Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

Amẹ́ríkà

Ìwádìí kan fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́ta ni kì í pọkàn pọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ sọdá títì. Ohun tó sì máa ń fà á ni pé wọ́n máa ń gbọ́ orin bí wọ́n ṣe ń sọdá, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù, àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ohun tó burú jù lọ tó lè fa àìpọkàn pọ̀ ni títẹ àtẹ̀jíṣẹ́ lójú títì. Ńṣe ni àwọn tó bá ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ máa ń wọ́sẹ̀ rìn lójú títì nígbà tó jẹ́ pé àwọn tó bá pọkàn pọ̀ máa ń sọdá kánmọ́kánmọ́. Bákan náà, àwọn tó ń tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ lójú títì kì í sábà kíyè sí àwọn iná tó ń darí ọkọ̀, wọ́n sábà máa ń sọdá níbi tí kò ti yẹ kí wọ́n sọdá, tàbí kí wọ́n sọdá títì láìwọ̀tún-wòsì.

Nàìjíríà

Àwọn tó máa ń kó àwọn obìnrin láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ ṣiṣẹ́ nílẹ̀ Yúróòpù máa ń fipá mú káwọn obìnrin náà mulẹ̀ pé àwọn ò ní tú àṣìrí fún ẹnikẹ́ni, ojúbọ òrìṣà ni wọ́n sì ti máa ń ṣe ìmùlẹ̀ náà. Wọ́n sì máa ń dẹ́rù bà wọ́n pé tí wọ́n bá fi tú àṣírí pé iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n ń fi wọ́n ṣe pẹ́rẹ́n, àwọn òòṣà máa fìyà jẹ wọ́n gidigidi.

Sípéènì

Àwọn kan tó pẹ́ tí wọ́n ti ń wáṣẹ́ kì í fi ìwé ẹ̀rí yunifásítì wọn àtàwọn ìwé ẹ̀rí míì tó fi hàn pé wọ́n kàwé dáadáa wáṣẹ́ mọ́. Ìdí tí wọ́n sì fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn tó fẹ́ gbà wọ́n síṣẹ́ lè máa wò ó pé ìwé tí wọ́n kà ti pọ̀ ju iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ gbà wọ́n fún lọ.

Kárí ayé

Èéfín tó máa ń jáde látinú àwọn ohùn èlò ìdáná bí àdògán ló ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn jù lọ láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ó tó mílíọ̀nù mẹ́rin èèyàn tó ń kú lọ́dọọdún látàrí àìsàn tí kì í jẹ́ kéeyàn lè mí dáadáa tí èéfín máa ń fà. Àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn èéfín olóró tó ń jáde látara àwọn igi ìdáná tàbí àwọn àdògán eléèédú léwu gan-an ni, kò sì yàtọ̀ sí èéfín olóró tó ń jáde látara sìgá.