Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6

Jèhófà Baba Wa Ọ̀run Nífẹ̀ẹ́ Wa Gan-an

Jèhófà Baba Wa Ọ̀run Nífẹ̀ẹ́ Wa Gan-an

“Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.’”​—MÁT. 6:9.

ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè rí ọba Páṣíà bá sọ̀rọ̀?

JẸ́ KÁ sọ pé ilẹ̀ Páṣíà lò ń gbé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) ọdún sẹ́yìn. O fẹ́ bá kábíyèsí ìlú yín sọ ọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn, torí náà o forí lé Ṣúṣánì tó jẹ́ olú ìlú yín níbi tí ààfin ọba wà. Àmọ́ o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbàṣẹ kó o tó lè bá ọba sọ̀rọ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ikú lo fi ń ṣeré yẹn!​—Ẹ́sít. 4:11.

2. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ bá òun sọ̀rọ̀?

2 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ò dà bí ọba Páṣíà yẹn! Jèhófà ga fíìfíì ju ọba èyíkéyìí lọ, síbẹ̀ kò sígbà tá a fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ tí kì í ráyè fún wa. Kódà ó fẹ́ ká máa wá sọ́dọ̀ òun, ká sì máa bá òun sọ̀rọ̀ nígbàkigbà tá a bá fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá, òun ni Olódùmarè, ó sì tún jẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ, ó fẹ́ ká máa pe òun ní “Baba” tá a bá fẹ́ bá òun sọ̀rọ̀. (Mát. 6:9) Ẹ ò rí i pé ìyẹn tuni lára gan-an, ó sì múnú wa dùn pé ojú Baba ni Jèhófà fẹ́ ká fi máa wo òun!

3. Kí nìdí tá a fi lè pe Jèhófà ní “Baba,” kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ó tọ́, ó sì yẹ ká máa pe Jèhófà ní “Baba,” ó ṣe tán òun ló dá wa. (Sm. 36:9) Torí pé òun ni Baba wa, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i. Tá a bá ń ṣe ohun tó fẹ́, ó máa rọ̀jò ìbùkún lé wa lórí. (Héb. 12:9) Lára ìbùkún náà ni ìyè àìnípẹ̀kun yálà lórí ilẹ̀ ayé tàbí lókè ọ̀run. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan là ń gbádùn báyìí. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tí Jèhófà Baba wa ọ̀run ń ṣe fún wa báyìí tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Bákan náà, àá rí ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé kò ní pa wá tì lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti pé ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún.

JÈHÓFÀ BABA WA Ọ̀RUN NÍFẸ̀Ẹ́ WA GAN-AN, Ọ̀RỌ̀ WA SÌ JẸ Ẹ́ LÓGÚN

Jèhófà máa ń sún mọ́ wa bí bàbá kan ṣe máa ń sún mọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn kan láti ka Jèhófà sí Baba wọn?

4 Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti ka Jèhófà sí Baba rẹ? Àwọn kan máa ń ronú pé kí làwọn já mọ́ níwájú Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, kódà àwọn ò ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́ lọ ní ìfiwéra. Wọ́n gbà pé tí Ọlọ́run Olódùmarè bá tiẹ̀ máa ráyè fún gbogbo èèyàn, kì í ṣe bíi tàwọn. Àmọ́, Baba wa ọ̀run ò fẹ́ ká ronú bẹ́ẹ̀. Òun ló dá wa, ó sì fẹ́ ká sún mọ́ òun. Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé kókó yìí fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ nílùú Áténì, ó fi kún un pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:24-29) Jèhófà fẹ́ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa máa wá sọ́dọ̀ òun láìbẹ̀rù bí ọmọ kan ṣe máa ń ṣe sí òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

5. Kí la rí kọ́ látinú ìrírí arábìnrin kan?

5 Ó ṣòro fáwọn míì láti ka Jèhófà sí Baba torí pé bàbá tó bí wọn lọ́mọ kò rí tiwọn rò ká má tíì sọ pé kó fìfẹ́ hàn sí wọn. Ẹ gbọ́ ohun tí arábìnrin kan sọ. Ó ní: “Bàbá mi máa ń bú mi gan-an, wọ́n sì máa ń ṣépè fún mi. Torí náà, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣòro fún mi láti gbà pé Jèhófà jẹ́ Bàbá mi ọ̀run. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo mọ Jèhófà, èrò mi yí pa dà pátápátá.” Ṣé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìwọ náà lè mọ Jèhófà débi tí wàá fi gbà pé kò sí bàbá tó dà bíi Jèhófà.

6. Bó ṣe wà nínú Mátíù 11:27, sọ ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà mú ká rí i pé Baba wa lòun àti pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

6 Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà mú ká rí i pé òun jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ ni bó ṣe mú kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù sílẹ̀ nínú Bíbélì. (Ka Mátíù 11:27.) Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ débi tó fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba.” (Jòh. 14:9) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù sọ àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe tó fi hàn pé Baba wa ni lóòótọ́. Nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nìkan, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìgbà tí Jésù pe Jèhófà ní “Baba.” Kí nìdí? Ìdí kan ni pé ó fẹ́ kó dá àwa èèyàn lójú pé Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni Jèhófà.​—Jòh. 17:25, 26.

7. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà nínú bó ṣe bá Ọmọ rẹ̀ lò?

7 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ nípa Jèhófà nínú bó ṣe bá Jésù Ọmọ rẹ̀ lò. Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà Jésù. Kì í ṣe pé ó ń tẹ́tí sí i nìkan, ó tún máa ń dáhùn àdúrà rẹ̀. (Jòh. 11:41, 42) Bákan náà, kò sígbà tí Jésù kojú àdánwò tí kì í rọ́wọ́ Jèhófà, ó sì máa ń rí i pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ òun.​—Lúùkù 22:42, 43.

8. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà pèsè fún Jésù?

8 Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ni Orísun ìyè, òun náà ló sì ń pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún òun nígbà tó sọ pé mo “wà láàyè nítorí Baba.” (Jòh. 6:57) Jésù gbẹ́kẹ̀ lé Baba rẹ̀ pátápátá, Jèhófà náà kò sì já a kulẹ̀ ní ti pé ó pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún un. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà ṣe fún Jésù ni pé ó mú kó lè jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀.​—Mát. 4:4.

9. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe fún Jésù tó fi hàn pé Baba onífẹ̀ẹ́ lòun?

9 Torí pé Baba tó nífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó mú kó dá Jésù lójú pé òun wà lẹ́yìn rẹ̀. (Mát. 26:53; Jòh. 8:16) Òótọ́ ni pé Jèhófà fàyè gba pé kí wọ́n fìyà jẹ Jésù, síbẹ̀ ó ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á. Jésù mọ̀ pé ìṣòro yòówù kó dé bá òun, fúngbà díẹ̀ ni. (Héb. 12:2) Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù ní ti pé ó tẹ́tí sí i, ó pèsè ohun tó nílò, ó dá a lẹ́kọ̀ọ́, ó sì tì í lẹ́yìn. (Jòh. 5:20; 8:28) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Baba wa ọ̀run ṣe ń bójú tó àwa náà.

BÍ JÈHÓFÀ BABA WA Ọ̀RUN ṢE Ń FÌFẸ́ BÓJÚ TÓ WA

Bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń (1) tẹ́tí sí wọn, (2) pèsè fún wọn, (3) dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń (4) dáàbò bò wọ́n. Bí Baba wa ọ̀run náà ṣe ń bójú tó wa nìyẹn (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 15) *

10. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 66:19, 20, báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa?

10 Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa. (Ka Sáàmù 66:19, 20.) Kò fẹ́ ká ronú pé ṣe là ń yọ òun lẹ́nu bá a ṣe ń gbàdúrà, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀ fàlàlà. (1 Tẹs. 5:17) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ibi yòówù ká wà, kò sígbà tá a yíjú sí Baba wa ọ̀run tí kò ráyè tiwa. Ọwọ́ rẹ̀ kò dí jù láti tẹ́tí sí wa, ìgbà gbogbo ló ṣeé bá sọ̀rọ̀, ó sì ṣe tán láti gbọ́ wa. Tá a bá mọ̀ pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ wa máa dà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí ó ń gbọ́ ohùn mi.”​—Sm. 116:1.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà wa?

11 Kì í ṣe pé Baba wa ọ̀run ń gbọ́ àdúrà wa nìkan, ó tún máa ń dáhùn wọn. Àpọ́sítélì Jòhánù fi dá wa lójú pé: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.” (1 Jòh. 5:​14, 15) Àmọ́ o, Jèhófà lè má dáhùn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́. Ìdí sì ni pé ó mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù, torí náà ó lè má fún wa lóhun tá a fẹ́ gan-an, ó sì lè gba pé ká mú sùúrù dìgbà tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀.​—⁠2 Kọ́r. 12:​7-9.

12-13. Àwọn nǹkan wo ni Baba wa ọ̀run ń pèsè fún wa?

12 Jèhófà ń pèsè ohun tá a nílò. Gbogbo ohun tó yẹ kí Baba ṣe ni Jèhófà ń ṣe. (1 Tím. 5:8) Ó ń fún àwa ọmọ rẹ̀ láwọn nǹkan tó ń gbé ẹ̀mí wa ró. Kò fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa oúnjẹ, aṣọ tàbí ilé tá a máa gbé. (Mát. 6:32, 33; 7:11) Torí pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ti ṣètò gbogbo ohun tó máa mú kí ọjọ́ ọ̀la wa ládùn kó sì lóyin.

13 Pabanbarì ẹ̀ ni pé Jèhófà ń fún wa lóhun tá a nílò nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká mọ irú ẹni tóun jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé, ìdí tó fi dá wa sáyé àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bó ṣe jẹ́ ká rí òtítọ́, yálà nípasẹ̀ àwọn òbí wa tàbí nípasẹ̀ Ẹlẹ́rìí tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Títí di bá a ṣe ń sọ yìí, ó ń lo àwọn alàgbà àtàwọn míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin láti máa ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Bákan náà, Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìpàdé ìjọ, a sì tún ń gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa. Àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì fi hàn pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.​—Sm. 32:8.

14. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́, báwo ló sì ṣe ń ṣe é?

14 Jèhófà ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Àwa ò dà bíi Jésù torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, ká lè kẹ́kọ̀ọ́ Baba wa ọ̀run máa ń bá wa wí nígbà tó bá yẹ. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí.” (Héb. 12:6, 7) Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń bá wa wí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ ohun kan tá a kà nínú Bíbélì tàbí tá a gbọ́ nípàdé ló máa jẹ́ ká ríbi tá a kù sí. Ó sì lè lo àwọn alàgbà láti tọ́ wa sọ́nà. Ọ̀nà yòówù kó jẹ́, ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa ló mú kó máa bá wa wí.​—Jer. 30:11.

15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá?

15 Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Bí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe máa ń dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Baba wa ọ̀run ṣe máa ń wà pẹ̀lú wa nígbà ìṣòro. Ó máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dáàbò bò wá kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú òun jẹ́. (Lúùkù 11:13) Jèhófà tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, ó jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la máa dáa. Ìrètí yìí ń mú ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa. Ohun kan tó dájú ni pé ohun yòówù kí ìṣòro tá a ní ti fà fún wa, Jèhófà máa mú gbogbo ẹ̀ kúrò. Torí náà, bó ti wù kí ìṣòro wa lágbára tó, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé fúngbà díẹ̀ ni torí pé títí ayé ni Jèhófà á máa rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ lé wa lórí.​—2 Kọ́r. 4:16-18.

BABA WA Ò NÍ PA WÁ TÌ LÁÉ

16. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run?

16 Ohun tí Jèhófà ṣe lẹ́yìn tí Ádámù ṣàìgbọràn tún fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́. Nígbà tí Ádámù ṣàìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run, kò sí lára ìdílé Jèhófà mọ́, bó sì ṣe rí fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ náà nìyẹn. (Róòmù 5:12; 7:14) Síbẹ̀, Jèhófà ò pa wá tì, ó tún ràn wá lọ́wọ́.

17. Kí ni Jèhófà ṣe kété lẹ́yìn tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀?

17 Jèhófà fìyà tó tọ́ jẹ Ádámù, àmọ́ ó ṣèlérí pé òun máa dá àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ nídè. Kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà ni Jèhófà ṣèlérí pé àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lára ọmọ Ádámù máa pa dà sínú ìdílé òun. (Jẹ́n. 3:15; Róòmù 8:20, 21) Jèhófà mú kíyẹn ṣeé ṣe lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Bí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ kú fún wa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.​—Jòh. 3:16.

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ti fi ètò Jèhófà sílẹ̀ àmọ́ tó o ronú pìwà dà, Jèhófà Baba wa ọ̀run máa gbà ẹ́ pa dà (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà fẹ́ ká wà lára ìdílé òun tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe?

18 Bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ ara ìdílé òun, kò sì ní sọ láé pé ọ̀rọ̀ wa ti sú òun. Òótọ́ ni pé a máa ń ṣẹ Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe ká ti fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ tàbí ká dẹwọ́ nínú ìjọsìn rẹ̀ fúngbà díẹ̀, síbẹ̀ Jèhófà ò gbà pé ọ̀rọ̀ wa ti kọjá àtúnṣe. Jésù ṣe àkàwé kan nípa ọmọ onínàákúnàá ká lè mọ bí ìfẹ́ tí Baba wa ọ̀run ní fún wa ṣe jinlẹ̀ tó. (Lúùkù 15:11-32) Bàbá inú àkàwé yẹn gbà pé ọmọ òun ṣì máa pa dà wálé lọ́jọ́ kan. Lọ́jọ́ tí ọmọ náà pa dà, tayọ̀tayọ̀ ni bàbá rẹ̀ fi gbà á. Torí náà, tó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé o ṣi ẹsẹ̀ gbé àmọ́ tó o ronú pìwà dà tọkàntọkàn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Baba rẹ ọ̀run ṣe tán láti gbà ẹ́ pa dà.

19. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣàtúnṣe ohun tí Ádámù bà jẹ́?

19 Baba wa ọ̀run máa ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí Ádámù bà jẹ́. Lẹ́yìn tí Ádámù ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà pinnu pé òun máa gba àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) lára aráyé ṣọmọ, wọ́n á sì di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù lọ́run. Nínú ayé tuntun, Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí máa ran àwọn tó jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ láti di pípé. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti pegedé nínú àdánwò ìkẹyìn, Jèhófà máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ wo bí inú Baba wa ọ̀run ṣe máa dùn tó nígbà tí ayé yìí bá kún fún àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n ti di pípé! Ó dájú pé àsìkò yẹn máa lárinrin gan-an!

20. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Baba tó ju baba lọ ni. Ó máa ń gbọ́ àdúrà wa, ó sì ń pèsè ohun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ó máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń tì wá lẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ṣètò ọjọ́ iwájú aláyọ̀ fún wa. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an! Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò bí àwa ọmọ rẹ̀ náà ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀.

ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

^ ìpínrọ̀ 5 A sábà máa ń pe Jèhófà ní Ẹlẹ́dàá wa àti Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Bó ṣe rí nìyẹn lóòótọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká gbà pé ó jẹ́ Baba wa àti pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. A tún máa rí ẹ̀rí táá mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé.

^ ìpínrọ̀ 59 ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí jẹ́ ká rí bí àwọn bàbá kan ṣe ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn: bàbá kan ń tẹ́tí sí ọmọ rẹ̀, bàbá kan pèsè ohun tí ọmọbìnrin rẹ̀ máa jẹ, bàbá kan ń dá ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, bàbá kan sì ń tu ọmọ rẹ̀ nínú. Àwòrán ọwọ́ Jèhófà tó wà lẹ́yìn wọn jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń pèsè fún wa ní gbogbo ọ̀nà.