Jóṣúà 6:1-27

  • Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ (1-21)

  • Wọ́n dá ẹ̀mí Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ sí (22-27)

6  Wọ́n ti ìlú Jẹ́ríkò pinpin torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; ẹnì kankan ò jáde, ẹnì kankan ò sì wọlé.+  Nígbà náà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò àti ọba rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú.+  Kí gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin ogun yan yí ìlú náà ká, kí ẹ lọ yí ká ìlú náà lẹ́ẹ̀kan. Kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà.  Jẹ́ kí àlùfáà méje mú ìwo àgbò méje dání níwájú Àpótí náà. Àmọ́ ní ọjọ́ keje, kí ẹ yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀méje, kí àwọn àlùfáà sì fun àwọn ìwo náà.+  Tí ìwo àgbò náà bá ti dún, gbàrà tí ẹ bá ti gbọ́ ìró ìwo náà,* kí gbogbo èèyàn kígbe tantan láti jagun. Ògiri ìlú náà á wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ,+ kí àwọn èèyàn náà sì gòkè lọ, kí kálukú máa lọ tààràtà.”  Jóṣúà ọmọ Núnì wá pe àwọn àlùfáà jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé àpótí májẹ̀mú, kí àlùfáà méje sì mú ìwo àgbò méje dání níwájú Àpótí Jèhófà.”+  Ó sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ máa lọ, kí ẹ yan yí ìlú náà ká, kí àwùjọ àwọn ọmọ ogun+ sì máa lọ níwájú Àpótí Jèhófà.”  Bí Jóṣúà ṣe sọ fún àwọn èèyàn náà gẹ́lẹ́, àwọn àlùfáà méje tó mú ìwo àgbò méje dání níwájú Jèhófà lọ síwájú, wọ́n sì fun àwọn ìwo náà, àpótí májẹ̀mú Jèhófà sì ń tẹ̀ lé wọn.  Àwùjọ àwọn ọmọ ogun náà ń lọ níwájú àwọn àlùfáà tó ń fun ìwo, àwọn ọmọ ogun tó sì wà lẹ́yìn ń tẹ̀ lé Àpótí náà bí wọ́n ṣe ń fun ìwo náà léraléra. 10  Jóṣúà ti pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ kígbe, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gbọ́ ohùn yín. Ọ̀rọ̀ kankan ò gbọ́dọ̀ ti ẹnu yín jáde títí di ọjọ́ tí mo bá sọ fún yín pé, ‘Ẹ kígbe!’ Ìgbà yẹn ni kí ẹ kígbe.” 11  Ó mú kí wọ́n gbé Àpótí Jèhófà yí ìlú náà ká, wọ́n gbé e yí i ká lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ibùdó, wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú. 12  Jóṣúà dìde ní àárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, àwọn àlùfáà sì gbé Àpótí+ Jèhófà, 13  àwọn àlùfáà méje tó mú ìwo àgbò méje dání sì ń lọ níwájú Àpótí Jèhófà, wọ́n ń fun ìwo náà léraléra. Àwùjọ àwọn ọmọ ogun ń lọ níwájú wọn, àwọn ọmọ ogun tó sì wà lẹ́yìn ń tẹ̀ lé Àpótí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń fun ìwo léraléra. 14  Wọ́n yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan ní ọjọ́ kejì, lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà sí ibùdó. Ohun tí wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹ́fà nìyẹn.+ 15  Ní ọjọ́ keje, wọ́n dìde ní àárọ̀ kùtù, gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n sì yan yí ìlú náà ká lọ́nà kan náà lẹ́ẹ̀méje. Ọjọ́ yẹn nìkan ni wọ́n yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀méje.+ 16  Ní ìgbà keje, àwọn àlùfáà fun ìwo, Jóṣúà sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ kígbe,+ torí Jèhófà ti fún yín ní ìlú náà! 17  Kí ẹ pa ìlú náà run àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀;+ Jèhófà ló ni gbogbo rẹ̀. Ráhábù+ aṣẹ́wó nìkan ni kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, òun àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé, torí ó fi àwọn tí a rán níṣẹ́ pa mọ́.+ 18  Àmọ́ ẹ yẹra fún ohun tí a máa pa run,+ kí ọkàn yín má bàa fà sí i, kí ẹ sì mú un,+ tí ẹ ó fi mú àjálù* bá ibùdó Ísírẹ́lì, tí ẹ ó sì sọ ọ́ di ohun tí a máa pa run.+ 19  Àmọ́ gbogbo fàdákà, wúrà, àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe jẹ́ ohun mímọ́ fún Jèhófà.+ Ibi ìṣúra Jèhófà ni kí ẹ kó o lọ.”+ 20  Ni àwọn èèyàn náà bá kígbe nígbà tí wọ́n fun ìwo.+ Gbàrà tí àwọn èèyàn náà gbọ́ ìró ìwo, tí wọ́n sì kígbe tantan láti jagun, ògiri ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ.+ Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn náà wọnú ìlú náà lọ, kálukú ń lọ tààràtà, wọ́n sì gba ìlú náà. 21  Wọ́n fi idà pa gbogbo ohun tó wà nínú ìlú náà run, wọ́n pa ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà, akọ màlúù, àgùntàn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 22  Jóṣúà sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé: “Ẹ lọ sínú ilé aṣẹ́wó náà, kí ẹ sì mú obìnrin náà àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde, bí ẹ ṣe búra fún un gẹ́lẹ́.”+ 23  Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ṣe amí náà wọlé lọ, wọ́n sì mú Ráhábù, bàbá rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jáde; àní wọ́n kó gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde,+ wọ́n sì kó wọn wá sí ibì kan lẹ́yìn ibùdó Ísírẹ́lì, ohunkóhun ò ṣe wọ́n. 24  Wọ́n wá dáná sun ìlú náà àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. Àmọ́ wọ́n kó fàdákà, wúrà àti àwọn ohun tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe lọ síbi ìṣúra nínú ilé Jèhófà.+ 25  Ráhábù àti agbo ilé bàbá rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ nìkan ni Jóṣúà dá ẹ̀mí wọn sí;+ ó sì ń gbé ní Ísírẹ́lì títí dòní,+ torí ó fi àwọn tí Jóṣúà rán pé kí wọ́n lọ ṣe amí Jẹ́ríkò pa mọ́.+ 26  Ìgbà yẹn ni Jóṣúà búra* pé: “Níwájú Jèhófà, ègún ni fún ẹni tó bá gbìyànjú láti tún ìlú Jẹ́ríkò yìí kọ́. Tó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ẹ̀mí àkọ́bí rẹ̀ ló máa fi dí i, tó bá sì gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nàró, ẹ̀mí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ló máa fi dí i.”+ 27  Jèhófà wà pẹ̀lú Jóṣúà,+ òkìkí rẹ̀ sì kàn ká gbogbo ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìró ìwo tó ń dún lala.”
Tàbí “wàhálà; ìtanùlẹ́gbẹ́.”
Tàbí kó jẹ́, “mú kí àwọn èèyàn náà búra.”