Jeremáyà 51:1-64
51 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá ru ẹ̀fúùfù tó ń pani run sókè
Sí Bábílónì+ àti sí àwọn tó ń gbé ní Lẹbu-kámáì.*
2 Màá rán àwọn tó ń fẹ́ ọkà sí Bábílónì,Wọ́n á fẹ́ ẹ bí ọkà, wọ́n á sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro;Wọ́n á wá dojú kọ ọ́ láti ibi gbogbo ní ọjọ́ àjálù.+
3 Kí tafàtafà má lè tẹ* ọrun rẹ̀.
Kí ẹnikẹ́ni tó wọ ẹ̀wù irin má sì lè nàró.
Ẹ má ṣàánú àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀.+
Ẹ pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run pátápátá.
4 Wọ́n á ṣubú, wọ́n á sì kú ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,A ó sì gún wọn ní àgúnyọ ní àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀.+
5 Nítorí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti Júdà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.*+
Àmọ́, ẹ̀bi kún ilẹ̀* wọn lójú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.
6 Ẹ sá kúrò nínú Bábílónì,Kí ẹ sì sá nítorí ẹ̀mí* yín.+
Ẹ má ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Nítorí àkókò ẹ̀san Jèhófà ti tó.
Ó máa san ohun tó ṣe pa dà fún un.+
7 Bábílónì jẹ́ ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà;Ó mú kí gbogbo ayé mu àmupara.
Àwọn orílẹ̀-èdè ti mu nínú wáìnì rẹ̀ ní àmuyó;+Ìdí nìyẹn tí orí àwọn orílẹ̀-èdè fi dà rú.+
8 Lójijì, Bábílónì ṣubú, ó sì fọ́.+
Ẹ pohùn réré ẹkún fún un! +
Ẹ fún un ní básámù nítorí ìrora rẹ̀; bóyá ara rẹ̀ máa yá.”
9 “A gbìyànjú láti mú Bábílónì lára dá, ṣùgbọ́n ara rẹ̀ kò yá.
Ẹ fi í sílẹ̀, kí kálukú máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.+
Nítorí ìdájọ́ rẹ̀ ti dé ọ̀run;Ó ti ga sókè bíi sánmà.+
10 Jèhófà ti mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ fún wa.+
Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a ròyìn iṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa ní Síónì.”+
11 “Ẹ dán ọfà;+ ẹ gbé àwọn apata ribiti.*
Jèhófà ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Mídíà sókè,+Torí ó ní in lọ́kàn láti pa Bábílónì run.
Nítorí ẹ̀san Jèhófà nìyí, ẹ̀san nítorí tẹ́ńpìlì rẹ̀.
12 Ẹ gbé àmì kan sókè*+ sí àwọn ògiri Bábílónì.
Ẹ túbọ̀ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì yan àwọn olùṣọ́ sẹ́nu iṣẹ́.
Ẹ múra àwọn tó máa lúgọ de Bábílónì sílẹ̀.
Nítorí Jèhófà ti ro ohun tó máa ṣe,Ó sì máa ṣe ohun tí ó ti ṣèlérí pé òun máa ṣe sí àwọn tó ń gbé ní Bábílónì.”+
13 “Ìwọ obìnrin tó ń gbé lórí omi púpọ̀,+Tí o ní ìṣúra tó pọ̀ rẹpẹtẹ,+Òpin rẹ ti dé, o ti dé òpin* èrè tí ò ń jẹ.+
14 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti fi ara* rẹ̀ búra pé,‘Màá fi èèyàn kún inú rẹ, wọ́n á pọ̀ bí eéṣú,Wọ́n á sì kígbe ìṣẹ́gun lórí rẹ.’+
15 Òun ni Aṣẹ̀dá ayé tó fi agbára rẹ̀ dá a,Ẹni tó fi ọgbọ́n rẹ̀ dá ilẹ̀ tó ń mú èso jáde+Tó sì fi òye rẹ̀ na ọ̀run bí aṣọ.+
16 Nígbà tí ó bá fọhùn,Omi ojú ọ̀run á ru gùdù,Á sì mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé.
Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò,Ó sì ń mú ẹ̀fúùfù wá láti inú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+
17 Kálukú ń hùwà láìronú, wọn ò sì ní ìmọ̀.
Ojú á ti gbogbo oníṣẹ́ irin nítorí ère tí wọ́n ṣe;+Nítorí ère onírin* rẹ̀ jẹ́ èké,Kò sì sí ẹ̀mí* kankan nínú wọn.+
18 Ẹ̀tàn* ni wọ́n,+ iṣẹ́ yẹ̀yẹ́ sì ni wọ́n.
Nígbà tí ọjọ́ ìbẹ̀wò wọn bá dé, wọ́n á ṣègbé.
19 Ọlọ́run* Jékọ́bù kò dà bí àwọn nǹkan yìí,Nítorí òun ni Ẹni tó dá ohun gbogbo,Kódà ọ̀pá tó jẹ́ ohun ìní* rẹ̀.+
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”+
20 “Kùmọ̀ ogun lo jẹ́ fún mi, ohun ìjà ogun,Màá fi ọ́ fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè túútúú.
Màá fi ọ́ pa àwọn ìjọba run.
21 Màá fi ọ́ fọ́ ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹni tí ó gùn ún túútúú.
22 Màá fi ọ́ fọ́ ọkùnrin àti obìnrin túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àgbà ọkùnrin àti ọmọkùnrin túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin túútúú.
23 Màá fi ọ́ fọ́ olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran rẹ̀ túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àwọn ẹran ìtúlẹ̀ rẹ̀ túútúú.
Màá fi ọ́ fọ́ àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè túútúú.
24 Màá san án pa dà fun Bábílónì àti fún gbogbo àwọn tó ń gbé ní KálídíàNítorí gbogbo búburú tí wọ́n ti ṣe ní Síónì lójú yín,”+ ni Jèhófà wí.
25 “Wò ó, mo dojú ìjà kọ ọ́,+ ìwọ òkè tó ń pani run,” ni Jèhófà wí,“Ìwọ tó pa gbogbo ayé run.+
Màá na ọwọ́ mi sí ọ, màá sì yí ọ wálẹ̀ látorí àwọn àpátaMàá sì sọ ọ́ di òkè tó ti jóná.”
26 “Àwọn èèyàn kò ní mú òkúta igun ilé tàbí òkúta ìpìlẹ̀ nínú rẹ,Nítorí pé wàá di ahoro títí láé,”+ ni Jèhófà wí.
27 “Ẹ gbé àmì kan sókè* ní ilẹ̀ náà.+
Ẹ fun ìwo láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí.
Ẹ pe àwọn ìjọba Árárátì,+ Mínì àti Áṣíkénásì+ láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ yan agbanisíṣẹ́ ogun láti wá gbéjà kò ó.
Ẹ jẹ́ kí àwọn ẹṣin gòkè wá bí eéṣú onírun gàn-ùn gàn-ùn.
28 Ẹ yan àwọn orílẹ̀-èdè* lé e lórí,Àwọn ọba Mídíà,+ àwọn gómìnà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀Àti gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí.
29 Ilẹ̀ ayé á mì tìtì, jìnnìjìnnì á sì bá a,Nítorí pé èrò Jèhófà sí Bábílónì máa ṣẹ
Láti sọ ilẹ̀ Bábílónì di ohun àríbẹ̀rù, tí ẹnì kánkán kò ní gbé ibẹ̀.+
30 Àwọn jagunjagun Bábílónì ti ṣíwọ́ ìjà.
Wọ́n jókòó sínú àwọn odi agbára wọn.
Okun wọn ti tán.+
Wọ́n ti di obìnrin.+
Wọ́n ti sọ iná sí àwọn ilé rẹ̀.
Wọ́n ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀.+
31 Asáréjíṣẹ́ kan sá lọ pàdé asáréjíṣẹ́ míì,Òjíṣẹ́ kan sì lọ pàdé òjíṣẹ́ míì,Láti ròyìn fún ọba Bábílónì pé wọ́n ti gba ìlú rẹ̀ láti apá ibi gbogbo,+
32 Pé wọ́n ti gba ibi tó ṣeé fẹsẹ̀ gbà kọjá nínú odò lọ́wọ́ rẹ̀,+Pé wọ́n ti dáná sun ọkọ̀ ojú omi tí a fi òrépèté* ṣeÀti pé jìnnìjìnnì ti bá àwọn ọmọ ogun.”
33 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí:
“Ọmọbìnrin Bábílónì dà bí ibi ìpakà.
Ó tó àkókò láti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kí o lè ki.
Láìpẹ́ àkókò ìkórè rẹ̀ máa dé.”
34 “Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ti gbé mi mì;+Ó ti kó ìdààmú bá mi.
Ó ti gbé mi kalẹ̀ bí òfìfo ìkòkò.
Ó ti gbé mi mì bí ejò ńlá ṣe ń gbé nǹkan mì;+Ó ti fi àwọn ohun rere mi kún ikùn ara rẹ̀.
Ó ti fi omi ṣàn mí dà nù.
35 ‘Kí ìwà ipá tí wọ́n hù sí mi àti sí ara mi wá sórí Bábílónì!’ ni ẹni tó ń gbé Síónì wí.+
‘Kí ẹ̀jẹ̀ mi sì wá sórí àwọn tó ń gbé Kálídíà!’ ni Jerúsálẹ́mù wí.”
36 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá gba ẹjọ́ rẹ rò,+Màá gbẹ̀san fún ọ.+
Màá mú kí omi òkun rẹ̀ gbẹ, màá sì mú kí àwọn kànga rẹ̀ gbẹ.+
37 Bábílónì á sì di òkìtì òkúta,+Ibùgbé àwọn ajáko,*+Ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé,Tí ẹnì kankan kò ní gbé ibẹ̀.+
38 Gbogbo wọn á jọ ké ramúramù bí ọmọ kìnnìún.*
Wọ́n á kùn bí àwọn ọmọ kìnnìún.”
39 “Nígbà tí ọ̀fun wọn bá ń dá tòló, màá se àsè fún wọn, màá sì rọ wọ́n yó,Kí wọ́n lè yọ̀;+Nígbà náà, wọ́n á sùn títí lọ,Tí wọn kò ní jí,”+ ni Jèhófà wí.
40 “Màá mú wọn sọ̀ kalẹ̀ bí ọ̀dọ́ àgùntàn tí à ń mú lọ sí ibi ti a ti fẹ́ pa á,Bí àwọn àgbò pẹ̀lú àwọn ewúrẹ́.”
41 “Ẹ wo bí wọ́n ṣe gba Ṣéṣákì,*+Ẹ wo bí wọ́n ṣe gba ìlú tí gbogbo ayé ń yìn!+
Ẹ wo bí Bábílónì ṣe di ohun àríbẹ̀rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!
42 Òkun ti bo Bábílónì mọ́lẹ̀.
Ìgbì rẹ̀ tó ń ru gùdù ti bò ó mọ́lẹ̀.
43 Àwọn ìlú rẹ̀ ti di ohun àríbẹ̀rù, ilẹ̀ tí kò lómi àti aṣálẹ̀.
Ilẹ̀ tí ẹnì kankan kò ní gbé, tí èèyàn kankan kò sì ní gba ibẹ̀ kọjá.+
44 Màá yí ojú mi sí Bélì+ ní Bábílónì,Màá sì yọ ohun tí ó ti gbé mì jáde ní ẹnu rẹ̀.+
Àwọn orílẹ̀-èdè kò sì ní rọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,Ògiri Bábílónì sì máa ṣubú.+
45 Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi!+
Ẹ sá nítorí ẹ̀mí* yín+ kí ẹ lè bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná.+
46 Ẹ má ṣojo, ẹ má sì bẹ̀rù ìròyìn tí ẹ ó gbọ́ ní ilẹ̀ náà.
Ní ọdún kan, ìròyìn náà á dé,Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, ìròyìn míì á tún dé,Nípa ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti nípa alákòóso kan tó dojú ìjà kọ alákòóso míì.
47 Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀Tí màá yíjú sí àwọn ère gbígbẹ́ Bábílónì.
Ìtìjú á bá gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,Òkú gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ á sì wà nílẹ̀ láàárín rẹ̀.+
48 Àwọn ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọnMáa kígbe ayọ̀ lórí Bábílónì,+Nítorí pé àwọn apanirun máa wá bá a láti àríwá,”+ ni Jèhófà wí.
49 “Kì í ṣe pé Bábílónì kàn pa àwọn èèyàn Ísírẹ́lì nìkan ni+Àmọ́ ó tún pa àwọn èèyàn gbogbo ayé tó wà ní Bábílónì.
50 “Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà, ẹ máa sá lọ, ẹ má ṣe dúró!+
Ẹ rántí Jèhófà láti ibi tó jìnnà,Kí ẹ sì máa ronú nípa Jerúsálẹ́mù.”+
51 “Ìtìjú ti bá wa, nítorí a ti gbọ́ ẹ̀gàn.
Ẹ̀tẹ́ ti mú kí ojú tì wá,Nítorí àwọn àjèjì* ti wá gbéjà ko àwọn ibi mímọ́ ilé Jèhófà.”+
52 “Torí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí,“Tí màá yíjú sí àwọn ère gbígbẹ́ rẹ̀,Àwọn tó fara pa yóò máa kérora ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.”+
53 “Bí Bábílónì tiẹ̀ gòkè lọ sí ọ̀run,+Bó bá tiẹ̀ fi ààbò yí àwọn odi agbára rẹ̀ gíga ká,Látọ̀dọ̀ mi ni àwọn tó máa pa á run ti máa wá,”+ ni Jèhófà wí.
54 “Ẹ fetí sílẹ̀! Igbe ẹkún kan ń dún ní Bábílónì,+Ìró àjálù ńlá ń dún láti ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà,+
55 Nítorí Jèhófà ń pa Bábílónì run,Á sì pa ohùn ńlá mọ́ ọn lẹ́nu,Ariwo ìgbì wọn á ròkè bíi ti omi púpọ̀.
A ó sì gbọ́ ìrò ohùn wọn.
56 Nítorí apanirun máa dé sórí Bábílónì;+A ó mú àwọn jagunjagun rẹ̀,+A ó ṣẹ́ ọfà* wọn sí wẹ́wẹ́,Nítorí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ẹ̀san.+
Ó dájú pé ó máa gbẹ̀san.+
57 Màá mú kí àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn amòye rẹ̀ mutí yó,+Àwọn gómìnà rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀,Wọ́n á sì sùn títí lọ,Wọn ò sì ní jí,”+ ni Ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.
58 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:
“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ògiri Bábílónì fẹ̀, a ó wó o palẹ̀,+Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹnubodè rẹ̀ ga, a ó sọ iná sí i.
Àwọn èèyàn ibẹ̀ á sì ṣe làálàá lásán;Àwọn orílẹ̀-èdè á ṣiṣẹ́ títí á fi rẹ̀ wọ́n, torí iná náà kò ní ṣeé pa.”+
59 Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà pa láṣẹ fún Seráyà ọmọ Neráyà+ ọmọ Maseáyà nígbà tó bá Sedekáyà ọba Júdà lọ sí Bábílónì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀; Seráyà sì ni olórí ibùdó.
60 Jeremáyà kọ gbogbo àjálù tó máa bá Bábílónì sínú ìwé kan, ìyẹn gbogbo ọ̀rọ̀ yìí tó kọ nípa Bábílónì.
61 Lẹ́yìn náà, Jeremáyà sọ fún Seráyà pé: “Tí o bá dé Bábílónì, tí o sì fojú kàn án, ka gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sókè.
62 Kí o sì sọ pé, ‘Jèhófà, o ti sọ nípa ibí yìí pé wọ́n á pa á run, ohunkóhun kò sì ní gbé inú rẹ̀, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko àti pé á di ahoro títí láé.’+
63 Nígbà tí o bá ti ka ìwé yìí tán, so òkúta kan mọ́ ọn, kí o sì jù ú sí àárín odò Yúfírétì.
64 Kí o sọ pé, ‘Bí Bábílónì ṣe máa wọlẹ̀ nìyí, tí kò sì ní gbérí mọ́,+ nítorí àjálù tí Ọlọ́run màá mú wá sórí rẹ̀; àárẹ̀ á sì mú wọn.’”+
Ibí ni ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ parí sí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Kálídíà.
^ Ní Héb., “fi okùn sí.”
^ Ní Héb., “Ísírẹ́lì àti Júdà kì í ṣe opó lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
^ Ìyẹn, ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ẹ kó ọfà kún apó.”
^ Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
^ Ní Héb., “òpin òṣùwọ̀n.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “oruku.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “ère dídà.”
^ Tàbí “èémí.”
^ Tàbí “Asán.”
^ Ní Héb., “Ìpín.”
^ Tàbí “ogún.”
^ Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
^ Ní Héb., “Ẹ ya àwọn orílẹ̀-èdè sí mímọ́.”
^ Ní Héb., “Ẹ ya àwọn orílẹ̀-èdè sí mímọ́.”
^ Ìyẹn, pápírọ́sì.
^ Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.
^ Tàbí “akátá.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Bábélì (Bábílónì).
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “àwọn àlejò.”
^ Ní Héb., “ọrun.”