Sáàmù 13:1-6

  • Dúró de ìgbàlà Jèhófà

    • ‘Títí dìgbà wo, Jèhófà?’ (1, 2)

    • Jèhófà ń san èrè fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀ (6)

Sí olùdarí. Orin Dáfídì. 13  Jèhófà, ìgbà wo lo máa gbàgbé mi dà? Ṣé títí láé ni? Ìgbà wo lo máa gbé ojú rẹ pa mọ́ fún mi dà?+   Ìgbà wo ni mi* ò ní dààmú mọ́,Tí ẹ̀dùn ọkàn mi ojoojúmọ́ á sì dópin? Ìgbà wo ni ọ̀tá mi ò ní jẹ gàba lé mi lórí mọ́?+   Bojú wò mí, kí o sì dá mi lóhùn, Jèhófà Ọlọ́run mi. Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má bàa sun oorun ikú,   Kí ọ̀tá mi má bàa sọ pé: “Mo ti ṣẹ́gun rẹ̀!” Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń ta kò mí yọ̀ lórí ìṣubú mi.+   Ní tèmi, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé;+Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ yóò máa mú ọkàn mi yọ̀.+   Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti san èrè fún mi lọ́pọ̀lọpọ̀.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “hùwà sí mi lọ́nà tó ń mérè wá.”