OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́
Irú ara wo ni Ọlọ́run ní?
“Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.”—Jòhánú 4:24.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ ẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 3:17) Torí náà, a kò lè fi wé àwa èèyàn rárá, ó sì jù wá lọ fíìfíì. 1 Tímótì 1:17 pè é ní, “Ọba ayérayé, tí kò lè díbàjẹ́, tí a kò lè rí.” Bíbélì tún sọ pé, “Kò tíì sí ìgbà kan rí tí ẹnikẹ́ni rí Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 4:12.
Ẹlẹ́dàá wa jù wá lọ débi pé ó máa ṣòro gan-an fún wa láti fojú inú wo bó ṣe rí. Aísáyà 40:18 sọ pé: “Ta sì ni ẹ lè fi Ọlọ́run wé, ohun ìrí wo sì ni ẹ lè mú kí ó bá a dọ́gba?” Kódà, a ò lè fi Ọlọ́run Olódùmarè wé àgbàyanu ọ̀run tó tẹ́ lọ rẹrẹ.—Aísáyà 40:22, 26.
Àmọ́ àwọn ẹ̀dá onílàákàyè kan wà tó lè rí Ọlọ́run, tí wọ́n sì lè bá a sọ̀rọ̀ lójú kojú. Kí ló jẹ́ kí wọ́n lè rí Ọlọ́run? Torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí làwọn náà, ọ̀run ni wọ́n sì ń gbé. (1 Àwọn Ọba 22:21; Hébérù 1:7) Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ni Bíbélì pè ní áńgẹ́lì, wọ́n lágbára ju àwa èèyàn lọ. Jésù sọ nípa wọn pé wọ́n “ń wo ojú Baba [òun] tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 18:10.
Ṣé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà lóòótọ́?
“Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’”—Mátíù 6:9.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì kò sọ pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run máa ń wà nígbà gbogbo bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ kárí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú ìwé Mátíù 6:9 àti 18:10 Jésù pe Ọlọ́run ní “Baba,” ó sì sọ pé ọ̀run ló ń gbé. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, ọ̀run sì ni “ibùgbé” rẹ̀.”—1 Àwọn Ọba 8:43, Bíbélì Mímọ́.
Nígbà tí àkókò tí Jésù fẹ́ lò lórí ilẹ̀ ayé ń parí lọ, ó ní: “Mo ń fi ayé sílẹ̀, mo sì ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Jòhánù 16:28) Lẹ́yìn tí Kristi kú gẹ́gẹ́ bí èèyàn tó sì wá jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, ó lọ “sí ọ̀run, . . . láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀.—Hébérù 9:24.
Òtítọ́ ni àwọn ohun tá a sọ yìí jẹ́ nípa Ọlọ́run, ó sì ṣe pàtàkì ká mọ̀ wọ́n. Kí nìdí? Torí pé Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, a lè mọ̀ ọ́n, ká sì sún mọ́ ọn. (Jákọ́bù 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, òtítọ́ tá a bá kọ́ nípa Ọlọ́run lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké, irú bí ìjọsìn ère. 1 Jòhánù 5:21 sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”
Báwo ni àwa èèyàn ṣe jẹ́ àwòrán Ọlọ́run?
“Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwa èèyàn lè fìwà jọ Ọlọ́run, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, tí a kì í rẹ́ wọn jẹ, tá a sì ń fọgbọ́n hùwà. Kódà Bíbélì sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ́.”—Éfésù 5:1, 2.
Ọlọ́run kì í fipá mú wa ṣe ohunkóhun, ó fún wa lómìnira láti yan ohun rere dípò búburú, ó tún kọ́ wa bá a ṣe lè fi hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 13:4-7) Ó fún wa ní ọpọlọ tá a lè fi ṣe onírúurú nǹkan ká sì ronú lórí àwọn nǹkan mèremère tó wà láyìíká wa, ká sì tún mọyì wọn. Pabanbarì rẹ̀ ni pé, a tún máa ń fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run, a máa ń fẹ́ mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá wa àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ ọ̀la.—Mátíù 5:3.
Àǹfààní tí òtítọ́ inú Bíbélì máa ṣe fún ẹ. Bó o bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó, tó o sì ń fara wé e, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Wàá sì ní ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn, àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Aísáyà 48:17, 18) Ọlọ́run mọ̀ dájú pé inú àwa èèyàn dùn sí bí òun ṣe ń ṣe sí wa, èyí sì ń mú ká túbọ̀ máa sún mọ́ ọn, ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.—Jòhánù 6:44; 17:3.