Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ni ìwádìí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa Bẹliṣásárì?
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn tó ń ta ko Bíbélì ti ń sọ pé kò sẹ́ni tó ń jẹ́ Ọba Bẹliṣásárì tí ìwé Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Dán. 5:1) Ohun tó jẹ́ kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀ ni pé orúkọ yẹn ò fara hàn nínú àwọn ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí. Àmọ́ òótọ́ fara hàn kedere lọ́dún 1854. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Lọ́dún yẹn, aṣojú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ J. G. Taylor ṣàyẹ̀wò àwọn àwókù kan nílùú Úrì, ìyẹn ìlú ìgbàanì kan tó wà ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Iraq báyìí. Ó ṣàwárí àwọn ìkòkò amọ̀ ribiti mélòó kan nínú ilé gogoro kan. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìkòkò náà gùn tó ínǹṣì mẹ́rin (10 cm), wọ́n sì fín àwọn ọ̀rọ̀ kan sára wọn. Lára ohun tí wọ́n fín sára ọ̀kan lára wọn ni àdúrà tí wọ́n gbà pé kí ẹ̀mí Ọba Nábónídọ́sì àti ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà tó ń jẹ́ Bẹliṣásárì gùn. Ńṣe lẹnu àwọn alátakò wọhò, wọ́n sì gbà láìjanpata pé Bẹliṣásárì gbáyé lóòótọ́.
Àmọ́ Bíbélì ò kàn sọ pé Bẹliṣásárì gbáyé nìkan, ó tún sọ pé ọba ni. Síbẹ̀, àwọn alátakò sọ pé irọ́ ni. Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ William Talbot sọ pé: “Àwọn kan mà tún sọ pé Bel-sar-ussur [Bẹliṣásárì] jọba lásìkò tí Nábónídọ́sì bàbá rẹ̀ wà lórí oyè. Àmọ́ kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá.”
Ọ̀rọ̀ yìí yanjú nígbà tí wọ́n ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fín sára àwọn ìkòkò yòókù. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí i pé ìgbà kan wà tí Ọba Nábónídọ́sì tó jẹ́ bàbá Bẹliṣásárì kò sí nílé fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ètò wo ló ṣe nígbà tí kò sí nílé? Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé “Nígbà tí Nábónídọ́sì kò sí nílé, ó fi Bẹliṣásárì ṣe adelé rẹ̀, ó sì ní kó máa bójú tó àwọn tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Ó ṣe kedere nígbà náà pé Bẹliṣásárì jọba ní Bábílónì lásìkò kan náà pẹ̀lú bàbá rẹ̀. Abájọ tí Alan Millard tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn tó sì tún jẹ́ ìjìmì nínú àwọn èdè àtijọ́ fi sọ pé òótọ́ lohun tí ìwé Dáníẹ́lì sọ pé “Bẹliṣásárì jẹ́ ‘ọba.’”
Àmọ́ o, ohun tí Bíbélì fúnra ẹ̀ sọ ló jẹ́ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà pé Ọlọ́run mí sí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì, ó sì ṣeé gbára lé.—2 Tím. 3:16.