Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀?

“Mo gbìyànjú gan-an láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fáwọn òbí mi, àmọ́ mi ò mọ bí mo ṣe máa gbọ́rọ̀ náà kalẹ̀ dáadáa, bí wọ́n ṣe dá ọ̀rọ̀ náà mọ́ mi lẹ́nu nìyẹn. Ó ṣòro fún mi láti pa dà sọ ohun tí mo ní lọ́kàn fún wọn, ibi tí gbogbo ẹ̀ sì parí sí nìyẹn!”—Rosa. a

NÍGBÀ tó o ṣì kéré, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn òbí rẹ lo máa ń tọ̀ lọ bó o bá nílò ìmọ̀ràn. Kò sí ohun tí o kì í sọ fún wọn. O máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ, ohun tí wọ́n bá sì sọ lo máa ń ṣe.

Àmọ́ ní báyìí, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí rẹ ò lóye rẹ dáadáa mọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Edie sọ pé, “nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí sunkún nígbà tá à ń jẹun tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi. Àwọn òbí mi tẹ́tí sí mi, àmọ́ ó jọ pé wọn ò lóye mi.” Kí nìyẹn yọrí sí? “Ńṣe ni mo kọjá lọ sínú yàrá mi, tí mo sì túbọ̀ ń sunkún!”

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà míì wà táá wù ẹ́ pé kó o sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fáwọn òbí ẹ. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Christopher sọ pé: “Mo máa ń bá àwọn òbí mi sọ oríṣiríṣi nǹkan. Àmọ́, nígbà míì, kì í wù mí kí wọ́n mọ gbogbo ohun tí mò ń rò lọ́kàn.”

Ṣó burú kó o fàwọn ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fáwọn òbí ẹ? Kò burú, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé kì í ṣe pé ò ń tàn wọ́n. (Òwe 3:32) Síbẹ̀ náà, bóyá ńṣe làwọn òbí ẹ ò lóye ẹ dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ńṣe lò ń fi ọ̀rọ̀ pa mọ́ fún wọn, ohun kan tó dájú ni pé: O ní láti máa bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, wọ́n sì ní láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

Má Panu Mọ́!

Láwọn ọ̀nà kan, ńṣe ni bíbá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ dà bí ìgbà tó o bá ń wa mọ́tò. Tí ọ̀nà tó ò ń gbà lọ bá dí, o ò ní pa dà sẹ́yìn, ńṣe lo máa wá ọ̀nà míì gbà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ìṣòro Àkọ́kọ́: O ní ohun tó o fẹ́ bá àwọn òbí ẹ sọ, àmọ́, ó dà bíi pé wọn ò rí tìẹ rò. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Leah sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi láti bá dádì mi sọ̀rọ̀. Nígbà míì, a ti lè máa sọ̀rọ̀ lọ́ o, wọ́n á kàn ṣàdédé sọ pé: ‘Máà bínú o, ṣé èmi lò ń bá sọ̀rọ̀?’”

ÌBÉÈRÈ: Kí ló yẹ kí Leah ṣe bó bá jẹ́ pé ìṣòro kan tó ní ló fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? Ó kéré tán, ohun mẹ́tà wà tó lè ṣe.

Ohun Àkọ́kọ́ Ohun Kejì Ohun Kẹta

Kó jágbe mọ́ dádì Kó má sọ ohun tó Kó dúró di ìgbà tí àkókò bá

rẹ̀. Leah lè kígbe pé: fẹ́ sọ mọ́. Leah lè wọ̀, kó tó sọ ohun tó ní í sọ. Leah

“Ohun tí mo fẹ́ sọ ṣe pinnu pé òun ò ní sọ lè pa dà lọ bá dádì ẹ̀ tàbí

pàtàkì! Ẹ gbọ́ tèmi!” ìṣòro òun fún àwọn kó kọ lẹ́tà sí i nípa ìṣòro tó ní.

òbí òun mọ́.

Èwo nínú àwọn ohun wọ̀nyí lo rò pé ó yẹ kí Leah ṣe? ․․․․․

Jẹ́ ká gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn àbá yìí yẹ̀ wò, ká sì wo ibi tó ṣeé ṣe kí wọ́n já sí. Dádì Leah ò fọkàn sí ohun tí Leah ń bá a sọ, torí náà kò mọ ìṣòro tí ọmọ rẹ̀ ń bá yí. Tí Leah bá mú Ohun Àkọ́kọ́, tó jágbe mọ́ dádì ẹ̀, ìyẹn lè máà ṣàṣeyọrí kankan. Bó bá jẹ́ ohun tí Leah ṣe nìyí, kò ní mú kí dádì rẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ò ní pọ́n àwọn òbí ẹ̀ lé, kò sì ní fi hàn pé ó ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (Éfésù 6:2) Ó dájú pé èyí ò ní yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Ó jọ pé Ohun Kejì, ló rọrùn jù, àmọ́ òun kọ́ ló bọ́gbọ́n mu jù lọ. Kí nìdí? Torí pé “àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 15:22) Kí Leah lè borí ìṣòro rẹ̀, ó ní láti bá àwọn òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀, tí ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí bá sì wà tí wọ́n á ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí i. Bó bá kọ̀ tí ò sọ ìṣòro rẹ̀ fún wọn mọ́, ọ̀ràn náà ò ní yanjú.

Àmọ́ tí Leah bá mú Ohun Kẹta, a jẹ́ pé kò fẹ́ bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín òun àti àwọn òbí rẹ̀ nìyẹn. Á kúkú dúró di ìgbà tí àkókò bá wọ̀ kó tó sọ ohun tó ní í sọ. Tó bá sì yàn láti kọ lẹ́tà sí dádì ẹ̀, ìyẹn lè mú kọ́rọ̀ náà fúyẹ́ lọ́kàn ẹ̀ lójú ẹsẹ. Tó bá kọ lẹ́tà, èyí lè ràn án lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà gan-an bó ṣe wà lọ́kàn ẹ̀ nígbà tí dádì ẹ̀ bá ṣe tán láti gbọ́. Tí dádì Leah bá ka lẹ́tà náà, á mọ ohun tí ọmọ rẹ̀ fẹ́ bá a sọ, èyí sì lè mú kó túbọ̀ mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro ọmọ náà. Nípa báyìí, Ohun Kẹta yìí máa ṣàǹfààní fún Leah àti dádì rẹ̀.

Kí làwọn nǹkan míì tí Leah lè ṣe? Wò ó bóyá wàá lè ronú kan ohun míì tó lè ṣe, kó o sì kọ ọ́ sórí ìlà yìí. Lẹ́yìn náà, kọ ibi tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà yọrí sí.

․․․․․

Ìṣòro Kejì: Àwọn òbí rẹ fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀, àmọ́ o rò pé kì í ṣe àkókò yìí ló yẹ kó o sọ̀rọ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Kò sóhun tó burú bíi kí wọ́n máa da ìbéèrè bò mí, lẹ́yìn gbogbo wàhálà iléèwé. Ó máa ń wù mí kí n gbé ọ̀rọ̀ iléèwé kúrò lọ́kàn, àmọ́ kí n máà tíì wọlé ni, àwọn òbí mi á ti máa bi mí pé: ‘Òní ti rí? Ṣé kò sí ìṣòro?’” Ó dájú pé torí àwọn òbí Sarah fẹ́ ohun tó dáa fún ọmọ wọn ni wọ́n ṣe ń bi í láwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Síbẹ̀ Sarah sọ pé: “Ó máa ń nira láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ iléèwé nígbà tó ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu.”

ÌBÉÈRÈ: Kí ló yẹ kí Sarah ṣe láti yanjú ìṣòro yìí? Bíi ti àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò ṣáájú, ó kéré tán ohun mẹ́ta wà tó lè ṣe.

Ohun Àkọ́kọ́ Ohun Kejì Ohun Kejì

Kó má sọ̀rọ̀. Ó lè sọ Kó dá wọn lóhùn. Bó tiẹ̀ Kó pa ọ̀rọ̀ “iléèwé” tì, àmọ́,

pé: “Ẹ fi mi sílẹ̀ jàre. jẹ́ pé ó ti rẹ Sarah, kó bá wọn sọ̀rọ̀ lórí

Mi ò tíì fẹ́ sọ̀rọ̀ báyìí!” ó lè fìbínú dáhùn ìbéèrè kókó míì. Sarah lè dábàá pé

táwọn òbí rẹ̀ bi í. kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ iléèwé di

ìgbà míì tó ṣeé ṣe kí ara òun balẹ̀

láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó

lè fi tọkàntọkàn sọ pé: “Báwo

ni iṣẹ́ yín ṣe rí lónìí. Ṣé ẹ gbádùn ẹ̀?”

Èwo nínú àwọn ohun wọ̀nyí lo rò pé ó yẹ kí Sarah ṣe?

․․․․․

Jẹ́ ká tún wá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá yẹn, ká wo ibi tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn máa já sí.

Inú ti ní láti bí Sarah kó tó lè mú Ohun Àkọ́kọ́, kò sì ní wù ú láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Bó bá sì mú un, inú á ṣì máa bí i, á sì tún máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi pé òun pariwo lé àwọn òbí òun lórí.—Òwe 29:11.

Àwọn òbí Sarah kò ní nífẹ̀ẹ́ sí bó ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà di ariwo tàbí bí wọn ò ṣe ni bára wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà. Wọ́n lè rò pé Sarah ń fi ohun kan pa mọ́ fún àwọn. Wọ́n tiẹ̀ lè sapá láti mú kí Sarah sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wọn, ìyẹn á sì túbọ̀ tán an ní sùúrù. Lópin ẹ̀, èyí ò ní yọrí síbi tó dá a.

Ó ṣe kedere pé Ohun Kejì sàn ju Ohun Àkọ́kọ́ lọ. Ó ṣe tán, Sarah àtàwọn òbí rẹ̀ á ṣì máa bára wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ torí pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà kì í ṣe látọkànwá, Sarah àtàwọn òbí ẹ kò ní rí ohun tí wọ́n ń fẹ́. Ìyẹn ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ fàlàlà láì fi ohunkóhun pa mọ́.

Àmọ́ tí Sarah bá ṣe Ohun Kẹta, ara máa tù ú torí pé ní báyìí wọ́n á ti pa ọ̀rọ̀ “ilé ìwé” tì. Àwọn òbí rẹ̀ á mọyì ipá tó sà láti bá wọn sọ̀rọ̀, inú wọ́n á sì dùn sí i. Ó ṣeé ṣe kí èyí so èso rere torí pé àtòbí àtọmọ ló ń fi ìlànà tó wà nínú Fílípì 2:4, sílò, èyí tó sọ pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

◼ Ipa wo ni mímọ àkókò tó wọ máa kó nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀?—Òwe 25:11.

◼ Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kó o sapá láti máa bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀?—Jóòbù 12:12.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ṢÉ OHUN TÓ O FẸ́ KÍ WỌ́N GBỌ́ KỌ́ NI WỌ́N Ń GBỌ́?

Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀? Ó lè jẹ́ pé ohun tó ò ń sọ kọ́ ni wọ́n ń gbọ́?

Bó o bá sọ pé . . .

“Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

Ohun táwọn òbí rẹ á fi gbọ́ ni . . .

“Kò sí nǹkan tí mò ń rò lọ́kàn tí mi ò lè sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi, àmọ́, mi ò kà yín sẹ́ni tó yẹ kí n máa sọ tinú mi fún.”

Bó o bá sọ pé . . .

“Kò lè yée yín.”

Ohun táwọn òbí rẹ á fi gbọ́ ni . . .

“Ẹ ti dàgbà, ẹ ò sì mọ ohun tó ń lọ. Ẹ má tiẹ̀ rò pé ẹ lè lóye ohun tó ń ṣe mi.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ

“Mo sọ ìṣòro kan tí mo ní níléèwé fáwọn òbí mi, ó sì yà mí lẹ́nu pé wọ́n fetí sílẹ̀ dáadáa. Bí wọ́n ṣe dá sí ọ̀rọ̀ náà mú kó tètè yanjú!”—Natalie.

“Ó lè má rọrùn fún ẹ láti bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, àmọ́ tó o bá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún wọn, ńṣe ló máa dà bíi pé ẹrù tó wúwo kan kúrò léjìká ẹ.” —Devenye.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Bó o bá jẹ́ òbí tí ọ̀rọ̀ ọmọ jẹ lógún, ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì bóyá ó máa ń ṣòro fáwọn ọmọ rẹ láti ba ẹ sọ̀rọ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ fún àwọn tó kọ ìwé ìròyìn yìí pé ó fà á tí àwọn kì í fi í bá àwọn òbí àwọn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi ara rẹ láwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e, kó o sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀.

Ohun tó mú kó ṣòro fún mi láti máa bá Dádì sọ̀rọ̀ ni pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń bójú tó níbi iṣẹ́ àti nínú ìjọ ti pọ̀ jù. Kì í sí àyè rárá láti bá wọn sọ̀rọ̀.”—Andrew.

‘Ǹjẹ́ ìhà tí mo kọ sáwọn ọmọ mi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà ti jẹ́ kí wọ́n gbà pé mi ò ráyè tiwọn rárá? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni mo lè ṣe tí á fi túbọ̀ rọrùn fún wọn láti màá tọ̀ mí wá? Àkókò wo ni mo lè yà sọ́tọ̀ láti máa bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ déédéé?’—Diutarónómì 6:7.

Pẹ̀lú omijé lójú ni mò ń sọ fún mọ́mì mi nípa àríyànjiyàn kan tó wáyé láàárín èmi àti ẹnì kan níléèwé wa. Mo fẹ́ kí Mọ́mì sọ̀rọ̀ tó máa tù mí nínú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí mi. Látìgbà yẹn ni mi ò ti bá wọn sọ̀rọ̀ pàtàkì mọ́.”—Kenji.

‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe táwọn ọmọ mi bá sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn fún mi? Bó bá tiẹ̀ gba pé kí n tún èrò wọn ṣe, ṣe mo lè fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu wọn ná, kí n lè mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn kí ń tó fún wọn nímọ̀ràn?’—Jákọ́bù 1:19.

Ó jọ pé gbogbo ìgbà táwọn òbí bá sọ pé ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa pé àwọn ò ní bínú, wọ́n ṣì máa pàpà fara ya náà ni. Ìyẹn sì máa ń dunni gan-an.”—Rachel.

‘Bí ọmọ mi bá sọ ohun kan tó bí mi nínú, báwo ni mo ṣe lè fọwọ́ wọ́nú kí n má sì ṣi inú bí?’—Òwe 10:19.

Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kan nípa ara mi fún Mọ́mì, kíá, wọ́n ti lọ sọ fáwọn ọ̀rẹ́ wọn. Èyí mú kí n má fọkàn tán wọ́n mọ́ fún ìgbà pípẹ́.”—Chantelle.

‘Ǹjẹ́ mo máa ń fi hàn pé mo gba ti ọmọ mi rò, nípa ṣíṣàì sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó fi sí mi lọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíì?’—Òwe 25:9.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lọ́kàn mi tí mo fẹ́ sọ fáwọn òbí mi, ó kàn jẹ́ pé á wù mí kó jẹ́ àwọn ló máa dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀.”—Courtney.

‘Ǹjẹ́ mo lè dá ìjíròrò sílẹ̀ pẹ̀lú ọmọ mi? Ìgbà wo ló dáa jù láti sọ̀rọ̀?’—Oníwàásù 3:7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kò pọn dandan kó o jẹ́ kí ohunkóhun bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín ìwọ àti àwọn òbí rẹ, o lè wá ọ̀nà ti wàá gbà bá wọn sọ̀rọ̀