Sí Àwọn Ará Róòmù 11:1-36
11 Nígbà náà, mo béèrè pé, Ṣé Ọlọ́run ti kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ ni?+ Rárá o! Nítorí ọmọ Ísírẹ́lì ni èmi náà, àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.
2 Ọlọ́run ò kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tó kọ́kọ́ mọ̀.+ Ṣé ẹ ò mọ ohun tí ìwé mímọ́ sọ nípa Èlíjà ni, bí ó ṣe ń fi ẹjọ́ Ísírẹ́lì sùn nígbà tó ń bẹ Ọlọ́run?
3 “Jèhófà,* wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọ́n ti hú àwọn pẹpẹ rẹ kúrò, èmi nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí* mi.”+
4 Síbẹ̀, èsì wo ni ó gbọ́ láti ọ̀run? “Mo ti ṣẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ọkùnrin kù fún ara mi, àwọn ọkùnrin tí kò kúnlẹ̀ fún Báálì.”+
5 Lọ́nà kan náà, ní àkókò yìí, àṣẹ́kù kan wà+ tí a yàn nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.
6 Ní báyìí, tó bá jẹ́ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ni,+ á jẹ́ pé kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ mọ́;+ àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí náà kò ní jẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mọ́.
7 Kí wá ni? Ísírẹ́lì kò rí ohun tó ń wá lójú méjèèjì gbà, àmọ́ àwọn tí a yàn rí i gbà.+ Ọkàn àwọn yòókù ti yigbì,+
8 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ọlọ́run ti fún wọn ní ẹ̀mí oorun àsùnwọra,+ ojú tí kò ríran àti etí tí kò gbọ́ràn, títí di òní olónìí.”+
9 Bákan náà, Dáfídì sọ pé: “Jẹ́ kí tábìlì wọn di ìdẹkùn àti pańpẹ́ àti ohun ìkọ̀sẹ̀ àti ẹ̀san fún wọn.
10 Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọ́n má lè ríran, sì mú kí ẹ̀yìn wọn tẹ̀ ba nígbà gbogbo.”+
11 Nítorí náà, mo béèrè pé, Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọsẹ̀ tí wọ́n fi ṣubú pátápátá ni? Rárá o! Àmọ́ bí wọ́n ṣe ṣi ẹsẹ̀ gbé ló mú ìgbàlà wá fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, èyí sì mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jowú.+
12 Ní báyìí, tí bí wọ́n ṣe ṣi ẹsẹ̀ gbé bá yọrí sí ọrọ̀ fún ayé, tí bí wọ́n ṣe dín kù sì yọrí sí ọrọ̀ fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè,+ ẹ wo bí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye wọn yóò ṣe yọrí sí ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ!
13 Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ wá láti àwọn orílẹ̀-èdè ni mo fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe jẹ́ àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mo ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lógo*+
14 bóyá màá lè rọ́nà mú kí àwọn èèyàn* mi jowú, kí n sì gba díẹ̀ lára wọn là.
15 Nítorí bí títa wọ́n nù+ bá yọrí sí ìpadàrẹ́ fún ayé, ṣé gbígbà wọ́n kò ní yọrí sí ìyè kúrò nínú ikú ni?
16 Síwájú sí i, tí apá tí a mú gẹ́gẹ́ bí àkọ́so lára ìṣùpọ̀ bá jẹ́ mímọ́, gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú; tí gbòǹgbò bá sì jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka yóò jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
17 Àmọ́, tí a bá ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka kan kúrò, tí a lọ́ ìwọ tí o jẹ́ ólífì inú igbó mọ́ àárín wọn, tí o sì wá pín nínú èròjà ilẹ̀ tó wà fún gbòǹgbò igi ólífì náà,
18 má ṣe máa gbéra ga* sí àwọn ẹ̀ka náà. Torí tí o bá gbéra ga* sí wọn,+ rántí pé ìwọ kọ́ lo gbé gbòǹgbò dúró, gbòǹgbò ló gbé ọ dúró.
19 Nígbà náà, wàá sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka kan kúrò, kí wọ́n lè lọ́ mi wọlé.”+
20 Òótọ́ nìyẹn! Nítorí àìnígbàgbọ́ wọn, a ṣẹ́ wọn kúrò,+ àmọ́ ìgbàgbọ́ mú kí ìwọ dúró.+ Má ṣe gbéra ga, àmọ́ ṣe ni kí o bẹ̀rù.
21 Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi gangan sí, kò ní dá ìwọ náà sí.
22 Nítorí náà, ronú nípa inú rere Ọlọ́run+ àti bó ṣe ń fìyà jẹni. Ìyà wà fún àwọn tó ṣubú,+ àmọ́ inú rere Ọlọ́run wà fún ìwọ, kìkì bí o bá dúró nínú inú rere rẹ̀; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ó ṣẹ́ ìwọ náà kúrò.
23 Tí àwọn náà bá kúrò nínú àìnígbàgbọ́ wọn, a ó lọ́ wọn wọlé,+ nítorí Ọlọ́run lè lọ́ wọn wọlé pa dà.
24 Nítorí tó bá jẹ́ pé a gé ọ kúrò lára igi ólífì inú igbó, tí a sì lọ́ ọ wọlé sínú igi ólífì inú ọgbà, ẹ wo bó ṣe máa rọrùn tó láti lọ́ àwọn tó jẹ́ ẹ̀ka igi ólífì gangan wọlé pa dà sínú igi ólífì tiwọn!
25 Nítorí mi ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ àṣírí mímọ́ yìí,+ ẹ̀yin ará, kí ẹ má bàa gbọ́n lójú ara yín: Pé ọkàn àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yigbì lápá kan títí iye àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè tó máa wọlé á fi pé,
26 báyìí la ṣe máa gba gbogbo Ísírẹ́lì+ là. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Olùdáǹdè* máa wá láti Síónì,+ á sì yí àwọn ìwà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù.
27 Èyí sì ni májẹ̀mú tí mo bá wọn dá,+ nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”+
28 Lóòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ìhìn rere, ọ̀tá ni wọ́n jẹ́ nítorí yín, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ àwọn tí Ọlọ́run yàn, ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ nítorí àwọn baba ńlá wọn.+
29 Nítorí Ọlọ́run kò ní kábàámọ̀ àwọn ẹ̀bùn tó fún wọn àti pípè tó pè wọ́n.
30 Nítorí bí ẹ ṣe fìgbà kan jẹ́ aláìgbọràn sí Ọlọ́run,+ àmọ́ tí a fi àánú hàn sí+ yín ní báyìí nítorí àìgbọràn wọn,+
31 bẹ́ẹ̀ náà ni bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìgbọràn ní báyìí ṣe yọrí sí àánú fún yín, kí a lè fi àánú hàn sí àwọn náà ní báyìí.
32 Nítorí Ọlọ́run ti sé gbogbo wọn pọ̀ mọ́ inú àìgbọràn,+ kí ó lè fi àánú hàn sí gbogbo wọn.+
33 Ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o! Ẹ wo bí àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ àwámáridìí tó, tí àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì kọjá àwárí!
34 Nítorí “ta ló mọ èrò Jèhófà,* ta sì ni agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?”+
35 Àbí, “ta ló ti kọ́kọ́ fún un ní nǹkan, tó fi gbọ́dọ̀ san án pa dà fún un?”+
36 Torí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá, ipasẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n fi wà, tìtorí rẹ̀ ni wọ́n sì ṣe wà. Òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “èso.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ga.”
^ Ní Grk., “ẹran ara.”
^ Tàbí “fọ́nnu.”
^ Tàbí “fọ́nnu.”
^ Tàbí “Olùgbàlà.”