Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹyẹ oriri àti ẹyẹlé rúbọ?
LÁBẸ́ Òfin Mósè, Jèhófà gbà pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹyẹ oriri àti ẹyẹlé rúbọ. Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ, ó sábà máa ń mẹ́nu kan àwọn ẹyẹ méjèèjì yìí pa pọ̀, wọ́n sì lè fi ọ̀kan rọ́pò èkejì. (Léf. 1:14; 12:8; 14:30) Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà pé wọ́n lè fi wọ́n rọ́pò ara wọn? Ìdí kan ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rí ẹyẹ oriri lò. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Àwọn ẹyẹ oriri máa ń ṣí kúrò láti ibì kan síbòmíì, àmọ́ wọ́n máa ń wà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láwọn oṣù tí oru bá ń mú. Tó bá di oṣù October, wọ́n máa ń ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó móoru, ibẹ̀ ni wọ́n á wà kí wọ́n tó pa dà sórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní oṣù April. (Orin Sól. 2:11, 12; Jer. 8:7) Èyí fi hàn pé ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ó máa ń ṣòro fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti rí ẹyẹ oriri tí wọ́n á fi rúbọ nígbà òtútù.
Àmọ́ àwọn ẹyẹlé ní tiwọn kì í ṣí kiri. Torí náà, kò sígbà tí wọn kì í sí lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jálẹ̀ ọdún. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn máa ń sin ẹyẹlé. (Fi wé Jòhánù 2:14, 16.) * Ìwé Bible Plants and Animals sọ pé: “Gbogbo abúlé àti ìlú tó wà ní Palẹ́sínì ni wọ́n ti ń sin ẹyẹlé. Gbogbo èèyàn ló ní ilé ẹyẹ nílé tàbí ihò kan lára ògiri tí ẹyẹlé máa ń gbé.”
Torí náà, bí Jèhófà ṣe gbà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹyẹ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn rúbọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, ó sì ń gba tiwọn rò.
^ ìpínrọ̀ 5 Àdàbà tí Jòhánù 2:14, 16 mẹ́nu kàn tún lè jẹ́ ẹyẹlé.