Jẹ́nẹ́sísì 29:1-35
29 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó sì forí lé ilẹ̀ àwọn ará Ìlà Oòrùn.
2 Ó wá rí kànga kan nínú pápá, ó sì rí agbo àgùntàn mẹ́ta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, torí wọ́n máa ń fún àwọn agbo ẹran lómi látinú kànga yẹn. Òkúta ńlá kan wà ní ẹnu kànga náà.
3 Nígbà tí gbogbo agbo ẹran náà ti kóra jọ síbẹ̀, wọ́n yí òkúta náà kúrò ní ẹnu kànga náà, wọ́n fún àwọn agbo ẹran náà lómi, wọ́n sì dá òkúta pa dà síbi tó wà, ní ẹnu kànga náà.
4 Jékọ́bù bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin èèyàn mi, ibo lẹ ti wá?” Wọ́n fèsì pé: “Háránì+ la ti wá.”
5 Ó bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ mọ Lábánì+ ọmọ ọmọ Náhórì?”+ Wọ́n fèsì pé: “A mọ̀ ọ́n.”
6 Ló bá bi wọ́n pé: “Ṣé àlàáfíà ló wà?” Wọ́n fèsì pé: “Àlàáfíà ni. Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ̀ náà ló ń da àgùntàn bọ̀ yìí!”
7 Ló bá sọ pé: “Ọ̀sán ṣẹ̀ṣẹ̀ pọ́n ni. Kò tíì tó àkókò láti kó agbo ẹran jọ. Ẹ fún àwọn àgùntàn lómi, kí ẹ sì lọ fún wọn ní oúnjẹ.”
8 Wọ́n fèsì pé: “Wọn ò gbà wá láyè ká ṣe bẹ́ẹ̀, ó dìgbà tí a bá kó gbogbo agbo ẹran jọ, tí wọ́n sì yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga náà. Lẹ́yìn ìyẹn, a lè fún àwọn àgùntàn lómi.”
9 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Réṣẹ́lì kó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ dé, torí darandaran ni Réṣẹ́lì.
10 Nígbà tí Jékọ́bù rí Réṣẹ́lì ọmọ Lábánì, arákùnrin ìyá rẹ̀ àti àwọn àgùntàn Lábánì, Jékọ́bù sún mọ́ ibi kànga náà lójú ẹsẹ̀, ó yí òkúta kúrò ní ẹnu rẹ̀, ó sì fún àwọn àgùntàn Lábánì arákùnrin ìyá rẹ̀ lómi.
11 Jékọ́bù wá fi ẹnu ko Réṣẹ́lì lẹ́nu, ó ké, ó sì bú sẹ́kún.
12 Jékọ́bù sì sọ fún Réṣẹ́lì pé mọ̀lẹ́bí* bàbá rẹ̀ ni òun àti pé òun ni ọmọ Rèbékà. Réṣẹ́lì bá sáré lọ sọ fún bàbá rẹ̀.
13 Gbàrà tí Lábánì+ gbọ́ ìròyìn nípa Jékọ́bù ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó sáré lọ pàdé rẹ̀. Ó gbá a mọ́ra, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sínú ilé rẹ̀. Jékọ́bù wá ń ròyìn gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ fún Lábánì.
14 Lábánì sọ fún un pé: “Ó dájú pé egungun mi àti ẹran ara mi ni ọ́.”* Torí náà, ó dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan gbáko.
15 Lábánì wá sọ fún Jékọ́bù pé: “Ṣé wàá máa bá mi ṣiṣẹ́ láìgba nǹkan kan torí o jẹ́ mọ̀lẹ́bí*+ mi ni? Sọ fún mi, kí lo fẹ́ kí n fún ọ?”+
16 Lábánì ní ọmọbìnrin méjì. Ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Líà, àbúrò sì ń jẹ́ Réṣẹ́lì.+
17 Ojú Líà kò fani mọ́ra, àmọ́ Réṣẹ́lì wuni, ó sì rẹwà gan-an.
18 Jékọ́bù wá nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì gidigidi, ó sì sọ pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje torí Réṣẹ́lì+ ọmọ rẹ tó jẹ́ àbúrò Líà.”
19 Lábánì fèsì pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n fún ọ ju kí n fún ọkùnrin míì. Máa gbé lọ́dọ̀ mi.”
20 Jékọ́bù wá fi ọdún méje ṣiṣẹ́ fún Lábánì nítorí Réṣẹ́lì,+ àmọ́ bí ọjọ́ díẹ̀ ló rí lójú rẹ̀ torí ìfẹ́ tó ní fún Réṣẹ́lì.
21 Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù sọ fún Lábánì pé: “Fún mi ní ìyàwó mi torí ọjọ́ mi ti pé, kí o sì jẹ́ kí n bá a ní àṣepọ̀.”
22 Ni Lábánì bá kó gbogbo èèyàn ibẹ̀ jọ, ó sì se àsè.
23 Àmọ́ ní alẹ́, Líà ló mú lọ fún un, kó lè bá a ní àṣepọ̀.
24 Lábánì tún fún Líà ọmọ rẹ̀ ní Sílípà ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, kó lè jẹ́ ìránṣẹ́+ Líà.
25 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jékọ́bù rí i pé Líà ni! Torí náà, ó sọ fún Lábánì pé: “Kí lo ṣe fún mi yìí? Ṣebí torí Réṣẹ́lì ni mo ṣe sìn ọ́? Kí ló dé tí o fi tàn mí jẹ?”+
26 Lábánì fèsì pé: “Kì í ṣe àṣà wa níbí pé kí àbúrò lọ ilé ọkọ ṣáájú ẹ̀gbọ́n.
27 Ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin yìí fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, màá fún ọ ní obìnrin kejì yìí tí o bá sìn mí fún ọdún méje sí i.”+
28 Jékọ́bù ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà fún ọ̀sẹ̀ kan. Lẹ́yìn náà, Lábánì fún un ní Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya.
29 Lábánì tún fún Réṣẹ́lì ọmọ rẹ̀ ní Bílíhà,+ ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ kó lè di ìránṣẹ́+ Réṣẹ́lì.
30 Jékọ́bù wá bá Réṣẹ́lì pẹ̀lú ní àṣepọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ Réṣẹ́lì ju Líà lọ, ó sì fi ọdún méje+ míì ṣiṣẹ́ fún Lábánì.
31 Nígbà tí Jèhófà rí i pé Jékọ́bù kò fẹ́ràn* Líà, ó jẹ́ kí Líà lóyún,*+ àmọ́ Réṣẹ́lì yàgàn.+
32 Líà wá lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Rúbẹ́nì.*+ Ó sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti rí ìyà+ tó ń jẹ mí, ọkọ mi á wá nífẹ̀ẹ́ mi báyìí.”
33 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé Jèhófà ti fetí sílẹ̀, ó rí i pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ mi, torí náà, ó tún fún mi ní èyí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Síméónì.*+
34 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, ọkọ mi yóò fà mọ́ mi, torí mo ti bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún un.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Léfì.*+
35 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, màá yin Jèhófà.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.*+ Lẹ́yìn ìyẹn, kò bímọ mọ́.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “arákùnrin.”
^ Tàbí “ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.”
^ Ní Héb., “arákùnrin.”
^ Ní Héb., “kórìíra.”
^ Ní Héb., “ó ṣí ilé ọlẹ̀ rẹ̀.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ọmọkùnrin Kan Rèé!”
^ Ó túmọ̀ sí “Ó Ń Gbọ́.”
^ Ó túmọ̀ sí “Rọ̀ Mọ́; Fà Mọ́.”
^ Ó túmọ̀ sí “Ìyìn; Ẹni Tí Ìyìn Yẹ.”