Sí Àwọn Ará Róòmù 15:1-33
15 Àmọ́ o, ó yẹ kí àwa tí a lókun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun,+ ká má sì máa ṣe ohun tó wù wá.+
2 Kí kálukú wa máa ṣe ohun tó wu ọmọnìkejì rẹ̀ fún ire rẹ̀, láti gbé e ró.+
3 Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tó wù ú,+ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹ̀gàn ẹnu àwọn tó ń pẹ̀gàn rẹ sì ti wá sórí mi.”+
4 Nítorí gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́,+ kí a lè ní ìrètí+ nípasẹ̀ ìfaradà+ wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.
5 Ní báyìí, kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìfaradà àti ìtùnú jẹ́ kí ẹ ní èrò kan náà pẹ̀lú Kristi Jésù láàárín ara yín,
6 kí ẹ lè jọ+ máa fi ohùn* kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.
7 Nítorí náà, ẹ tẹ́wọ́ gba* ara yín,+ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ṣe tẹ́wọ́ gbà yín,+ kó lè yọrí sí ògo fún Ọlọ́run.
8 Nítorí mo sọ fún yín pé Kristi di òjíṣẹ́ àwọn tó dádọ̀dọ́*+ nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kí ó lè fìdí ìlérí tí Ó ṣe fún àwọn baba ńlá+ wọn múlẹ̀,
9 kí àwọn orílẹ̀-èdè sì lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀.+ Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ìdí nìyẹn tí màá fi yìn ọ́ ní gbangba láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí màá sì fi orin yin orúkọ rẹ.”+
10 Ó tún sọ pé: “Ẹ bá àwọn èèyàn rẹ̀ yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè.”+
11 Àti pé: “Ẹ yin Jèhófà,* gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí gbogbo àwọn èèyàn sì yìn ín.”+
12 Àìsáyà tún sọ pé: “Gbòǹgbò Jésè yóò wà,+ ẹni tó máa dìde láti ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè;+ òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”+
13 Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí fi gbogbo ayọ̀ àti àlàáfíà kún inú yín nítorí ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé e, kí ìrètí yín lè túbọ̀ dájú* nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́.+
14 Ní tèmi, ó dá mi lójú, ẹ̀yin ará mi, pé ẹ máa ń ṣe rere, ẹ ní gbogbo ìmọ̀, ẹ sì lè máa tọ́ ara yín sọ́nà.*
15 Àmọ́ ṣá, mo ti kọ̀wé sí yín lọ́nà tó túbọ̀ ṣe ṣàkó lórí àwọn kókó kan, kí n lè tún rán yín létí, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fún mi,
16 kí n lè jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo èèyàn tí Kristi Jésù ti yàn fún àwọn orílẹ̀-èdè.+ Mò ń ṣe iṣẹ́ mímọ́ ti ìhìn rere Ọlọ́run,+ kí àwọn orílẹ̀-èdè náà lè jẹ́ ọrẹ tí a tẹ́wọ́ gbà, tí a sì fi ẹ̀mí mímọ́ yà sọ́tọ̀.
17 Nítorí náà, ìdí wà fún mi láti yọ̀ nínú Kristi Jésù lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run.
18 Torí pé mi ò ní sọ nǹkan míì àfi àwọn ohun tí Kristi ti ṣe nípasẹ̀ mi kí àwọn orílẹ̀-èdè lè wá di onígbọràn, nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi,
19 pẹ̀lú agbára àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu,*+ pẹ̀lú agbára ẹ̀mí Ọlọ́run, tó fi jẹ́ pé láti Jerúsálẹ́mù títí mo fi lọ yí ká dé Ílíríkónì ni mo ti wàásù ìhìn rere nípa Kristi+ kúnnákúnná.
20 Ní tòótọ́, lọ́nà yìí, mo ní in lọ́kàn pé mi ò ní kéde ìhìn rere níbi tí àwọn èèyàn bá ti mọ orúkọ Kristi, kí n má lọ máa kọ́lé sórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíì;
21 gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Àwọn tí kò gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀ yóò rí i, àwọn tí kò sì tíì gbọ́ yóò lóye.”+
22 Ìdí nìyí tí a kò fi gbà mí láyè lọ́pọ̀ ìgbà láti wá sí ọ̀dọ̀ yín.
23 Àmọ́ ní báyìí mi ò ní ìpínlẹ̀ tí a kò tíì fọwọ́ kàn ní àwọn agbègbè yìí mọ́, ọ̀pọ̀ ọdún* ló sì ti ń wù mí kí n wá sọ́dọ̀ yín.
24 Torí náà, nígbà tí mo bá lọ sí Sípéènì, mo retí pé màá rí yín, ẹ ó sì sìn mí dójú ọ̀nà lẹ́yìn tí mo bá ti kọ́kọ́ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ yín fúngbà díẹ̀.
25 Àmọ́ ní báyìí, mo fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́.+
26 Nítorí ó ti ń wu àwọn tó wà ní Makedóníà àti Ákáyà láti fi lára àwọn nǹkan wọn ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn aláìní tó wà lára àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.+
27 Lóòótọ́, ó wù wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí ní ti gidi, wọ́n jẹ wọ́n ní gbèsè; nítorí bí àwọn orílẹ̀-èdè bá ti pín nínú àwọn nǹkan tẹ̀mí wọn, àwọn náà jẹ wọ́n ní gbèsè láti fi àwọn nǹkan tara tí wọ́n ní ṣe ìtìlẹ́yìn fún wọn.+
28 Nítorí náà, tí mo bá ti parí èyí, tí mo sì fi ìtìlẹ́yìn* yìí jíṣẹ́ fún wọn láìséwu, màá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Sípéènì.
29 Yàtọ̀ síyẹn, mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín, màá wá pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Kristi.
30 Ní báyìí, mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ tí ẹ̀mí mú kí ẹ ní, pé kí a jọ tẹra mọ́ àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run nítorí mi,+
31 kí a lè gbà mí+ lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà, kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lórí Jerúsálẹ́mù sì lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn ẹni mímọ́,+
32 kó lè jẹ́ pé nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, màá wá sọ́dọ̀ yín tayọ̀tayọ̀, ara á sì tù mí pẹ̀lú yín.
33 Kí Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín.+ Àmín.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Grk., “ẹnu.”
^ Tàbí “ẹ gba.”
^ Tàbí “kọlà.”
^ Tàbí “kún rẹ́rẹ́.”
^ Tàbí “kọ́ ara yín.”
^ Tàbí “àwọn àmì.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ọdún díẹ̀.”
^ Ní Grk., “èso.”