Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Amẹ́ríkà

Lójoojúmọ́, iye tó ju ogun [20] lọ lára àwọn ajagunfẹ̀yìntì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń fọwọ́ ara wọn para wọn. Lóṣooṣù, nǹkan bí àádọ́ta dín lẹ́gbẹ̀rún [950] lára àwọn ajagunfẹ̀yìntì tó ń gbàtọ́jú ní ilé iṣẹ́ ìjọba tó ń bójú tó àwọn ológun ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn.

Ṣáìnà

Ìwé ìròyìn China Daily sọ pé, “Nǹkan bí ìdajì lára àwọn obìnrin tí kò tíì pé ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún tí wọ́n wáṣẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè Ṣáínà ni wọ́n máa ń lóyún kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Èyí sì ti mú kí iye àwọn obìnrin tó ń bímọ láìsí nílé ọkọ pọ̀ gan-an ju ti ìran tó ṣáájú wọn lọ.” Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé ohun míì tó tún wọ́pọ̀ gan-an nílẹ̀ Ṣáínà ni kí “ọkùnrin àti obìnrin máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó.”

Gíríìsì

Àìsàn ibà tó ti dàwátì lórílẹ̀-èdè Gíríìsì látọdún 1974 tún ti pa dà báyìí o. Ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ àti bí ìjọba ṣe dín owó tí wọ́n ń ná sórí ọ̀ràn ìlera kù ni wọ́n sọ pé ó fà á tí àìsàn ibà yìí tún fi pa dà.

Íńdíà

Ìwádìí kan fi hàn pé láìka ti ọ̀làjú tó ti wọ ilẹ̀ Íńdíà báyìí, ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn ọmọ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé àwọn fara mọ́ ọn pé kí wọ́n bá àwọn yan ẹni táwọn máa fẹ́ dípò káwọn fúnra àwọn yàn án. Bákan náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àwọn mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá tó sọ pé ó wu àwọn pé káwọn máa gbé pẹ̀lú àwọn ìbátan wọn ju pé káwọn àti ìdílé àwọn nìkan máa dá gbé lọ.

Ítálì

“Nǹkan ti wá tojú sú ṣọ́ọ̀ṣì [Kátólíìkì] báyìí láwọn ilẹ̀ tó ti gòkè àgbà dáadáa bíi Yúróòpù àti Amẹ́ríkà. Àwọn àṣà àtijọ́ là ń tẹ̀ lé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gìrìwò la kọ́ jọ, àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kò sí mọ́, ẹnu àwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì ò ká àwọn ọmọ ìjọ mọ́, àwọn ààtò ẹ̀sìn wa ò lóǹkà, àwọn aṣọ oyè wa sì rí gbàgẹ̀rẹ̀. . . . Ìlànà igba [200] ọdún sẹ́yìn tí kò bágbà mu mọ́ la ṣì ń tẹ̀ lé.”—Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àlùfáà àgbà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Carlo Maria Martini, èyí tí ìwé ìròyìn Corriere della Sera gbé jáde lẹ́yìn ikú àlùfáà náà.