Jeremáyà 31:1-40

  • Àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì á tún pa dà máa gbé ilẹ̀ wọn (1-30)

    • Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ (15)

  • Májẹ̀mú tuntun (31-40)

31  “Ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “màá di Ọlọ́run gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+   Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Àwọn tó bọ́ lọ́wọ́ idà rí ojú rere ní aginjùNígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn lọ sí ibi ìsinmi rẹ̀.”   Jèhófà ti fara hàn mí láti ọ̀nà jíjìn, ó sì sọ pé: “Ìfẹ́ tí mo ní sí ọ jẹ́ ìfẹ́ ayérayé. Ìdí nìyẹn tí mo fi fà ọ́ mọ́ra pẹ̀lú ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.*+   Síbẹ̀ náà, màá tún ọ kọ́ bí ilé, wàá sì dà bí ilé tí a tún kọ́.+ Ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, wàá tún pa dà mú ìlù tanboríìnì rẹWàá sì máa jó lọ tayọ̀tayọ̀.*+   Wàá tún pa dà gbin àwọn ọgbà àjàrà sórí àwọn òkè Samáríà;+Àwọn tó gbìn wọ́n á sì gbádùn èso wọn.+   Nítorí ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí àwọn olùṣọ́ tó wà lórí àwọn òkè Éfúrémù máa ké jáde pé: ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká lọ sí Síónì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.’”+   Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ fi ìdùnnú kọrin sí Jékọ́bù. Ẹ sì kígbe ayọ̀ nítorí ẹ ti ga ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ.+ Ẹ kéde rẹ̀; ẹ yin Ọlọ́run, kí ẹ sì sọ pé,‘Jèhófà, gba àwọn èèyàn rẹ là, àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì.’+   Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ àríwá.+ Màá sì kó wọn jọ láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+ Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ máa wà lára wọn,+Aboyún àti ẹni tó ń rọbí, gbogbo wọn pa pọ̀. Bí ìjọ ńlá ni wọ́n máa pa dà sí ibí yìí.+   Wọ́n á wá pẹ̀lú ẹkún.+ Màá máa darí wọn bí wọ́n ṣe ń wá ojú rere. Màá ṣamọ̀nà wọn lọ sí ìṣàn* omi,+Lórí ọ̀nà tó tẹ́jú tí wọn ò ti ní kọsẹ̀. Nítorí èmi ni Bàbá Ísírẹ́lì, Éfúrémù sì ni àkọ́bí mi.”+ 10  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+ “Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ. Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+ 11  Nítorí Jèhófà máa ra Jékọ́bù pa dà+Á sì gbà á* lọ́wọ́ ẹni tó lágbára jù ú lọ.+ 12  Wọ́n á wá, wọ́n á sì kígbe ayọ̀ ní ibi gíga Síónì+Inú wọn á dùn nítorí oore* Jèhófà,Nítorí ọkà àti wáìnì tuntun+ pẹ̀lú òróró,Nítorí àwọn ọmọ inú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran.+ Wọ́n* á dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+Wọn kò sì ní ráágó mọ́.”+ 13  “Ní àkókò yẹn, wúńdíá á máa jó ijó ayọ̀,Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn àgbà ọkùnrin á máa jó pa pọ̀.+ Màá sọ ọ̀fọ̀ wọn di ìdùnnú.+ Màá tù wọ́n nínú, màá sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ní.+ 14  Màá fi ọ̀pọ̀ nǹkan* tẹ́ àwọn àlùfáà* lọ́rùn,Oore mi á sì tẹ́ àwọn èèyàn mi lọ́rùn,”+ ni Jèhófà wí. 15  “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,+ ìdárò àti ẹkún kíkorò: Réṣẹ́lì ń sunkún nítorí àwọn ọmọkùnrin* rẹ̀.+ Wọ́n tù ú nínú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò gbà,Torí pé wọn kò sí mọ́.’”+ 16  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “‘Má sunkún mọ́, má sì da omi lójú mọ́,Nítorí èrè wà fún iṣẹ́ rẹ,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọ́n á pa dà láti ilẹ̀ ọ̀tá.’+ 17  ‘Ìrètí wà fún ọ ní ọjọ́ ọ̀la,’+ ni Jèhófà wí. ‘Àwọn ọmọ rẹ á sì pa dà sí ilẹ̀ wọn.’”+ 18  “Mo ti gbọ́ tí Éfúrémù ń kérora,‘O ti tọ́ mi sọ́nà, mo sì ti gba ìtọ́sọ́nà,Bí ọmọ màlúù tí a kò fi iṣẹ́ kọ́. Mú mi pa dà, màá sì ṣe tán láti yí pa dà,Nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi. 19  Torí pé lẹ́yìn tí mo pa dà, mo kẹ́dùn;+Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi yé mi, mo gbá itan mi tẹ̀dùntẹ̀dùn. Ojú tì mí, ẹ̀tẹ́ sì bá mi,+Nítorí mo ti ru ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’” 20  “Ǹjẹ́ Éfúrémù kì í ṣe ọmọ mi àtàtà, ọmọ tí mo nífẹ̀ẹ́?+ Torí bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀ mo ṣì ń rántí rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọkàn* mi fi gbé sókè nítorí rẹ̀.+ Ó sì dájú pé màá ṣàánú rẹ̀,” ni Jèhófà wí.+ 21  “Ri àwọn àmì ojú ọ̀nà mọ́lẹ̀ fún ará rẹ,Ri àwọn òpó àmì mọ́lẹ̀.+ Fiyè sí òpópónà, ọ̀nà tí o máa gbà.+ Pa dà, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì, pa dà wá sí àwọn ìlú rẹ. 22  Ìgbà wo lo máa ṣiyèméjì dà, ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin? Nítorí Jèhófà ti dá ohun tuntun kan sí ayé: Obìnrin kan á máa fìtara lé ọkùnrin kan kiri.” 23  Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Wọ́n á tún ọ̀rọ̀ yìí sọ ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà: ‘Kí Jèhófà bù kún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo,+ ìwọ òkè mímọ́.’+ 24  Inú rẹ̀ ni Júdà àti gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ á jọ máa gbé, àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń da agbo ẹran.+ 25  Nítorí ẹni* tí àárẹ̀ mú ni màá tẹ́ lọ́rùn, màá sì pèsè fún gbogbo ẹni* tó jẹ́ aláìní.”+ 26  Bí mo ṣe gbọ́ èyí ni mo jí, mo la ojú mi, oorun mi sì dùn mọ́ mi. 27  “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá sọ àtọmọdọ́mọ* ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà di púpọ̀, tí màá sì sọ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn di púpọ̀.”+ 28  “Bí mo ṣe kíyè sí wọn láti fà wọ́n tu, láti ya wọ́n lulẹ̀, láti fà wọ́n ya, láti pa wọ́n run àti láti ṣe wọ́n léṣe,+ bẹ́ẹ̀ ni màá kíyè sí wọn láti kọ́ wọn bí ilé àti láti gbìn wọ́n,”+ ni Jèhófà wí. 29  “Ní àkókò yẹn, wọn kò tún ní sọ pé, ‘Àwọn baba jẹ èso àjàrà kíkan, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan.’*+ 30  Àmọ́ nígbà náà, kálukú máa kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹni tó bá sì jẹ èso àjàrà kíkan ni eyín máa kan.” 31  “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.+ 32  Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ‘májẹ̀mú mi tí wọ́n dà,+ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọ̀gá wọn tòótọ́,’* ni Jèhófà wí.” 33  “Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,” ni Jèhófà wí. “Màá fi òfin mi sínú wọn,+ inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.”+ 34  “Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ẹnì kejì rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’+ nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn,”+ ni Jèhófà wí. “Nítorí màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”+ 35  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,Ẹni tó ń mú kí oòrùn máa tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,Tó sì ṣe òfin* pé kí òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ máa tàn ní òru,Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo,Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun:+ 36  “‘Bí àwọn ìlànà yìí bá yí pa dà Nìkan ni àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì kò fi ní jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi mọ́,’ ni Jèhófà wí.”+ 37  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “‘Àyàfi bí a bá lè díwọ̀n ọ̀run lókè, tí a sì lè wá ìpìlẹ̀ ayé kàn nísàlẹ̀, ni màá tó kọ gbogbo àtọmọdọ́mọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ torí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe,’ ni Jèhófà wí.”+ 38  “Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “nígbà tí wọ́n á kọ́ ìlú+ fún Jèhófà láti Ilé Gogoro Hánánélì+ dé Ẹnubodè Igun.+ 39  Okùn ìdíwọ̀n+ máa jáde lọ tààrà sí òkè Gárébù, á sì yíjú sí Góà. 40  Gbogbo àfonífojì* àwọn òkú àti ti eérú* pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ onípele títí dé Àfonífojì Kídírónì,+ títí lọ dé igun Ẹnubodè Ẹṣin,+ lápá ìlà oòrùn, yóò jẹ́ ohun mímọ́ fún Jèhófà.+ A kò ní fà á tu láé, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní ya á lulẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí mò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ.”
Tàbí “máa jó lọ bí àwọn tó ń jó tẹ̀ríntẹ̀rín.”
Tàbí “àfonífojì.”
Tàbí “gbà á pa dà.”
Tàbí “àwọn ohun rere látọ̀dọ̀.”
Tàbí “Ọkàn wọn.”
Ní Héb., “sísanra.”
Tàbí “ọkàn àwọn àlùfáà.”
Tàbí “ọmọ.”
Ní Héb., “ìfun.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “eyín wọn kò mú.”
Tàbí kó jẹ́, “ọkọ wọn.”
Tàbí “pa àṣẹ.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.