Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ṣé ó tiẹ̀ yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Wò ó báyìí ná:
Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí ohun iyebíye kan. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó jẹ́ ìwé tó ń tà jù lọ láyé yìí, ará àwọn nǹkan tó o máa jèrè nìyí:
● Wàá mọ ohun tó o lè ṣe láti gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ
● Wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, àwọn ohun tí o kò lè rí níbòmíì
● Wàá mọ irú èèyàn tí ìwọ fúnra rẹ jẹ́, wàá sì mọ bó o ṣe lè mú kí ìwà rẹ̀ dára sí i a
Ó GBA ìsapá kí èèyàn tó lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Ṣé o fẹ́ mọ bí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe ń ṣe é? Gé ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí, kó o sì ká a sí méjì. Ó máa di ìwé olójú mẹ́rin kékeré kan tó máa jẹ́ kó o mọ bí àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ ṣe borí ìṣòro tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra wọn, àti àǹfààní tí wọ́n ń rí nínú rẹ̀.
“Kò sí ẹni tó máa ka Bíbélì tí kò ní rí nǹkan jèrè. Ẹ̀kọ́ tí èèyàn lè kọ́ látinú Bíbélì kò lópin!”—Valerie. b
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kí o lè túbọ̀ mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15, 16]
BÍ O ṢE LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
Ìṣòro: KÌ Í WÙ MÍ LÁTI KẸ́KỌ̀Ọ́
“Kì í fìgbà gbogbo wù mí láti máa fi odindi wákàtí kan jókòó láti máa kàwé.”—Lena.
Ohun tó o nílò: RONÚ NÍPA ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ
Kí o bàa lè gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ kó o dáhùn ìbéèrè yìí: Àǹfààní wo ni màá rí níbẹ̀? Ṣé o fẹ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Ṣé o fẹ́ lóye ìdí tí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé fi ń ṣẹlẹ̀? Ṣé o fẹ́ kí ìwà rẹ̀ túbọ̀ dára sí i? Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, àti àwọn nǹkan míì!
“Má ṣe wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tàbí bí ẹni pé o fẹ́ ṣe ìdánwò ní ilé ìwé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o wò ó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó o lè gbà túbọ̀ sún mọ́ Ọ̀rẹ́ rẹ tó ga jù lọ, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.”—Bethany.
“Tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó jẹ́ àkókò tí o fi ń dá wà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé kìkì ìgbà tí àwọn òbí rẹ bá wà lọ́dọ̀ ẹnì kan lo máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú ẹni náà, ǹjẹ́ a lè sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ ni ẹnì náà lóòótọ́ àbí ọ̀rẹ́ àwọn òbí rẹ? Tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ńṣe ni Jèhófà máa di ọ̀rẹ́ ìwọ fúnra rẹ.”—Bianca.
Rántí pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Ìwọ́ náà lè rí àwọn àǹfààní yìí látinú Bíbélì!
“Àwọn àǹfààní tó wà nínú rẹ̀ ni mo máa ń gbìyànjú láti ronú lé. Bí àwọn nǹkan kan bá wà tí mo ní láti ṣàtúnṣe nípa wọn, mo máa ń lo ìkẹ́kọ̀ọ́ mi láti rí sí àwọn apá yìí kí n sì wá nǹkan ṣe nípa wọn.”—Max.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé:
Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó máa jẹ́ kó wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́?
Ìṣòro: Ó MÁA Ń SÚ MI
“Tó bá ti tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́, ńṣe ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀ mí; tó bá fi tó nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú, ọkàn mi ti kúrò níbẹ̀; nígbà tó bá fi máa tó ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, ó ti sú mi pátápátá!”—Allison.
Ohun tó o nílò: LO ỌGBỌ́N ÌDÁNÚṢE
Máa lo oríṣiríṣi ọgbọ́n ìdánúṣe, bóyá lórí ohun tí ò ń kẹ́kọ̀ọ́, ọ̀nà tí ò ń gbà kẹ́kọ̀ọ́, àti ibi tí o ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́.
“Wá àyè láti ṣèwádìí nípa àwọn ìbéèrè tó o ní. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun kan tó o ti ń ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, nígbà tó o bá fi máa parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, wàá rí i pé kì í ṣe pé o kàn fi àkókò rẹ ṣòfò lásán, inú rẹ sì máa dùn gan-an.”—Richard.
“Tó o bá ń kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, fojú inú wò ó bíi pé ìwọ náà wà nínú ìtàn yẹn. Ṣe bíi pé ìwọ ni ọ̀rọ̀ náà dá lé lórí tàbí pé ńṣe lo wà ní ibì kan tí ò ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Gbìyànjú láti máa fi ojú inú bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.”—Steven.
“Ṣe ohun tó máa mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ ẹ. Jókòó sí ẹ̀yìnkùlé, kí o sì máa wá nǹkan fi panu. Mo fẹ́ràn láti máa jẹ ìpápánu nígbà tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Àbí, tani kò fẹ́ irú ẹ̀?”—Alexandra.
Rántí pé: Ojú tí èèyàn fi ń wo nǹkan ló sábà máa ń jẹ́ kí nǹkan súni, kì í ṣe pé ohun tí èèyàn ń ṣe yẹn gan-an ló ń súni. Dípò tí wàá fi sọ pé “ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń sú mi,” á dáa kó o sọ pé, “kò wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́.” Ojú tó o bá fi wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa mú kó gbádùn mọ́ ẹ tàbí kó sú ẹ. Èyí ló máa mú ìwọ fúnra rẹ kíyè sára kó o sì sapá láti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.—Òwe 2:10, 11.
“Ìdákẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe ohun tó yẹ kó súni. Bóyá ó máa sú ẹ tàbí kò ní sú ẹ, ọwọ́ rẹ ló wà.”—Vanessa.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé:
Àwọn ọgbọ́n ìdánúṣe wo ni ìwọ lè lò tó máa jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ gbádùn mọ́ ẹ?
Ìṣòro: MI KÌ Í RÁYÈ
“Ó máa ń wù mí pé kí n túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ pẹ̀lú bí ọwọ́ mi ṣe máa ń dí, ó máa ń ṣòro fún mi gan-an láti rí àyè jókòó kí n sì ka Bíbélì!”—Maria.
Ohun tó o nílò: OHUN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ
Lára ohun tó máa fi hàn pé o ti ń dàgbà ni pé kó o mọ béèyàn ṣe máa ń “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
“Mọ́mì mi máa ń sọ fún mi pé kò sígbà tí màá rí àyè fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ńṣe ni mo gbọ́dọ̀ wá àyè fún un. Lẹ́yìn tí mo ti wá rí ìdí tó fi yẹ kí n máa kẹ́kọ̀ọ́, mo wá wá àyè fún un.”—Natanya.
“Ní báyìí tí mo ti wá dàgbà ni mó rí i pé ó yẹ kí n ṣètò àkókò tí màá máa kẹ́kọ̀ọ́, àkókò yẹn gan-an ni mo sì máa ń ṣe é, láìka ohun yòówù tó lè ṣẹlẹ̀ sí.”—Yolanda.
“Tó bá jẹ́ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ lo fi ṣáájú eré ìnàjú, mó fi dá ẹ lójú pé wàá túbọ̀ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ, ọkàn rẹ kò sì ní dá ẹ lẹ́bi tó o bá wá ṣe eré ìnàjú.”—Diana.
Rántí pé: Tí o kò bá mọ ohun tó yẹ kó o fi ṣáájú, àkókò máa lọ mọ́ ẹ lọ́wọ́, o ò sì ní lè ṣe ohunkóhun ní àṣeyọrí. Ó sàn pé kó o wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, kó o sì wá àyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́.—Éfésù 5:15, 16.
“Bó ṣe jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ girama ni mò ń lọ, kò sí ìgbà tí ọwọ́ mi kì í dí! Àmọ́, mo rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí n sa gbogbo ipá mi láti máa wá àyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—Jordan.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé:
Irú ètò wo ni ìwọ lè ṣe láti máa kẹ́kọ̀ọ́?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
OHUN TÍ ÀWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ
Zachary—Má kàn máa ka ìwé kan nítorí pé òun ni àwọn òbí rẹ tàbí àwọn míì ń kà. Tó bá jẹ́ pé ohun tí ìwọ alára fẹ́ láti mọ̀ lò ń kà, a jẹ́ pé ìdákẹ́kọ̀ọ́ lò ń ṣe yẹn.
Kaley—Díẹ̀díẹ̀ ni kó o bẹ̀rẹ̀. Ì báà jẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún lo lè lò, ṣáà rí i pé ò ń ṣe é lójoojúmọ́. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, o lè wá máa lo ìṣẹ́jú mẹ́wàá, ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, . . . Tó bá yá, ńṣe ni wàá máa gbádùn rẹ̀ gan-an!
Daniela—Àwọn nǹkan kéékèèké kan wà tó o lè máa ṣe tó lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbádùn mọ́ ẹ. Wá àwọn ìkọ̀wé tó jẹ́ oríṣiríṣi àwọ̀ àti ìwé àjákọ, o sì lè ṣí abala kan lórí kọ̀ǹpútà rẹ tí wàá pe àkọlé rẹ̀ ní Ìdákẹ́kọ̀ọ́.
Jordan—Tó bá jẹ́ kókó kan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí ni mo yàn láti kẹ́kọ̀ọ́, mi kì í mọ̀ pé àkókò ti lọ. Bákan náà, mo máa ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ níbi tó pa rọ́rọ́. Mi ò lè kẹ́kọ̀ọ́ níbi tí ariwo bá wà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Gé e
Ká a sí méjì