Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Keje: Àjọṣe Tó Fìdí Múlẹ̀ Ṣinṣin

Ohun Keje: Àjọṣe Tó Fìdí Múlẹ̀ Ṣinṣin

Ohun Keje: Àjọṣe Tó Fìdí Múlẹ̀ Ṣinṣin

Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Bó ṣe jẹ́ pé ilé kan kì í ṣàdédé wà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìjẹ́ pé a kọ́ ọ sórí ìpìlẹ̀ tó lágbára, bẹ́ẹ̀ ni ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan kì í ṣàdédé wà fún ìgbà pípẹ́, bí kò ṣe pé a kọ́ ọ sórí àjọṣe tó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin. Ìdílé tó bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó wúlò máa ń wà ní ìṣọ̀kan.

Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ìmọ̀ràn tó wà fún ìdílé pọ̀ gan-an nínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn àti àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn kan tó ń gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó máa ń rọ àwọn tọkọtaya tí wọ́n níṣòro nínú ìgbéyàwó wọn pé kí wọ́n má ṣe fira wọn sílẹ̀, nígbà táwọn míì á sì sọ pé kí wọ́n tú ká. Èrò táwọn ògbógi gan-an ní nípa ọ̀ràn náà kò yéé yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1994, gbajúmọ̀ onímọ̀ nípa ìtọ́jú láìlo egbòogi, tó máa ń ṣètọ́jú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bàlágà kọ̀wé pé nígbà tóun kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, òun lérò pé “ó sàn káwọn ọmọ máa gbé lọ́dọ̀ òbí kan ṣoṣo tó láyọ̀ ju kí wọ́n máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí méjèèjì tí kò láyọ̀. Mo ronú pé ìkọ̀sílẹ̀ sàn ju kéèyàn máa rún ìgbéyàwó tí kò fara rọ mọ́ra.” Àmọ́ lẹ́yìn ogún ọdún lẹ́nu iṣẹ́, ó yí èrò rẹ̀ pa dà. Ó sọ pé: “Ìkọ̀sílẹ̀ máa ń ba ọ̀pọ̀ ọmọ láyé jẹ́.”

Èrò èèyàn kì í dúró sójú kan, àmọ́ ìmọ̀ràn dídára jù lọ yòówù tó bá wà kò gbọ́dọ̀ ta ko àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì. Bó o ṣe ń ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wàá ti kíyè sí i pé ìlànà Bíbélì kọ̀ọ̀kan wà lápá òkè lójú ìwé 3 sí 8. Irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ ti ran ọ̀pọ̀ ìdílé lọ́wọ́ láti wà ní ìṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ní ìṣòro bíi tàwọn ìdílé yòókù. Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé Bíbélì ni ìpìlẹ̀ tó lágbára èyí tí wọ́n kọ́ ìgbéyàwó wọn lé. Bó sì ṣe yẹ́ kó rí náà nìyẹn, torí pé Jèhófà Ọlọ́run tó ni Bíbélì ló dá ìdílé sílẹ̀.—2 Tímótì 3:16, 17.

Gbìyànjú èyí wò. Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ lápá òkè lójú ìwé 3 sí 8. Fi àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kún un. Máa jẹ́ kí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o kọ sílẹ̀ yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, kó o sì máa yẹ̀ wọ́n wò déédéé.

Pinnu ohun tó o máa ṣe. Pinnu láti máa fi Bíbélì sílò nínú ìgbéyàwó rẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Bó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nínú ìdílé rẹ, ìṣòro ò ní lè bì í wó, bí ìjì ò ṣe lè bi ilé tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lágbára wó