Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

Kí Ni Kò Tọ̀nà Nínú Àwòrán Yìí?

Ka Ìṣe 8:26-40. Wo àwòrán yìí. Àwọn nǹkan wo ni kò tọ̀nà nínú àwòrán náà? Kọ ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà yìí.

1. ․․․․․

2. ․․․․․

3. ․․․․․

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí nìdí tí ìwẹ̀fà yẹn kò fi lóye ohun tó ń kà? Ta ló ràn án lọ́wọ́ tó fi lóye ohun tó ń kà? Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fara wé ìwẹ̀fà yẹn?

Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí

Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.

OJÚ ÌWÉ 3 Ẹni tí kò bá pèsè fún ìdílé rẹ̀ burú ju ta ni lọ? 1 Tímótì 5:․․․

OJÚ ÌWÉ 16 Bó bá dọ̀rọ̀ ìrísí wa, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn? 1 Pétérù 3:․․․

OJÚ ÌWÉ 24 Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ kí ló yẹ kó o ṣe? Róòmù 12:․․․

OJÚ ÌWÉ 27 Ká bàa lè máa láyọ̀, kí ló gbọ́dọ̀ máa jẹ wá lọ́kàn? Mátíù 5:․․․

Kí Lo Mọ̀ Nípa Jẹ́fútà Onídàájọ́?

Ka Àwọn Onídàájọ́ 11:1–12:7. Dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

4. ․․․․․

Èwo lára ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ló ti wá?

AMỌ̀NÀ: Wo Númérì 26:29.

5. ․․․․․

Ọwọ́ orílẹ̀-èdè wo ló ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀?

6. ․․․․․

Bẹ́ẹ̀ ni tàbí rárá? Ó gbé ayé lẹ́yìn Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Jákọ́bù (Ísírẹ́lì).

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí lo rò pé ó mú kí ọmọbìnrin Jẹ́fútà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí bàbá rẹ̀ lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ? Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọmọbìnrin Jẹ́fútà?

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ

1. Ó jọ pé Fílípì nìkan ló dá wà.

2. Kẹ̀kẹ́ ẹṣin ni ìwẹ̀fà yẹn gùn kì í ṣe ẹṣin.

3. Aṣálẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ti wáyé kì í ṣe àárín ìlú téèyàn pọ̀ sí.

4. Mánásè.—Númérì 26:29; Àwọn Onídàájọ́ 11:1.

5. Ámónì—Àwọn Onídàájọ́ 11:4.

6. Òótọ́.