Sáàmù 6:1-10

  • Ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere

    • Òkú kì í yin Ọlọ́run (5)

    • Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ojú rere (9)

Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín tí a yí sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì. 6  Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìrunú rẹ.+   Ṣojú rere sí mi,* Jèhófà, nítorí ó ti ń rẹ̀ mí. Wò mí sàn, Jèhófà,+ nítorí àwọn egungun mi ń gbọ̀n.   Bẹ́ẹ̀ ni, ìdààmú ti bá mi* gidigidi,+Torí náà, mò ń bi ọ́, Jèhófà, ìgbà wo ló máa dópin?+   Pa dà, Jèhófà, kí o sì gbà mí* sílẹ̀;+Gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.+   Nítorí òkú kò lè sọ nípa* rẹ;Àbí, ta ló lè yìn ọ́ nínú Isà Òkú?*+   Àárẹ̀ ti mú mi nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi;+Láti òru mọ́jú ni omijé mi ń rin ibùsùn mi gbingbin;*Ẹkún mi ti fi omi kún àga tìmùtìmù mi.+   Ìbànújẹ́ ti sọ ojú mi di bàìbàì;+Ojú mi ti ṣú* nítorí gbogbo àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ mi.   Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń hùwà burúkú,Nítorí pé Jèhófà yóò gbọ́ igbe ẹkún mi.+   Jèhófà yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ojú rere;+Jèhófà yóò dáhùn àdúrà mi. 10  Ojú á ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi, ìdààmú á sì bá wọn;Ìtìjú òjijì á mú wọn sá pa dà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ṣàánú mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “ọkàn mi.”
Tàbí “rántí.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ń mú kí ibùsùn mi lúwẹ̀ẹ́.”
Tàbí “gbó.”