Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Òtítọ́ Yóò Sọ Yín Di Òmìnira’—Lọ́nà Wo?

‘Òtítọ́ Yóò Sọ Yín Di Òmìnira’—Lọ́nà Wo?

Ojú Ìwòye Bíbélì

‘Òtítọ́ Yóò Sọ Yín Di Òmìnira’—Lọ́nà Wo?

Ọ̀KẸ́ àìmọye èèyàn ló gbà pé àwọn kì í ṣe ẹrú, àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ẹrú ni wọ́n. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti mú lẹ́rú. Àwọn kan máa ń bẹ̀rù òkú, wọ́n máa ń náwó rẹpẹtẹ kí wọ́n lè rí ojúure àwọn tó ti kú. Ṣe ni ọ̀rọ̀ ikú máa ń mú kí àwọn míì máa gbọ̀n jìnnìjìnnì, torí pé wọn kò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn lẹ́yìn ikú. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn yìí lè dòmìnira lọ́wọ́ èrò òdì, ẹ̀dùn-ọkàn àti gbèsè tí ìbẹ̀rù òkú ń fà fún wọn? Bẹ́ẹ̀ ni! Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jésù Kristi tá a kọ sókè yìí ṣe fi hàn, ohun tó lè mú kí wọ́n dòmìnira ni òtítọ́. Àmọ́, òtítọ́ wo? Ṣé gbogbo ohun tó bá ṣáà ti jẹ́ òtítọ́ ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àbí òtítọ́ kan ní pàtó?

Jésù ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn lọ́nà tó ṣe kedere. Ó sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, . . . ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Inú Bíbélì la ti lè rí “ọ̀rọ̀” Jésù, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Nígbà tí Jésù sọ pé “òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira,” ohun tó ní lọ́kàn gan-an ni bí òtítọ́ ṣe máa sọ wá dòmìnira lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́, yàtọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a mọ̀ tún máa ń sọ wá dòmìnira lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ìbẹ̀rù òkú àti bíbẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá kú. Lọ́nà wo?

1. Òmìnira lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé bí ẹyẹ kowéè bá ké, a jẹ́ pé ẹnì kan máa kú ní àdúgbò náà nìyẹn. Àwọn míì gbà pé béèyàn bá fi ẹsẹ̀ ọ̀tún kọ, àmì nǹkan rere ló jẹ́, àmọ́ tó bá jẹ́ ẹsẹ̀ òsì, a jẹ́ pé àmì nǹkan búburú nìyẹn. Ní ti àwọn míì, ó dìgbà tí wọ́n bá kàn sí àwọn abẹ́mìílò kí wọ́n to ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.

Bí òtítọ́ Bíbélì ṣe ń sọni dòmìnira: Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run gbà gbọ́ nínú àwọn ohun asán, débi pé wọ́n tiẹ̀ ń sin “ọlọ́run Oríire” àti “ọlọ́run Ìpín,” tàbí àyànmọ́! Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára Jèhófà Ọlọ́run? Ó sọ pé, ‘Ẹ ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi.’ (Aísáyà 65:11, 12) Ojú kan náà ni Ọlọ́run fi wo àwọn tó lọ́ ń bá àwọn abẹ́mìílò pé kí wọ́n tọ́ àwọn sọ́nà: “Ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò. . . jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.”—Diutarónómì 18:11, 12.

Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti ìbẹ́mìílò léwu torí pé wọ́n wà lára “àwọn ètekéte Èṣù,” Èṣù yìí sì ni Jésù pè ní “baba irọ́.” (Éfésù 6:11; Jòhánù 8:44) Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ohun kan tó ṣe pàtàkì, ṣé wàá lọ bá òpùrọ́? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà pé kó o yẹra fún ohunkóhun tó bá wá látọ̀dọ̀ “baba irọ́.”

Ohun tó lè mú kéèyàn ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání nígbèésí ayé ni pé kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Bíbélì dáadáa àti ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé. Òwe 2:6 sọ pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”

2. Òmìnira lọ́wọ́ ìbẹ̀rù òkú. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ẹ̀mí àwọn baba ńlá to ti kú lè lágbára lórí àwọn alààyè. Wọ́n gbà pé àwọn gbọ́dọ̀ máa rú àwọn ẹbọ kan láti tu àwọn ẹ̀mí yẹn lójú, èyí tó jẹ́ pé tí àwọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀mí náà máa bínú. Nítorí náà, ṣe ni àwọn kan máa ń tọrùn bọ gbèsè láti ṣèrúbọ kí wọ́n si ṣe àwọn ayẹyẹ ìsìnkú tí ayé á gbọ́ tí ọ̀run á sì mọ̀.

Bí òtítọ́ Bíbélì ṣe ń sọni dòmìnira: Bíbélì sọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ fún wa nípa ipò tí àwọn òkú wà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé ńṣe ni àwọn òkú wà “lójú oorun” tàbí pé wọ́n ń sùn. (Jòhánù 11:11, 14) Kí ló ní lọ́kàn? Ohun tó ní lọ́kàn wà nínú Oníwàásù 9:5: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Ó ṣe kedere pé, ńṣe ló dà bíi pé àwọn òkú ń sùn fọnfọn, tí wọn kò mọ ohunkóhun. Kódà, wọn ò tiẹ̀ sí mọ́, torí náà, wọn kò lè ṣe ohun rere fún wa, wọn ò sì lè pa wá lára.

Àmọ́ ṣá o, àwọn kan sọ pé àwọn ti bá òkú sọ̀rọ̀ rí. Ṣé ó lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́? Bíbélì náà ló tún máa dá wa lóhùn. Ó sọ fún wa pé láìpẹ́ sígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn, àwọn áńgẹ́lì mélòó kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (2 Pétérù 2:4) Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì yìí ní ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì máa ń wá ọ̀nà láti tan aráyé jẹ. (1 Tímótì 4:1) Ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń dọ́gbọ́n ṣe bí ẹni tó kú, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn èèyàn gbà pé àwọn òkú wà láàyè nírú ọ̀nà míì tàbí pé wọ́n máa ń lọ gbé níbòmíì.

3. Òmìnira lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú. Ọ̀tá ni ikú jẹ́ lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ìdí nìyẹn tí àwa èèyàn fi máa ń bẹ̀rù ikú tí a kò sì fẹ́ kú. Síbẹ̀, kò yẹ ká wá máa bẹ̀rù ikú ju bó ṣe yẹ lọ.

Bí òtítọ́ Bíbélì ṣe ń sọni dòmìnira: Yàtọ̀ sí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà, ó tún jẹ́ ka mọ̀ pé Ọlọ́run máa jí àwọn tó ti kú dìde. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [ìyẹn Kristi], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

Báwo ni wọ́n ṣe máa rí nígbà tí wọ́n bá “jáde wá”? Bí àwọn tí Jésù jí dìde ṣe rí jẹ́ ká mọ báwọn òkú ṣe máa rí nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Ní gbogbo ìgbà tí Jésù jí àwọn òkú dìde, wọn ò yí pa dà, irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ náà ni wọ́n pa dà jẹ́. (Máàkù 5:35-42; Lúùkù 7:11-17; Jòhánù 11:43, 44) Èyí bá ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àjíǹde” mu, èyí tó túmọ̀ sí “dídìde dúró.” Ọlọ́run sọ́ fún Dáníẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti darúgbó pé: “Ìwọ yóò sì sinmi [tàbí sùn nínú ikú], ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:13) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn á tu Dáníẹ́lì nínú gan-an ni, èyí tó mú kó má ṣe bẹ̀rù ikú, tí kò sì gbọ̀n jìnnìjìnnì!

Ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run ran Jésù ni pé kí ó “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè”—ìyẹn àwọn tó wà lábẹ́ ìgbèkùn ẹ̀kọ́ èké. (Lúùkù 4:18) Torí pé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ wà nínú Bíbélì, ojoojúmọ́ ni àwọn ẹ̀kọ́ yìí ń sọ àwọn èèyàn dòmìnira. Àdúrà wa ni pé kí òtítọ́ Bíbélì dá ọ sílẹ̀ lómìnira títí ayé.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Báwo ni òtítọ́ Bíbélì ṣe ń sọni dòmìnira lọ́wọ́

● ìgbàgbọ́ nínú ohun asán?—Aísáyà 8:19, 20; 65:11, 12.

● ìbẹ̀rù àwọn òkú?—Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11, 14.

● ìbẹ̀rù ikú?—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Òtítọ́ Bíbélì ń sọni dòmìnira lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ìbẹ̀rù òkú àti bíbẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá kú