Sáàmù 36:1-12
Sí olùdarí. Ti Dáfídì, ìránṣẹ́ Jèhófà.
36 Ẹ̀ṣẹ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn ẹni burúkú;Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọ́run lójú rẹ̀.+
2 Ó ń pọ́n ara rẹ̀ lé ju bó ṣe yẹ lọDébi pé kò rí àṣìṣe ara rẹ̀, kí ó sì kórìíra rẹ̀.+
3 Ọ̀rọ̀ ìkà àti ẹ̀tàn ló wà lẹ́nu rẹ̀;Kì í ronú bó ṣe máa ṣe rere.
4 Ó máa ń gbèrò ibi, kódà lórí ibùsùn rẹ̀.
Ọ̀nà tí kò dáa ló forí lé;Kì í kọ ohun búburú sílẹ̀.
5 Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run,+Òtítọ́ rẹ ga títí dé àwọsánmà.
6 Òdodo rẹ dà bí àwọn òkè ńlá;*+Àwọn ìdájọ́ rẹ dà bí alagbalúgbú ibú omi.+
Àti èèyàn àti ẹranko ni ò ń dá sí,* Jèhófà.+
7 Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run!+
Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹNi àwọn ọmọ èèyàn fi ṣe ibi ààbò.+
8 Wọ́n ń mu àwọn ohun tó dára jù lọ ní* ilé rẹ ní àmutẹ́rùn,+O sì mú kí wọ́n máa mu nínú adùn rẹ tó ń ṣàn bí odò.+
9 Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà;+Ipasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a fi lè rí ìmọ́lẹ̀.+
10 Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́,+Àti òdodo rẹ sí àwọn tí ọkàn wọn dúró ṣinṣin.+
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn agbéraga tẹ̀ mí mọ́lẹ̀Tàbí kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú lé mi dà nù.
12 Ẹ wo àwọn aṣebi níbi tí wọ́n ṣubú sí;A ti là wọ́n mọ́lẹ̀, wọn kò sì lè dìde.+