Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Ewu Pọ̀ Tó Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ni Ewu Pọ̀ Tó Nínú Fífẹ́ra Sọ́nà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
“O lè má mọ irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Dan, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún. a
“Àwọn èèyàn ń pa fòóò irọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó rọrùn láti díbọ́n níbẹ̀.”—George, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
ŃṢE làwọn tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kàn ń pọ̀ sí i káàkiri àgbáyé. Bí àpilẹ̀kọ tá a tẹ̀ ṣáájú èyí lórí ọ̀ràn yẹn ṣe sọ, ìfẹ́ tètè máa ń wọni lọ́kàn látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣùgbọ́n nígbà tójú àwọn méjèèjì bá kojú, kíá nirú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń forí ṣánpọ́n. b Àmọ́, ohun kan tún wà tó yẹ kó kọni lóminú tó kọjá kí ìfẹ́ yẹn forí ṣánpọ́n. Irú ìfẹ́ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì báyìí lè kó ẹ sínú ewu tó burú jáì nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ó sì lè bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́.
Báwo lohun kan tó dà bí ọ̀rọ̀ eré tí kò léwu nínú, ìyẹn fífi kọ̀ǹpútà lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti ibi tó o wà, ṣe lè wá kó ẹ sínú ewu? Àwọn kan lára ewu náà tiẹ̀ jẹ mọ́ títẹ àwọn ìlànà pàtàkì tó wà nínú Bíbélì lójú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Gbọ́ o, kì í ṣe pé à ń sọ pé alábòsí lẹni tó bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, a ò sì sọ pé lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì lè sọ ẹ́ di alábòsí. Àmọ́, ó yẹ ká mọ̀ pé àwọn míì sábà máa ń parọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọ̀rọ̀ tá a fà yọ lókè yẹn sì fi hàn pé ó dà bíi pé Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń jẹ́ kó rọrùn láti pa irú àwọn irọ́ kan, tó sì túbọ̀ ṣòro láti já irú irọ́ bẹ́ẹ̀. Tó bá sì wá dọ̀rọ̀ à-ń-fẹ́ra, ewu ńlá ló máa ń fà tẹ́nì kan bá ń parọ́.
Bí àpẹẹrẹ, wo irú àìṣòótọ́ tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹnu kàn pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé.” (Sáàmù 26:4) Àwọn wo ni “àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́”? Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan pè wọ́n ní “alágàbàgebè.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé a lè lo ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe “àwọn tó ń fi ète ọkàn wọn pa mọ́ káwọn ẹlòmíì má bàa mọ̀ ọ́n, tàbí àwọn tó ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àtohun tí wọ́n fẹ́ ṣe pa mọ́.” Báwo ni wọ́n ṣe máa ń hu irú ìwà àìṣòótọ́ bẹ́ẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Kí sì làwọn ewu wo tó wà nínú ẹ̀ fẹ́ni tó bá ń wá olólùfẹ́?
Àwọn Ìkookò Nínú Aṣọ Àgùntàn
Ẹ̀rù ba Bàbá kan tó ń jẹ́ Michael gan-an ni nígbà tó gbọ́ ní ìpàdé àpérò kan pé ọ̀pọ̀ ọmọdé ló ń ṣàìgbọràn sí òfin àwọn òbí pé kí wọ́n má ṣe lọ sórí àwọn ìkànnì tó léwu lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó sọ pé: “Ohun tó túbọ̀ já mi láyà ni gbígbọ́ tí mo gbọ́ pé àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe lè ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tan àwọn ọmọdé débi tí wọ́n á ti máa bá wọn ṣèṣekúṣe.” Táwọn ọ̀dọ́ bá ń pàdé ọ̀rẹ́ tuntun lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n lè má mọ bí ewu táwọn á kó sí ṣe pọ̀ tó.
Ìròyìn tiẹ̀ ti gbòde kan báyìí nípa àwọn àgbàlagbà olubi tó ń dọ́gbọ́n ṣe bí ọ̀dọ́ bí wọ́n ṣe ń dọdẹ àwọn ọ̀dọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kọ́wọ́ ṣìnkún wọn lè tẹ àwọn tí wọ́n fẹ́ fi ṣèfà jẹ. Ìwádìí kan fi hàn pé “nínú àwọn ọmọ márùn-ún tó ń dédìí Íntánẹ́ẹ̀tì, wọ́n ti fi ìbálọ̀pọ̀ lọ ẹyọ kan rí.” Ìwé ìròyìn kan sọ pẹ̀lú pé ọmọ kan nínú mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí mẹ́tàdínlógún, ni wọ́n “ń yọ lẹ́nu ṣáá” nípasẹ̀ fífi kọ̀ǹpútà bá wọn sọ̀rọ̀.
Ó ya àwọn èwe kan lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí i pé ẹni táwọn pè ní ọ̀dọ́, tọ́rọ̀ ìfẹ́ ti ń wà láàárín àwọn àti ẹ̀ kì í ṣe ọ̀dọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ àgbàlagbà ẹlẹ́wọ̀n kan ni. Àwọn ọ̀dọ́ míì ti tipa bẹ́ẹ̀ kó sọ́wọ́ àwọn tó kó wọn nífà nípa bíbá wọn lò pọ̀. Ibi kí wọ́n jọ máa rojọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì làwọn olubi wọ̀nyí á ti máa kó ọ̀rọ̀ sórí ẹni tí wọ́n bá rí mú. Àmọ́, nígbà tó bá yá wọ́n á máa wá bí wọ́n ṣe máa fojú kan ọmọ ọlọ́mọ kí wọ́n lè mú ìfẹ́ inú wọn ṣẹ. Ó dunni pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ lù tàbí kí wọ́n fipá bá lò pọ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n.
Kò sí àníàní pé àwọn èèyàn burúkú máa “ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́” kí wọ́n bàa lè rẹ́ni táá kó sí wọn lọ́wọ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀rọ̀ àwọn tó ń dọdẹ àwọn ọmọdé yìí lè rán ẹ létí àpèjúwe Jésù nípa àwọn wòlíì èké tó máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn “nínú aṣọ àgùntàn,” àmọ́ tó jẹ́ pé “ọ̀yánnú ìkookò” ni wọ́n ní tòótọ́. (Mátíù 7:15) Téèyàn bá ń bá ẹni tí kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èèyàn á fẹ́rẹ̀ẹ́ má mọ̀ pé ṣe ló ń tan òun jẹ. George tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ pé: “Ojú la fi ń gbéyàwó ọ̀rọ̀, o lè tipa bí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ṣe ṣe ojú àti bí ohùn rẹ̀ ṣe ń dún, mọ àwọn ohun kan nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o ò lè rójú ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀, o ò sì lè gbóhùn rẹ̀. Nítorí náà, ó rọrùn fún un láti tàn ẹ́ jẹ.”
Ẹ ò rí i pé ọgbọ́n wà nínú ìmọ̀ràn Bíbélì náà pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) A gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹni tó o bá bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló fẹ́ kó ẹ nífà o. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì tún wà táwọn èèyàn fi máa ń “fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.”
Ẹ̀tàn Pọ̀ Ńbẹ̀, O Kò sì Lè Mọ Àṣírí Wọn
Kò yani lẹ́nu pé àwọn tó ń wá olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sábà máa ń pọ́n ara wọn lé nípa bíbù kún àwọn ànímọ́ dáadáa tí wọ́n ní tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa dín àwọn àlèébù wọn kù, wọ́n tiẹ̀ lè máa fi ìbàjẹ́ ara wọn pa mọ́. Bákan náà, ìwé ìròyìn The Washington Post gbé ohun tí òǹkọ̀wé kan sọ jáde, pé: “Fífẹ́ra sọ́nà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì burú nítorí pé wọ́n máa ń tipasẹ̀ rẹ̀ tan ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ.” Ó wá fi kún un pé: “Àwọn èèyàn máa ń díbọ́n ṣe bí obìnrin tàbí kí wọ́n díbọ́n ṣe bí ọkùnrin. . . . Èèyàn ò lè mọ iye owó tó ń wọlé fún wọn, . . . ẹ̀yà tí wọ́n ti wá, bóyá wọ́n ti dáràn rí, bí ọpọlọ wọn ṣe pé tó àti bóyá wọ́n ti ṣègbéyàwó títí dìgbà tẹ́ ẹ bá ti lọ jìnnà nínú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tó wà láàárín yín.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sọ ohun tójú wọn ti rí látàrí bí wọ́n ṣe fi ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàn wọ́n jẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, káwọn míì lè fi tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n.
Ṣé àwọn èèyàn lè parọ́ lórí ọ̀rọ̀ pàtàkì, irú bíi bí wọ́n ṣe ń ṣe sí nípa tẹ̀mí? Ó bani nínú jẹ́ láti
sọ pé wọ́n máa ń fìyẹn náà parọ́, àwọn kan ti sọ pé Kristẹni tòótọ́ làwọn nígbà tó sì jẹ́ pé irọ́ ni wọ́n ń pa. Kí ló fa gbogbo ẹ̀tàn yìí? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, ara ohun tó máa ń fà á ni pé Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó rọrùn. Ọ̀dọ́kùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Ireland tó ń jẹ́ Sean sọ pé: “Ó rọrùn láti díbọ́n pe o jẹ́ ohun tí o kò jẹ́ nígbà tó o bá ń tẹ ọ̀rọ̀ sínú kọ̀ǹpútà.”Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fojú ṣákálá wo ẹ̀tàn yìí, wọ́n máa ń sọ pé kò tíì pọ̀ jù téèyàn bá ń parọ́ díẹ̀díẹ̀ fẹ́ni tó ń fẹ́. Àmọ́, rántí pé Ọlọ́run kórìíra irọ́ o. (Òwe 6:16-19) Ó sì nídìí pàtàkì tí Ọlọ́run fi kórìíra rẹ̀. Ṣebí irọ́ pípa ló fa ọ̀pọ̀ ìdààmú àti làásìgbò tó ń bá aráyé fínra yìí. (Jòhánù 8:44) Tó bá wá jẹ́ pé irọ́ làwọn méjì fi pilẹ̀ ìfẹ́ tó wà láàárín wọn, pàápàá àwọn tí wọ́n ní in lọ́kàn láti fẹ́ra, a jẹ́ pé irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ò lè já síbi tó dáa. Ó léwu fún ipò tẹ̀mí èèyàn láti jẹ́ aláìṣòótọ́; ó lè jẹ́ kéèyàn pàdánù ojú rere Jèhófà Ọlọ́run.
Ó mà ṣe o, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí hu irú ìwà àìṣòótọ́ míì. Wọ́n ti ní olólùfẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọn ò sì jẹ́ káwọn òbí wọn mọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn òbí ọ̀dọ́kùnrin kan dédé rí ọmọbìnrin kan tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwọn tó dé sílé wọn láti iyànníyàn ibi tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ kìlómítà [1,500] lọ, wọ́n lanu wọn ò lè pa á dé. Oṣù kẹfà nìyẹn tóun àti ọmọkùnrin wọn ti ń fẹ́ra lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn òbí yìí ò sì gbọ́ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rí!
Ìbéèrè tó jáde lẹ́nu wọn ni pé: “Kí ló lè fa irú eléyìí ná?” Wọ́n rò ó lọ́kàn pé, ‘Ọmọkùnrin wa ò lè dẹnu fífẹ́ kọ ẹnì kan tí wọn ò tíì jọ pàdé lójúkojú rí.’ Àṣé, ọmọkùnrin wọn ti ń tàn wọ́n jẹ, tó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi irú ẹni tó jẹ́ pa mọ́. Ṣé ìwọ náà wá gbà báyìí pé kò yẹ kéèyàn fi irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà?
Yan Ọ̀rẹ́ Tó O Lè Fojú Rí Dípò Ọ̀rẹ́ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì
Àwọn ewu míì tún wà níbi fífẹ́ èèyàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà míì, ó lè dà bíi pé ọ̀rẹ́ tó o mọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń wù ẹ́ ju àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ríra yín lójoojúmọ́ lọ. Á wá di pé kọ́rọ̀ àwọn ẹbí ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ àti ojúṣe ẹ má ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Monika láti orílẹ̀-èdè Austria sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn ẹni tó ṣe pàtàkì sí mi tì torí pé mò ń lo àkókò púpọ̀ nídìí kọ̀ǹpútà pẹ̀lú àwọn tí mo pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.” Nígbà tó ríbi tí ọ̀rọ̀ ń lọ, ẹ̀rù bà á, ló bá sọ pé òun ò ní lọ́rẹ̀ẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì mọ́.
Àmọ́ ṣá o, àwọn kan kì í kọjá àyè wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Lẹ́tà téèyàn bá ń kọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń jẹ́ kàwọn ọ̀rẹ́ àti ará lè máa gbúròó èèyàn. Síbẹ̀, ìwọ náà á gbà pé kò sí ohun tó dáa tó bíbára ẹni sọ̀rọ̀ lójúkojú. Tó o “bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe,” ìyẹn àkókò tí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ sábà máa ń lágbára lọ́kàn èèyàn jù, tó sì wù ẹ́ láti ṣègbéyàwó, mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé ẹ lo fẹ́ ṣe yẹn. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Tóò, rò ó dáadáa kó o tó ṣèpinnu.
Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Dípò tí wàá fi gba gbogbo ohun tẹ́nì kan tó ò tíì rí rí kọ ránṣẹ́ sí ọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì gbọ́, ṣe ló yẹ kó o ro àròjinlẹ̀ nípa rẹ̀ o. Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló dáa jù, pé kéèyàn pàdé ẹnì kan tó máa yàn lọ́rẹ̀ẹ́ lójúkojú. Wádìí bóyá lóòótọ́ lẹ bá ara yín mu, pàápàá tó bá dọ̀ràn ohun tó o fẹ́ ṣe nípa tẹ̀mí àti ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé. Irú ìfẹ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ ló máa ń yọrí sí ìgbéyàwó olóyinmọmọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ‘Ṣé Mo Lè Rẹ́ni Fẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?’” tó jáde nínú Jí May 8, 2005.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ṣó dá ọ lójú pé o mọ ẹni tó ń tẹ ọ̀rọ̀ tó ò ń kà yìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Tó bá dọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà kò sí àbùjá míì ju pé kẹ́ ẹ fojú kan ara yín kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀