Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Kíyè Sára Tó Bá Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì

Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Kíyè Sára Tó Bá Ń Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ohun tó ò ń gbọ́ nínú ìròyìn ni pé àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni, àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe àtàwọn olè pọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Èyí kò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ torí pé ọmọ rẹ sábà máa ń wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sì jọ pé kò mọ ewu tó wà níbẹ̀.

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ bó ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ kó má bàa kó sọ́wọ́ àwọn èèyànkéèyàn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àmọ́ o, ìwọ náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tó ń lọ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àwọn ọmọ lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì látorí fóònù wọn. Ó ṣì mọ́gbọ́n dání pé kí kọ̀ǹpútà máa wà níbi táwọn èèyàn á ti máa lọ bọ̀ nínú ilé. Àmọ́ láyé tí oríṣiríṣi fóònù ìgbàlódé tó lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti gbòde báyìí, ọmọ rẹ lè lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbàkigbà, o ò sì ní wà níbẹ̀ láti wo ohun tó ń ṣe.

Ǹjẹ́ a lè sọ pé kó dára kéèyàn máa wa ọkọ̀ torí pé àwọn kan ní jàǹbá ọkọ̀? Rárá. Bí ọ̀rọ̀ lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe rí náà nìyẹn. Ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọ́ bí ó ṣe lè máa kíyè sára tó bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì

Àwọn ọmọ kan máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọmọbìnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlógún kan sọ pé, “Mo kàn fẹ́ lo ìṣẹ́jú márùn-ún lórí kọ̀ǹpútà kí n lè ka ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ránṣẹ́ sí mi lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àmọ́ kí n tó mọ̀ mo ti lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí fídíò. Àfi kí n máa kó ara mi níjàánu gan-an.”

Àwọn ọmọ lè tú ọ̀rọ̀ ara wọn síta lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn èèyànkéèyàn lè ti ara ohun tí ọmọ kan kọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn fọ́tò tó gbé síbẹ̀ mọ àwọn ìsọfúnni kan nípa rẹ̀, irú bí, ibi tó ń gbé, iléèwé tó ń lọ àtàwọn ìgbà tí kì í sí ẹnì kankan nílé.

Àwọn ọmọ kan ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè kó bá wọn. Ohun tí èèyàn bá gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ṣeé pa rẹ́. Nígbà míì, àwọn èèyàn lè rí ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tó ń dójú tini tẹ́nì kan ti gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó sì lè jẹ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tó ń wá ìsọfúnni nípa ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ gbà síbi iṣẹ́ ló máa wá rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Òótọ́ ni pé àwọn ohun tá a jíròrò yìí fi hàn pé ewu wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àmọ́ fi sọ́kàn pé: Íńtánẹ́ẹ̀tì gangan kọ́ ni ìṣòro. Àmọ́ téèyàn ò bá fọgbọ́n lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó lè kóni sí ìṣòro.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Kọ́ ọmọ rẹ béèyàn ṣe ń mọ àwọn ohun àkọ́múṣe àti bó ṣe máa ṣètò àkókò rẹ̀. Ara ohun tí wọ́n fi ń mọ̀ pé ẹnì kan kì í ṣe ọmọdé mọ́ ni pé kó mọ àwọn ohun àkọ́múṣe. Àwọn nǹkan bí, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín ìdílé, iṣẹ́ àṣetiléwá àti iṣẹ́ ilé ṣe pàtàkì ju kéèyàn kan máa fàkókò ṣòfò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí ọmọ rẹ bá ti ń pẹ́ jù nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, sọ fún un pé ìgbà báyìí-báyìí lo fẹ́ kó máa kúrò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kódà o lè máa wo aago fún un tó bá pọn dandan bẹ́ẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 1:10.

Kọ́ ọmọ rẹ pé kó máa ronú jinlẹ̀ kó tó gbé ohunkóhun sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kọ́ ọmọ rẹ pé kó tó kọ ohunkóhun sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó kọ́kọ́ máa ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi, Ṣé ohun tí mo fẹ́ kọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí ò ní mú ẹnikẹ́ni bínú? Ṣé fọ́tò yìí ò ní jẹ́ káwọn èèyàn máa fojú burúkú wò mí? Ṣé ojú ò ní tì mí tí àwọn òbí mi tàbí àwọn àgbàlagbà míì bá rí fọ́tò tàbí ọ̀rọ̀ tí mo gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Irú èèyàn wo ni wọ́n máa gbà pé mo jẹ́ tí wọ́n bá rí ohun tí mo gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Irú ojú wo ni èmi á fi wo ẹni tó bá gbé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Ìlànà Bíbélì: Òwe 10:23.

Kọ́ ọmọ rẹ kó lè mọ ohun tó tọ́, dípò kó kàn máa tẹ̀ lé òfin. Kò sí bó o ṣe lè máa ṣọ́ ọmọ rẹ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Àti pé gẹ́gẹ́ bí òbí, ohun tó o fẹ́ ni pé kí àwọn ọmọ rẹ “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́,” kì í ṣe pé ó fẹ́ máa fipá mú wọn ṣe nǹkan. (Hébérù 5:14) Torí náà, dípò tí wàá fi máa tẹnu mọ́ àwọn òfin tó o gbé kalẹ̀ àti ìyà tó o máa fi jẹ ọmọ rẹ tó bá rú àwọn òfin náà, ńṣe ni kó o kúkú kọ́ ọmọ rẹ bó ṣe lè máa hùwà tó dáa. Irú èèyàn wo ló fẹ́ káwọn èèyàn mọ òun sí? Irú ìwà wo ló fẹ́ káwọn èèyàn fi mọ òun? Ohun tó o fẹ́ ni pé kí ọmọ rẹ lè dá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, yálà o wà níbẹ̀ tàbí o ò sí níbẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 3:21.

“Àwọn ọmọdé mọ púpọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ṣùgbọ́n àwọn òbí mọ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé”

Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá ń wa ọkọ̀ ó gba pé kéèyàn ní àròjinlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe rí, ó ju pé kéèyàn kan mọ bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé. Torí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí òbí máa tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà. Ọ̀gbẹ́ni Parry Aftab, tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn nípa ààbò lórí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Àwọn ọmọdé mọ púpọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ṣùgbọ́n àwọn òbí mọ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé.”