Ṣó Dáa Kí Ọkùnrin àti Obìnrin Máa Gbé Pọ̀ Kí Wọ́n Tó Ṣègbéyàwó?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣó Dáa Kí Ọkùnrin àti Obìnrin Máa Gbé Pọ̀ Kí Wọ́n Tó Ṣègbéyàwó?
ǸJẸ́ o máa ra kóòtù tàbí ẹ̀wù kan láìjẹ pé o kọ́kọ́ wò ó bóyá ó bá ẹ mu? Bóyá ni. Torí pé tó o bá lọ mọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà pé kò bá ẹ mu, ńṣe ló fi owó àti àkókò ẹ ṣòfò.
Ọ̀pọ̀ máa ń lo irú àpèjúwe yìí tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó. Wọ́n ronú pé ó dáa kí ọkùnrin àti obìnrin kọ́kọ́ máa gbé pọ̀ kí wọ́n tó ṣàdéhùn láti di tọkọtaya. Wọ́n máa ń sọ pé, ‘bí ọ̀rọ̀ wọn ò bá wọ̀, àwọn méjèèjì lè pínyà, kí kálukú sì máa bá tiẹ̀ lọ, láì sí pé wọ́n ń náwó rẹpẹtẹ sórí ìkọ̀sílẹ̀ tó sábà máa ń gba àkókò.’
Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ní irú èrò yìí ti rí àwọn ọ̀rẹ́ wọn kan tó ti ṣègbéyàwó tí wọ́n máa ń rọ̀jò kòbákùngbé ọ̀rọ̀ lé ara wọn lórí. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ti rí wàhálà tó máa ń wà nínú ìgbéyàwó tí tọkọtaya ò ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́. Torí èyí, wọ́n lè ronú pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ bí ọkùnrin àti obìnrin bá kọ́kọ́ gbè pọ̀ ná kí wọ́n tó ṣàdéhùn ìgbéyàwó.
Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ìgbéyàwó.
“Ara Kan”
Ojú pàtàkì ni Bíbélì fi wo ìgbéyàwó, èyí ò sì yà wá lẹ́nu, torí pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24) Láti ìbẹ̀rẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé kí ọkọ àti aya di “ara kan” tí wọ́n bá ti ṣe ìgbéyàwó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lẹ́yìn tí Jésù ṣe àyọlò ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì, ó wá fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.
Òótọ́ ni pé àwọn kan tí wọ́n ṣègbéyàwó máa kọ ara wọn sílẹ̀ tó bá yá. a Bí èyí bá ṣẹlẹ̀, kì í ṣe ètò ìgbéyàwó ló ní ìṣòro; kàkà bẹ́ẹ̀, ọkọ àti aya, tàbí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì ni kò mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn ṣẹ.
Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ọkùnrin àti obìnrin kan ní ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, àmọ́ wọn kì í tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tó ṣe ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ náà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bójú tó o. Bí ọkọ̀ yẹn bá wá dẹnu kọlẹ̀, ẹ̀bi ta ni? Ṣé ẹ̀bi ẹni tó ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ni àbí ẹni tó rà á tí kò bójú tó o bó ṣe yẹ?
Bí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ṣe rí náà nìyẹn. Bí ọkọ àti aya ò bá jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wọn jẹ́, tí wọ́n sì pinnu láti yanjú àwọn ìṣòro wọn nípa títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, kò dájú pé wọ́n á kọra wọn sílẹ̀. Àdéhùn tí wọ́n bára wọn ṣe á jẹ́ kí
wọ́n ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Èyí á wá mú kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nígbà gbogbo.“Ẹ Ta Kété sí Àgbèrè”
Àwọn kan ṣì lè máa ronú pé: ‘Kí ló dé ta ò fi lè kọ́kọ́ máa gbé pọ̀? Ǹjẹ́ kò fi hàn pé èèyàn ka ìgbéyàwó sí ohun mímọ́ tí ọkùnrin àti obìnrin bá kọ́kọ́ gbé pọ̀ kí wọ́n tó ṣàdéhùn ìgbéyàwó?’
Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ṣe kedere. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè” fún gbogbo ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni. Èyí kan pé kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò ṣègbéyàwó máa gbé pọ̀, ì báà jẹ́ pé wọ́n ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó. Torí náà, lójú ìwòye Bíbélì, kò dáa kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò ṣègbéyàwó máa gbé pọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì máa ṣègbéyàwó.
Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ yìí ṣì wúlò lóde òní? Àwọn kan lè ronú pé kò wúlò. Torí pé, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọn ò rí ohun tó burú nínú kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò gbéyàwó máa gbé pọ̀, yálà wọ́n ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó tàbí wọn ò ní in lọ́kàn. Àmọ́ ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ ilé àwọn tí wọ́n ń gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó máa ń tòrò? Ǹjẹ́ wọ́n máa ń láyọ̀ ju àwọn tó ṣègbéyàwó lọ? Lẹ́yìn ìgbéyàwó, ǹjẹ́ wọ́n máa ń ṣòótọ́ sí ara wọn ju àwọn tí kò kọ́kọ́ gbé pọ̀ lọ? Ìwádìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn tó bá kọ́kọ́ gbé pọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó máa ń ní ìṣòro tó pọ̀ jù, wọ́n sì máa pàpà kọ ara wọn sílẹ̀ náà ni.
Àwọn ògbóǹkangí kan sọ pé àwọn ò gbà pẹ̀lú ohun tí ìwádìí yìí sọ. Obìnrin kan tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú sọ pé: “Àwọn tó yàn láti ṣègbéyàwó láìkọ́kọ́ [gbé pọ̀] yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n yàn láti kọ́kọ́ [gbé pọ̀] kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.” Obìnrin náà tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀rọ̀ pé ọkùnrin àti obìnrin gbé pọ̀ kọ́ ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe pé kéèyàn ṣáà ti “ka ìgbéyàwó sí ohun pàtàkì.”
Ká tiẹ̀ wá sọ pé òótọ́ lohun tí obìnrin yìí sọ, ńṣe ni ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti máa fojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó wò ó. Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” (Hébérù 13:4) Bí ọkùnrin àti obìnrin kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di ara kan tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó, àjọṣe wọn á ṣe tímọ́tímọ́, kò sì ní rọrùn fún ohunkóhun láti da àárín wọn rú.—Oníwàásù 4:12.
Ká wá pa dà sórí àpèjúwe tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn wò ó bóyá kóòtù tàbí ẹ̀wù kan bá èèyàn mu kó tó rà á. Àmọ́, kí ọkùnrin àti obìnrin máa gbé pọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kọ́ ló máa dènà ìṣòro lẹ́yìn ìgbéyàwó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kéèyàn fara balẹ̀ dáadáa láti mọ ìwà ẹni tó fẹ́ fi ṣe ọkọ tàbí aya. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í sábà ka ọ̀rọ̀ yìí sí, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó máa ń mú kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíbélì fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀, kéèyàn sì fẹ́ ẹlòmíì, bí ọkọ tàbí aya bá ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì.—Mátíù 19:9.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé a ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni? —Sáàmù 84:11; 1 Kọ́ríńtì 6:18.
◼ Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kó o wá lara ẹni tó o fẹ́ fẹ́?—Rúùtù 1:16, 17; Òwe 31:10-31.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
‘Ẹ̀ṢẸ̀ SÍ ARA ẸNI’
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Àràádọ́ta èèyàn tí àrùn éèdì àtàwọn àrùn ìbálòpọ̀ míì ti pá ní ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Kò tán síbẹ̀ o. Ìwádìí fi hàn pé, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń ní ìbálòpọ̀ gan-an sábà máa ń ní ìdààmú ọkàn, wọ́n sì máa ń fẹ́ láti gbẹ̀mí ara wọn. Ìṣekúṣe tún máa ń yọrí sí oyún ẹ̀sín, ńṣe ni wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣẹ́ oyún náà. Látàrí gbogbo èyí, ó ṣe kedere pé ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó tọ́ ṣì wúlò lóde òní.