ, kí o lọ sínú igbó, kí o sì pa ẹran ìgbẹ́ wá fún mi.+
4 Kí o wá se oúnjẹ tó dùn, irú èyí tí mo fẹ́ràn, kí o gbé e wá fún mi, kí n sì jẹ ẹ́, kí n* lè súre fún ọ kí n tó kú.”
5 Àmọ́ Rèbékà ń gbọ́ ohun tí Ísákì ń bá Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ sọ. Ísọ̀ sì lọ sínú igbó kó lè pa ẹran ìgbẹ́ wálé.+
6 Rèbékà sọ fún Jékọ́bù ọmọ+ rẹ̀ pé: “Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tí bàbá rẹ ń sọ fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ pé,
7 ‘Lọ pa ẹran ìgbẹ́ wá fún mi, kí o se oúnjẹ tó dùn, kí n sì jẹ ẹ́, kí n lè súre fún ọ níwájú Jèhófà kí n tó kú.’+
8 Ọmọ mi, fetí sílẹ̀ dáadáa, kí o sì ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ.+
9 Jọ̀ọ́, lọ síbi tí agbo ẹran wà, kí o sì mú méjì nínú àwọn ọmọ ewúrẹ́ tó dáa jù wá fún mi, kí n lè fi wọ́n se oúnjẹ tó dùn fún bàbá rẹ, bó ṣe máa ń fẹ́ kó rí.
10 Kí o wá gbé e lọ fún bàbá rẹ kó jẹ ẹ́, kó lè súre fún ọ kó tó kú.”
11 Jékọ́bù sọ fún Rèbékà ìyá rẹ̀ pé: “Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n mi nírun lára,+ àmọ́ èmi ò nírun lára.
12 Tí bàbá mi bá fọwọ́ kàn mí lára+ ńkọ́? Ó dájú pé yóò mọ̀ pé ṣe ni mo tan òun, màá wá mú ègún wá sórí ara mi dípò ìbùkún.”
13 Ni ìyá rẹ̀ bá sọ fún un pé: “Ọmọ mi, kí ègún tó yẹ kó wá sórí rẹ kọjá sórí mi. Ṣáà lọ ṣe ohun tí mo sọ fún ọ, lọ bá mi mú wọn wá.”+
14 Torí náà, ó lọ mú wọn wá fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì se oúnjẹ tó dùn bí bàbá rẹ̀ ṣe máa ń fẹ́ kó rí.
15 Lẹ́yìn náà, Rèbékà mú aṣọ tó dáa jù tó jẹ́ ti Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà, èyí tó ní nínú ilé, ó sì wọ̀ ọ́ fún Jékọ́bù+ ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò.
16 Ó tún fi awọ àwọn ọmọ ewúrẹ́ náà bo ọwọ́ rẹ̀ àti ibi tí kò nírun ní ọrùn+ rẹ̀.
17 Ó wá gbé oúnjẹ aládùn náà àti búrẹ́dì tó ṣe lé Jékọ́bù+ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.
18 Ló bá wọlé lọ bá bàbá rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bàbá mi!” Ó fèsì pé: “Èmi nìyí! Ọmọ mi, ìwọ ta ni?”
19 Jékọ́bù sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Èmi ni Ísọ̀ àkọ́bí+ rẹ. Mo ti ṣe ohun tí o ní kí n ṣe. Jọ̀ọ́, dìde jókòó, kí o sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí mo pa, kí o* lè súre fún mi.”+
20 Ni Ísákì bá bi ọmọ rẹ̀ pé: “Báwo lo ṣe tètè rí i pa, ọmọ mi?” Ó fèsì pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ló jẹ́ kí n tètè rí i pa.”
21 Ísákì sọ fún Jékọ́bù pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́ sún mọ́ mi kí n lè fọwọ́ kan ara rẹ, kí n lè mọ̀ bóyá ìwọ ni Ísọ̀ ọmọ mi lóòótọ́ tàbí ìwọ kọ́.”+
22 Torí náà, Jékọ́bù sún mọ́ Ísákì bàbá rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án lára, ó sì sọ pé: “Ohùn Jékọ́bù ni ohùn yìí, àmọ́ ọwọ́ yìí, ti Ísọ̀+ ni.”
23 Kò dá a mọ̀, torí ọwọ́ rẹ̀ nírun bí ọwọ́ Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Torí náà, ó súre fún un.+
24 Lẹ́yìn náà, ó bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ísọ̀ ọmọ mi lóòótọ́?” Ó fèsì pé: “Èmi ni.”
25 Ó wá sọ pé: “Ọmọ mi, mú lára ẹran ìgbẹ́ tí o pa wá, kí n lè jẹ ẹ́, kí n* sì súre fún ọ.” Torí náà, ó gbé e wá fún un, ó sì jẹ ẹ́, ó tún gbé wáìnì wá fún un, ó sì mu ún.
26 Lẹ́yìn náà, Ísákì bàbá rẹ̀ sọ fún un pé: “Ọmọ mi, jọ̀ọ́ sún mọ́ mi, kó o sì fi ẹnu kò mí lẹ́nu.”+
27 Ó sún mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó ń gbọ́ òórùn aṣọ+ tó wọ̀. Ó sì súre fún un, ó ní:
“Wò ó, òórùn ọmọ mi dà bí òórùn pápá tí Jèhófà bù kún.
28 Kí Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ìrì sẹ̀ fún ọ láti ọ̀run,+ kó fún ọ ní àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá ní ayé,+ kó sì fún ọ ní ọkà tó pọ̀ àti wáìnì tuntun.+
29 Kí àwọn èèyàn máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹrí ba fún ọ. Kí o di ọ̀gá lórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ọmọ ìyá rẹ sì máa tẹrí ba fún ọ.+ Kí ègún wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá gégùn-ún fún ọ, kí ìbùkún sì wà lórí ẹnikẹ́ni tó bá ń súre fún ọ.”+
30 Bí Ísákì ṣe súre fún Jékọ́bù tán, tí Jékọ́bù sì kúrò lọ́dọ̀ Ísákì bàbá rẹ̀ ni Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ dé láti oko ọdẹ.+
31 Òun náà se oúnjẹ tó dùn, ó gbé e wá fún bàbá rẹ̀, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dìde, kí o sì jẹ lára ẹran ìgbẹ́ tí ọmọ rẹ pa, kí o* lè súre fún mi.”
32 Ni Ísákì bàbá rẹ̀ bá bi í pé: “Ìwọ ta ni?” Ó fèsì pé: “Èmi ọmọ rẹ ni, Ísọ̀+ àkọ́bí rẹ.”
33 Ísákì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ó sì bi í pé: “Ta ló wá pa ẹran ìgbẹ́, tó sì gbé e wá fún mi? Mo ti jẹ ẹ́ kí o tó dé, mo sì ti súre fún ẹni náà. Ó sì dájú pé yóò rí ìbùkún gbà!”
34 Nígbà tí Ísọ̀ gbọ́ ohun tí bàbá rẹ̀ sọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe tantan torí ohun tó ṣẹlẹ̀ dùn ún wọra, ó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá+ mi, súre fún mi, àní kí o súre fún èmi náà!”
35 Àmọ́ ó sọ fún un pé: “Àbúrò rẹ ti wá fi ẹ̀tàn gba ìbùkún tó yẹ kí o gbà.”
36 Ló bá fèsì pé: “Abájọ tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Jékọ́bù,* ẹ̀ẹ̀mejì+ ló ti gba ipò mi báyìí! Ó ti kọ́kọ́ gba ogún ìbí mi,+ ó tún gba ìbùkún+ tó jẹ́ tèmi!” Ó wá sọ pé: “Ṣé o ò ṣẹ́ ìbùkún kankan kù fún mi ni?”
37 Àmọ́ Ísákì dá Ísọ̀ lóhùn pé: “Mo ti fi ṣe olórí rẹ,+ mo ti fi gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, mo sì ti fi ọkà àti wáìnì tuntun bù kún un.+ Kí ló wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”
38 Ísọ̀ sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, ṣé ìbùkún kan ṣoṣo lo ní ni? Súre fún mi, bàbá mi, àní kí o súre fún èmi náà!” Ni Ísọ̀ bá ké, ó sì bú sẹ́kún.+
39 Ísákì bàbá rẹ̀ wá sọ fún un pé:
“Wò ó, ibi tó jìnnà sí àwọn ilẹ̀ tó lọ́ràá ní ayé àti ibi tó jìnnà sí ìrì tó ń sẹ̀ láti ọ̀run ni wàá máa gbé.+
40 Idà rẹ ni yóò máa mú ọ wà láàyè,+ àbúrò+ rẹ sì ni ìwọ yóò máa sìn. Àmọ́ tí o kò bá lè fara dà á mọ́, ó dájú pé wàá ṣẹ́ àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.”+
41 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú torí pé bàbá rẹ̀ ti súre fún un,+ Ísọ̀ sì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí a máa ṣọ̀fọ̀ bàbá mi ti ń sún mọ́lé.+ Lẹ́yìn náà, ṣe ni màá pa Jékọ́bù àbúrò mi.”
42 Nígbà tí wọ́n sọ fún Rèbékà ohun tí Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà sọ, ojú ẹsẹ̀ ló ránṣẹ́ pe Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó! Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń wá bó ṣe máa pa ọ́ kó lè gbẹ̀san.*
43 Torí náà, ọmọ mi, ṣe ohun tí mo bá sọ fún ọ. Gbéra, kí o sì sá lọ sọ́dọ̀ Lábánì arákùnrin mi ní Háránì.+
44 Kí o lọ gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ fúngbà díẹ̀ títí inú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀,
45 títí inú tó ń bí ẹ̀gbọ́n rẹ sí ọ á fi rọlẹ̀, tí á sì gbàgbé ohun tí o ṣe sí i. Màá wá ránṣẹ́ sí ọ pé kí o pa dà wá láti ibẹ̀. Kò yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì kú mọ́ mi lọ́wọ́ lọ́jọ́ kan náà!”
46 Lẹ́yìn ìyẹn, Rèbékà ń tẹnu mọ́ ọn fún Ísákì pé: “Àwọn ọmọbìnrin Hétì+ ti fayé sú mi. Bí Jékọ́bù bá lọ fẹ́ ìyàwó nínú àwọn ọmọ Hétì, irú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, kí làǹfààní pé mo wà láàyè?”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ọrun.”
^ Tàbí “kí ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Di Gìgísẹ̀ Mú; Ẹni Tó Gba Ipò Onípò.”
^ Tàbí “ń fi bó ṣe fẹ́ pa ọ́ tu ara rẹ̀ nínú.”