ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ April 2017

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti May 29 sí July 2, 2017 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“Ohun Tí O Jẹ́jẹ̀ẹ́, San Án”

Kí ló túmọ̀ sí tá a bá léèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́? Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Ọlọ́run?

Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?

Bíbélì sọ pé “ayé ń kọjá lọ.” Àmọ́ àwọn nǹkan wo ló wà nínú “ayé” tó “ń kọjá lọ” yìí?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́

Wọ́n ju Demetrius Psarras sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológún. Síbẹ̀ kò fi Ọlọ́run sílẹ̀ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kojú.

‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo? Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì fáwa Kristẹni lónìí?

Ṣé Èrò Tí Jèhófà Ní Nípa Ìdájọ́ Òdodo Ni Ìwọ Náà Ní?

Ó ṣe pàtàkì ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì máa dárí jini ká tó lè ní irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìdájọ́ òdodo. Kí nìdí?

Yọ̀ǹda Ara Rẹ Tinútinú, Kí Ìyìn Lè Jẹ́ ti Jèhófà!

Ọlọ́run mọyì bá a ṣe ń sapá láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ rẹ̀ bó ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ láìka bí ohun tá a ṣe ṣe kéré tó.