Àwọn Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Láti Jẹ́ Olóòótọ́
Àwọn Ohun Tó Mú Kó Ṣòro Láti Jẹ́ Olóòótọ́
“Ayé àtijọ́ làwọn èèyàn ti máa ń ṣòótọ́ nídìí iṣẹ́ ajé, ẹni tó bá dán irú ẹ̀ wò lóde òní, inú ìyà lonítọ̀hún máa kú sí.”—Stephen, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
ṢÉ ÌWỌ náà fara mọ́ ohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ? Òótọ́ ni pé àwọn aláìṣòótọ́ sábà máa ń rí èrè jẹ nídìí ìwà àìṣòótọ́ wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Èyí sì máa ń mú kí ó ṣòro fún àwọn olóòótọ́ èèyàn láti máa ṣe ohun tó tọ́ ní àwọn ọ̀nà tá a tò sísàlẹ̀ yìí.
Ohun Tó Máa Ń Dẹni Wò. Ta ni kò fẹ́ kí owó rẹpẹtẹ máa wọlé fún òun kí òun sì máa gbádùn oríṣiríṣi àwọn nǹkan afẹ́? Nígbà tí àǹfààní láti rí owó rẹpẹtẹ lọ́nà èrú bá yọjú, kì í rọrùn láti kọ̀.
● “Níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́, èmi ni mo máa ń gbéṣẹ́ fún àwọn agbaṣẹ́ṣe. Àwọn èèyàn sábà máa ń fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ̀ mí. Béèyàn bá rí owó téèyàn ò làágùn fún, ó máa ń ṣòro gan-an láti kọ̀.”—Franz, Àárín Ìlà Oòrùn Ayé.
Èrè Àjẹjù. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú kí nǹkan ṣòro fún àwọn oníṣòwò kárí ayé. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń sáré bí wọn ò ṣe ní dẹni ẹ̀yìn pẹ̀lú bí ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe ń tẹ̀ síwájú, tí àwọn iléeṣẹ́ nílé lóko sì ń figa gbága. Àwọn òṣìṣẹ́ lè máa wò ó pé àfi tí àwọn bá wá ọgbọ́n dá, kí àwọn fi irọ́ gbe òótọ́ lẹ́yìn, kí àwọn tó lè máa tẹ́ àwọn tó ni iléeṣẹ́ àti àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ lọ́rùn.
● “A ò rí ọgbọ́n míì dá sí i, àfi kí á ṣe bẹ́ẹ̀. . . . Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ilé iṣẹ́ á kógbá wọlé.”—Reinhard Siekaczek, ẹni tí wọ́n fi òfin mú nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀.—Ìwé ìròyìn The New York Times.
Bí Àwọn Èèyàn Ṣe Ń Fúngun Mọ́ni. Àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn oníbàárà lè dá a lábàá, tàbí kí wọ́n fúngun mọ́ ẹ pé kí ìwọ náà máa lọ́wọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n ń hù.
● “Ọ̀gá iléeṣẹ́ ńlá kan tí mo ti máa ń gba iṣẹ́ sọ fún mi pé mi ò ní rí iṣẹ́ gbà mọ́ bí mi ò bá fún òun ní ‘ẹ̀tọ́ tòun,’ ìyẹn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”—Johan, orílẹ̀-èdè South Africa.
Àṣà Tó Wọ́pọ̀. Láwọn ibì kan, ó ti di àṣà àwọn iléeṣẹ́ tó ń bára wọn ṣòwò pé kí wọ́n máa fún ara wọn lẹ́bùn. Bí ẹ̀bùn tí wọ́n ń fún ara wọn ṣe pọ̀ tó àti ohun tó fà á tí wọ́n fi ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn náà ti mú kí ó ṣòro fún àwọn èèyàn láti mọ irú ìwà tá a lè pè ní ìwà àìṣòótọ́. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn òṣìṣẹ́ tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ lẹ́wù máa ń béèrè owó kí wọ́n tó ṣe ojúṣe wọn, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì máa ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣe ojúure àrà ọ̀tọ̀ sáwọn èèyàn.
● “Ìṣòro ńlá ló máa ń jẹ́ láti mọ̀ bóyá ẹ̀bùn ni kí á ka ohun tá a fún ẹnì kan sí tàbí àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”—William, orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà.
Àyíká Ibi Tí Èèyàn Wà. Ó túbọ̀ máa ń nira gan-an fún àwọn tí nǹkan kò ṣẹnuure fún tàbí tí wọ́n ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwà ìbàjẹ́ ti gbòde kan láti jẹ́ olóòótọ́. Nírú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ojú aláìfẹ́kan-ánṣe, tí kò fẹ́ pèsè fún ìdílé rẹ̀ ni wọ́n fi máa ń wo ẹni tó bá sọ pé òun kò ní ṣe màgòmágó tàbí pé òun kò ní jí nǹkan.
● “Àwọn èèyàn gbà pé kò sí ohun tó burú nínú ìwà àìṣòótọ́, pé ohun tó pọn dandan ni àti pé ohun tí ayé ń ṣe ni, bí ọwọ́ kò bá ṣáà ti tẹ̀ onítọ̀hún.”—Tomasi, orílẹ̀-èdè Congo Kinshasa.
Ohun Tó Mú Kí Ìṣòtítọ́ Dohun Ìgbàgbé
Kò rọrùn rárá láti jẹ́ olóòótọ́. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà fi hàn pé àwọn mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ló gbà pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ìwà ìbàjẹ́ “kò dára, àmọ́ kò sí bí èèyàn ò ṣe ní lọ́wọ́ sí i.” Àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà sọ pé àwọn ṣe tán
láti gbé ìwà ọmọlúàbí tì sí ẹ̀gbẹ́ kan kí àwọn bàa lè rí iṣẹ́ gbà tàbí kí ọwọ́ àwọn lè tẹ ohun tó máa ṣe iléeṣẹ́ àwọn láǹfààní.Síbẹ̀, àwọn tó ń lọ́wọ́ sí irú àwọn ìwà àìṣòótọ́ yìí máa ń gbà pé olóòótọ́ èèyàn ni àwọn. Ọgbọ́n wo ni wọ́n ń dá sí i nígbà tó jẹ́ pé irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an yàtọ̀ sí irú ìwà tí wọ́n ń hù? Ìwé Ìròyìn kan tó sọ̀rọ̀ nípa káràkátà, ìyẹn Journal of Marketing Research sọ pé: “Ojú kì í ti àwọn èèyàn láti fi èrú gba ìbùkún, wọ́n á sì máa tan ara wọn jẹ pé olóòótọ́ ni àwọn.” Kó má bàa di pé ẹ̀rí ọkàn á máa dà wọ́n láàmú, ńṣe ni wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti dá ara wọn láre, wọ́n lè máa sọ pé ìwà àìṣòótọ́ táwọn ń hù kò fi bẹ́ẹ̀ burú tàbí kí wọ́n máa sọ pé ayé ń ṣe irú ẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà àìṣòótọ́ bí ohun tí kò ba ìwà ọmọlúàbí jẹ́. Wọ́n máa ń sọ pé ńṣe ni ẹni tó ń parọ́ tàbí tó ń ṣe awúrúju “ń dọ́gbọ́n sí i” tàbí pé “kò fẹ́ kí wọ́n jẹ òun máyé.” Wọ́n á sọ pé owó “ojúure” tàbí owó “múṣẹ́ yá” lásán ni àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́.
Àwọn míì máa ń fi ọ̀rọ̀ ṣákálá túmọ̀ ìwà tí kò dára tí wọ́n ń hù láti mú kó dà bíi pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Tom tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tó ń bojú tó ọ̀ràn owó sọ pé: “Èrò táwọn èèyàn ní nípa jíjẹ́ olóòótọ́ ni pé, ó dìgbà tí ọwọ́ bá tẹ ẹnì kan kí wọ́n tó gbà pé ìwà àìṣòótọ́ lonítọ̀hún hù.” Ọ̀gbẹ́ni David tó jẹ́ ọ̀gá àgbà tẹ́lẹ̀ rí nílé ìṣòwò kan sọ pé: “Ìgbà tí àṣírí ẹni tó hùwà àìṣòótọ́ bá tú nìkan làwọn èèyàn tó máa ń wo irú ìwà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò dáa, àmọ́ tí èèyàn bá ṣe é ní àṣegbé, kò sóhun tó burú níbẹ̀. Ọ̀jáfáfá ni wọ́n máa pe ẹni tó bá hùwà àìṣòótọ́ tí ọwọ́ kò sì tẹ̀ ẹ́.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tiẹ̀ máa ń sọ pé bí èèyàn kò bá hùwà àìṣòótọ́, onítọ̀hún kò lè rọ́wọ́ mú láwùjọ. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ti pẹ́ gan-an lẹ́nu ìṣòwò sọ pé: “Nítorí pé àwọn kò fẹ́ kí wọ́n jẹ àwọn máyé ni wọ́n ṣe máa ń sọ pé, ‘Gbogbo ohun tó bá gbà ló yẹ kéèyàn fún un kí iṣẹ́ téèyàn ń wá lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́’.” Àmọ́, ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Àbí ńṣe ni àwọn tó ń gbìyànjú láti dá ìwà àìṣòótọ́ láre kàn ‘ń fi èrò èké tan ara wọn jẹ ni’? (Jákọ́bù 1:22) Jẹ́ ká wo àwọn àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ olóòótọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Èrò táwọn èèyàn ní nípa jíjẹ́ olóòótọ́ ni pé, ó dìgbà tí ọwọ́ bá tẹ ẹnì kan kí wọ́n tó gbà pé ìwà àìṣòótọ́ lonítọ̀hún hù”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé bí èèyàn kò bá hùwà àìṣòótọ́, onítọ̀hún kò lè rọ́wọ́ mú láwùjọ