Àkọsílẹ̀ Lúùkù 2:1-52
2 Nígbà yẹn, Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn tó ń gbé láyé lọ forúkọ sílẹ̀.
2 (Ìgbà tí Kúírínọ́sì jẹ́ gómìnà Síríà ni ìforúkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ yìí wáyé.)
3 Gbogbo èèyàn sì lọ forúkọ sílẹ̀, kálukú lọ sí ìlú rẹ̀.
4 Jósẹ́fù+ náà gòkè lọ láti Gálílì, ó gbéra ní ìlú Násárẹ́tì lọ sí Jùdíà, sí ìlú Dáfídì, tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ torí pé ó jẹ́ ará ilé àti ìdílé Dáfídì.
5 Ó lọ forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà, tí a ti fún un pé kó fi ṣe aya bí a ṣe ṣèlérí,+ tí kò sì ní pẹ́ bímọ.+
6 Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ó tó àkókò fún un láti bímọ.
7 Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí,+ ó wá fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran,+ torí pé kò sí àyè fún wọn ní ibi táwọn èèyàn ń dé sí.
8 Ní agbègbè yẹn kan náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbé níta, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.
9 Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà* dúró síwájú wọn, ògo Jèhófà* tàn yòò yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
10 Àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù, torí, ẹ wò ó! mò ń kéde ìhìn rere ayọ̀ ńláǹlà fún yín, èyí tí gbogbo èèyàn máa ní.
11 Torí lónìí, a bí olùgbàlà kan+ fún yín ní ìlú Dáfídì,+ òun ni Kristi Olúwa.+
12 Àmì tí ẹ máa rí nìyí: Ẹ máa rí ọmọ jòjòló kan tí wọ́n fi ọ̀já wé, tí wọ́n tẹ́ sínú ibùjẹ ẹran.”
13 Lójijì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run+ wá bá áńgẹ́lì náà, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé:
14 “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè àti àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà* ní ayé.”
15 Torí náà, nígbà tí àwọn áńgẹ́lì náà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ká lọ wo ohun tó ṣẹlẹ̀, ohun tí Jèhófà* jẹ́ ká mọ̀.”
16 Wọ́n yára lọ, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù àti ọmọ jòjòló náà nínú ibùjẹ ẹran tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.
17 Nígbà tí wọ́n rí èyí, wọ́n sọ ohun tí a ti sọ fún wọn nípa ọmọ kékeré yìí.
18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tó gbọ́ ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn,
19 àmọ́ Màríà bẹ̀rẹ̀ sí í pa gbogbo ọ̀rọ̀ yìí mọ́, ó sì ń parí èrò nínú ọkàn rẹ̀.+
20 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà wá pa dà lọ, wọ́n ń fògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín torí gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí, bí a ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́.
21 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ, nígbà tí àkókò tó láti dádọ̀dọ́ rẹ̀,*+ wọ́n sọ ọ́ ní Jésù, orúkọ tí áńgẹ́lì náà pè é kí wọ́n tó lóyún rẹ̀.+
22 Bákan náà, nígbà tí àkókò tó láti wẹ̀ wọ́n mọ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè,+ wọ́n gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fún Jèhófà,*
23 bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Jèhófà* pé: “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* ni ká pè ní mímọ́ fún Jèhófà.”*+
24 Wọ́n sì rúbọ bí Òfin Jèhófà* ṣe sọ: “ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.”+
25 Wò ó! ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù tó ń jẹ́ Síméónì, olódodo àti ẹni tó ní ìfọkànsìn ni ọkùnrin yìí, ó ń dúró de ìgbà tí a máa tu Ísírẹ́lì nínú,+ ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀.
26 Bákan náà, a ti ṣí i payá fún un látọ̀run wá nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ pé kò ní rí ikú kó tó rí Kristi Jèhófà.*
27 Ẹ̀mí darí rẹ̀, ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì, bí àwọn òbí ọmọ náà ṣe gbé Jésù ọmọ kékeré náà wọlé láti ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe lábẹ́ Òfin fún un,+
28 ó gba ọmọ náà, ó sì gbé e dání, ó yin Ọlọ́run, ó sì sọ pé:
29 “Ní báyìí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ò ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ ní àlàáfíà+ bí o ṣe kéde,
30 torí ojú mi ti rí ohun tí o máa fi gbani là,+
31 èyí tí o pèsè níṣojú gbogbo èèyàn,+
32 ìmọ́lẹ̀+ láti mú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè+ àti ògo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì.”
33 Ohun tó ń sọ nípa ọmọ náà sì ń ya bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́nu.
34 Bákan náà, Síméónì súre fún wọn, ó sì sọ fún Màríà, ìyá ọmọ náà pé: “Wò ó! A ti yan ọmọ yìí kí ọ̀pọ̀ ní Ísírẹ́lì lè ṣubú,+ kí ọ̀pọ̀ sì tún dìde,+ kó sì lè jẹ́ àmì tí wọ́n máa sọ̀rọ̀ lòdì sí +
35 (àní, a máa fi idà gígùn kan gún ọ*),+ kí a lè mọ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń rò lọ́kàn.”
36 Wòlíì obìnrin kan wà, Ánà lorúkọ rẹ̀, ọmọbìnrin Fánúẹ́lì ni, láti ẹ̀yà Áṣérì. Obìnrin yìí ti lọ́jọ́ lórí gan-an, ọdún méje ló sì lò nílé ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó,*
37 ó ti di opó, ó sì ti di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) báyìí. Kì í pa wíwá sí tẹ́ńpìlì jẹ, ó máa ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tọ̀sántòru, ó máa ń gbààwẹ̀, ó sì máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀.
38 Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá sí tòsí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ń sọ̀rọ̀ ọmọ náà fún gbogbo àwọn tó ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.+
39 Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ṣe gbogbo nǹkan bó ṣe wà nínú Òfin Jèhófà,*+ wọ́n pa dà sí Gálílì, wọ́n lọ sí Násárẹ́tì ìlú wọn.+
40 Ọmọ kékeré náà wá ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ọgbọ́n kún inú rẹ̀, Ọlọ́run sì ń ṣojúure sí i.+
41 Ó jẹ́ àṣà àwọn òbí rẹ̀ láti máa lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún kí wọ́n lè lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.+
42 Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12), wọ́n gòkè lọ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ náà.+
43 Nígbà tí wọ́n parí àjọyọ̀ náà, tí wọ́n sì ń pa dà sílé, ọmọdékùnrin náà, Jésù, ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn òbí rẹ̀ ò sì mọ̀.
44 Wọ́n rò pé ó wà láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, torí náà, wọ́n ti rin ìrìn ọjọ́ kan kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ojúlùmọ̀.
45 Àmọ́ nígbà tí wọn ò rí i, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fara balẹ̀ wá a.
46 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì, ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.
47 Àmọ́ léraléra ni ẹnu ń ya gbogbo àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.+
48 Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ rí i, ẹnu yà wọ́n, ìyá rẹ̀ wá sọ fún un pé: “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe báyìí sí wa? Wò ó, èmi àti bàbá rẹ ti dààmú gan-an bá a ṣe ń wá ọ kiri.”
49 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá mi? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”+
50 Ṣùgbọ́n ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.
51 Ó wá tẹ̀ lé wọn sọ̀ kalẹ̀, wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì, ó sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.*+ Bákan náà, ìyá rẹ̀ rọra fi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn.+
52 Ọgbọ́n Jésù wá ń pọ̀ sí i, ó ń dàgbà sí i, ó sì ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “àwọn èèyàn tó tẹ́wọ́ gbà.”
^ Tàbí “kọ ọ́ nílà.”
^ Ní Grk., “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin tó ṣí ilé ọmọ kọ̀ọ̀kan.”
^ Tàbí “gún ọkàn rẹ.”
^ Ní Grk., “láti ìgbà wúńdíá rẹ̀.”
^ Ní Grk., “fi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.”