Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mọyì Òmìnira Tó O Ní

Mọyì Òmìnira Tó O Ní

‘Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.’2 KỌ́R. 3:17.

ORIN: 62, 65

1, 2. (a) Èrò wo làwọn èèyàn ní nípa òmìnira? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa òmìnira tá a ní, àwọn ìbéèrè wo la sì máa jíròrò?

OBÌNRIN kan fẹ́ kí ọ̀rẹ́ òun gba òun nímọ̀ràn nípa ìpinnu kan tó fẹ́ ṣe, ó wá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Má wulẹ̀ jẹ́ kí n da ọpọlọ mi láàmú, ohun tí màá ṣe ni kó o sọ fún mi. Ohun tó pé mi nìyẹn.” Lédè míì, obìnrin yẹn gbà pé á dáa kí wọ́n sọ ohun tí òun máa ṣe dípò kó lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn òmìnira. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ìwọ lo máa ń pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe àbí o máa ń fẹ́ káwọn míì ṣèpinnu fún ẹ? Kí ló túmọ̀ sí pé a ní òmìnira?

2 Ọjọ́ pẹ́ tẹ́nu àwọn èèyàn ò ti kò lórí ọ̀rọ̀ pé èèyàn ní òmìnira. Àwọn kan sọ pé àwa èèyàn ò lómìnira èyíkéyìí torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tá a máa ṣe láyé. Àwọn míì sì sọ pé káwọn tó lè gbà pé a ní òmìnira ó dìgbà táwa èèyàn bá lè ṣe ohun tó wù wá láìsí pé ẹnì kan ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, tá a bá máa lóye ọ̀rọ̀ náà, á dáa ká wo ohun tí Bíbélì sọ. Bíbélì ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló dá wa tó sì fún wa lómìnira ká lè fara balẹ̀ yan ohun tá a fẹ́ ṣe. (Ka Jóṣúà 24:15.) Bíbélì tún dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Báwo ló ṣe yẹ ká máa lo òmìnira tá a ní yìí? Ṣé òótọ́ ni pé ohun tó wù wá la lè ṣe láìsí pé ẹnì kan ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò? Báwo la ṣe lè lo òmìnira wa lọ́nà táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Báwo la ṣe lè fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣèpinnu?

OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁRA JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ

3. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun kì í ṣi agbára òun lò?

3 Jèhófà nìkan ló lè ṣe ohunkóhun tó wù ú láìsí ẹnikẹ́ni tó máa yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò, síbẹ̀ kò ṣi agbára yẹn lò. Bí àpẹẹrẹ, ó pinnu láti yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó pè wọ́n ní èèyàn rẹ̀, “àkànṣe dúkìá.” (Diu. 7:6-8) Jèhófà kò kàn ṣàdédé yàn wọ́n. Ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn ló mú ṣẹ. (Jẹ́n. 22:15-18) Bákan náà, Jèhófà máa ń lo ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo nígbà tó bá ń pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí torí pé léraléra ni wọ́n pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Àmọ́ tí wọ́n bá ronú pìwà dà, Jèhófà máa ń fínnú fíndọ̀ dárí jì wọ́n torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó sọ pé: “Èmi yóò wo àìṣòótọ́ wọn sàn. Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi.” (Hós. 14:4) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà nìyẹn tó bá di pé ká lo òmìnira tá a ní lọ́nà tó máa ṣe àwọn míì láǹfààní!

4, 5. (a) Ta lẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ fún lẹ́bùn òmìnira, báwo ló sì ṣe lò ó? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

4 Nígbà tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan láyé àti lọ́run, ó dìídì fún àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn ní òmìnira torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ẹni tó kọ́kọ́ fún lẹ́bùn òmìnira yìí ni àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, tí Bíbélì pè ní “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (Kól. 1:15) Kí Jésù tó wá sáyé, ó yàn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà dípò táá fi lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Sátánì ọlọ̀tẹ̀. Nígbà tó sì wá sáyé, Sátánì dẹ ẹ́ wò, àmọ́ ó pinnu pé ìfẹ́ Ọlọ́run lòun máa ṣe. (Mát. 4:10) Kódà lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, àdúrà tó gbà fi hàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ló wà lọ́kàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká máa lo òmìnira wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu. Àmọ́, ṣé ìyẹn ṣeé ṣe?

5 Ó ṣeé ṣe ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù torí pé àwòrán Ọlọ́run làwa náà. (Jẹ́n. 1:26) Àmọ́, ó níbi tí òmìnira wa mọ, a ò lè máa ṣe bó ṣe wù wá láìsí ẹni tó ń yẹ̀ wá lọ́wọ́ wò. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run fún wa láwọn òfin àti ìlànà tá a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aya gbọ́dọ̀ fara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ wọn, kí àwọn ọmọ sì máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn. (Éfé. 5:22; 6:1) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àwọn òfin àti ìlànà yẹn máa darí wa tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu? Ó ṣe pàtàkì ká wá ìdáhùn sí ìbéèrè yìí torí pé bá a bá ṣe lo òmìnira wa ló máa pinnu bóyá a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun.

BÉÈYÀN ṢE LÈ LO ÒMÌNIRA LỌ́NÀ TÓ TỌ́ ÀTI LỌ́NÀ TÍ KÒ TỌ́

6. Ṣàpèjúwe ìdí tó fi dáa ká láwọn òfin àti ìlànà tá à ń tẹ̀ lé.

6 Tó bá jẹ́ pé àwọn òfin àti ìlànà wà tá a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé, ṣé a lè sọ pé a ní òmìnira lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, a lómìnira! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tá a bá láwọn ìlànà tó ń tọ́ wa sọ́nà, ó máa dáàbò bò wá. Bí àpẹẹrẹ, a lè pinnu pé a fẹ́ wọkọ̀ lọ sílùú kan tó jìnnà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé kò sí òfin ìrìnnà lójú ọ̀nà tá a fẹ́ gbà, táwọn èèyàn ń wa mọ́tò níwàkuwà, tí wọ́n sì ń sá eré àsápajúdé, ṣé ọkàn wa máa balẹ̀? Ó dájú pé ọkàn wa ò ní balẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká láwọn òfin àti ìlànà táá máa darí wa tí gbogbo wa bá máa gbádùn òmìnira tá a ní. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì táá jẹ́ ká rí bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó pé ká máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tá a bá ń ṣèpinnu.

7. (a) Báwo ni òmìnira tí Ádámù ní láti pinnu ohun tó wù ú ṣe mú kó yàtọ̀ sáwọn ẹranko inú ọgbà Édẹ́nì? (b) Sọ àpẹẹrẹ bí Ádámù ṣe lo òmìnira tí Ọlọ́run fún un.

7 Nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, ó fún òun náà lómìnira bó ṣe fún àwọn áńgẹ́lì. Òmìnira tí Ádámù ní láti pinnu ohun tó wù ú yìí ló mú kó yàtọ̀ sáwọn ẹranko, torí pé àwọn ẹranko kì í ronú. A rí àpẹẹrẹ bí Ádámù ṣe lo òmìnira yìí lọ́nà tó tọ́ nígbà tí Ọlọ́run gbéṣẹ́ ńlá kan fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko ṣáájú Ádámù, òun ni Ọlọ́run sọ fún pé kó sọ àwọn ẹranko náà lórúkọ. Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run “bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà láti wo ohun tí yóò pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.” Lẹ́yìn tí Ádámù ti fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ẹranko náà tó sì fún wọn lórúkọ, Jèhófà ò kọminú sí orúkọ tó sọ àwọn ẹranko náà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yí i pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ èyíkéyìí tí ọkùnrin náà bá pe ẹranko kọ̀ọ̀kan, ìyẹn ni orúkọ rẹ̀.Jẹ́n. 2:19.

8. Báwo ni Ádámù ṣe ṣi òmìnira tó ní lò, kí ló sì yọrí sí?

8 Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù ò mọyì iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un pé kó máa ro ọgbà náà, kó sì máa tọ́jú rẹ̀. Jèhófà fún Ádámù ní òmìnira tó pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún un pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja . . . , àwọn ẹ̀dá tí ń fò . . . , àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́n. 1:28) Àmọ́ dípò tí Ádámù á fi mọrírì òmìnira náà, ńṣe ló fayọ̀ fọ́ ọ. Ó kọjá àyè rẹ̀ torí pé ó jẹ èso tí Ọlọ́run ní kó má jẹ. Òmìnira tí Ádámù ṣì lò yìí ló fà á táwa èèyàn fi ń jìyà látọdún yìí wá. (Róòmù 5:12) Ìkìlọ̀ gidi lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù yìí jẹ́ fún wa, pé ká má ṣi òmìnira wa lò, ká sì rí i pé à ń tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run.

9. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí làwọn èèyàn náà sì ṣe?

9 Àìgbọràn Ádámù àti Éfà ló mú káwọn àtọmọdọ́mọ wọn jogún àìpé àti ikú. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. A rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí nínú bí Jèhófà ṣe bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Jèhófà gbẹnu Mósè sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n yàn bóyá àwọn á jẹ́ àkànṣe dúkìá òun tàbí wọn ò ní fẹ́ bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kís. 19:3-6) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe? Wọ́n gbà láti ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà béèrè kí wọ́n lè di èèyàn rẹ̀, torí náà wọ́n panu pọ̀ sọ pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 19:8) Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣi òmìnira wọn lò, wọn ò sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Ìkìlọ̀ ni àpẹẹrẹ wọn yìí jẹ́ fún wa pé ká mọyì òmìnira tá a ní, ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.1 Kọ́r. 10:11.

10. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká rí i pé àwa èèyàn aláìpé lè lo òmìnira wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Ìwé Hébérù orí 11 mẹ́nu kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mẹ́rìndínlógún [16] tí wọ́n lo òmìnira wọn lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Èyí mú kí wọ́n rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà, kí wọ́n sì nírètí àtiwà láàyè lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, Nóà fi hàn pé òun nígbàgbọ́ torí pé ó yàn láti tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run pé kó kan ọkọ̀ áàkì. Ọkọ̀ áàkì yìí ló gba ẹ̀mí ìdílé rẹ̀ là tí kò sì jẹ́ kí ìran aráyé pa run. (Héb. 11:7) Ábúráhámù àti Sárà náà yàn láti jẹ́ kí Ọlọ́run darí wọn lọ sí ilẹ̀ ìlérí. Kódà nígbà tí wọ́n ń rìnrìn-àjò yìí, ‘àyè ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà’ sí ìlú Úrì tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Àmọ́ dípò kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹjú mọ́ “ìmúṣẹ àwọn ìlérí” Ọlọ́run, wọ́n sì ń fojú sọ́nà fún “ibi tí ó sàn jù.” (Héb. 11:8, 13, 15, 16) Mósè náà kọ gbogbo ìṣura Íjíbítì sílẹ̀, “ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Héb. 11:24-26) Ó yẹ káwa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ yìí, ká máa lo òmìnira wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

11. (a) Ìbùkún wo la máa rí tá a bá yàn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà? (b) Kí nìdí tá a fi fẹ́ lo òmìnira wa lọ́nà tó tọ́?

11 Lóòótọ́ ó lè rọ̀ wá lọ́rùn tí ẹlòmíì bá ṣèpinnu fún wa, àmọ́ ìyẹn ò ní jẹ́ ká rí ìbùkún téèyàn máa ń ní téèyàn bá fúnra rẹ̀ ṣèpinnu. Diutarónómì 30:19, 20 jẹ́ ká mọ ìbùkún téèyàn máa rí. (Kà á.) Ní ẹsẹ 19, Ọlọ́run ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yan ohun tí wọ́n máa ṣe. Ní ẹsẹ 20, Jèhófà fún wọn láǹfààní láti fi ohun tó wà lọ́kàn wọn hàn. Àwa náà lè yàn láti jọ́sìn Jèhófà. Ìdí pàtàkì tá a fi fẹ́ máa lo òmìnira wa lọ́nà tó tọ́ ni pé a fẹ́ fògo fún Jèhófà, a sì fẹ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

MÁ ṢE ṢI ÒMÌNIRA RẸ LÒ

12. Kí ni kò yẹ ká ṣe sí òmìnira tí Jèhófà fún wa?

12 Ká sọ pé o fún ọ̀rẹ́ rẹ lẹ́bùn kan, ó wá ju ẹ̀bùn náà sí ààtàn tàbí ó ń fi ẹ̀bùn náà pa àwọn míì lára. Tó o bá gbọ́, ṣé inú rẹ máa dùn? Wá wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí i táwọn èèyàn ń ṣi òmìnira wọn lò tí wọ́n sì tún fi ń pa àwọn míì lára. Bí Bíbélì ṣe sọ náà ló rí, pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “aláìlọ́pẹ́.” (2 Tím. 3:1, 2) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò ṣi òmìnira tá a ní yìí lò. Àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní ṣì í lò?

13. Kí ló yẹ ká pinnu tá ò bá fẹ́ ṣi òmìnira wa lò?

13 Gbogbo wa la lómìnira láti yan ẹni tá a máa bá ṣọ̀rẹ́, irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti irú eré ìnàjú tá a máa ṣe. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, a lè sọ òmìnira yìí di “bojúbojú fún ìwà búburú.” Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ wa lọ́rùn la máa ń ṣe tàbí tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àwọn èèyàn ayé. (Ka 1 Pétérù 2:16.) Dípò tá a fi máa lo òmìnira wa láti ṣe ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ wa lọ́rùn, á dáa ká pinnu pé àá “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” Gál. 5:13; 1 Kọ́r. 10:31.

14. Tá ò bá fẹ́ ṣi òmìnira wa lò, kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

14 Ohun míì tá a lè ṣe tá ò fi ní ṣi òmìnira wa lò ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì jẹ́ kí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ máa tọ́ wa sọ́nà. Jèhófà nìkan ni ‘Ẹni tí ń kọ́ wa kí a lè ṣe ara wa láǹfààní, Ẹni tí ń mú ká tọ ọ̀nà tí ó yẹ ká máa rìn.’ (Aísá. 48:17) A gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jer. 10:23) Kò yẹ ká máa gbára lé òye tara wa bíi ti Ádámù àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ya ọlọ̀tẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká “fi gbogbo ọkàn-àyà [wa] gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”Òwe 3:5.

MÁA FỌ̀WỌ̀ WỌ ÀWỌN MÍÌ NÍGBÀ TÍ WỌ́N BÁ ṢÈPINNU

15. Báwo la ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:5 sílò?

15 Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ó níbi tí òmìnira wa mọ, a ò sì lè ṣèpinnu fáwọn míì. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní òmìnira, ìpinnu tí kálukú máa ṣe sì lè yàtọ̀ síra nígbà míì. Kódà, ọ̀rọ̀ yìí kan ìwà wa àti ìjọsìn wa. Ẹ jẹ́ ká rántí ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:5. (Kà á.) Tá a bá gbà pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa “ru ẹrù ti ara rẹ̀,” àá máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu.

Tá a bá pinnu láti ṣe ohun kan, kò yẹ ká fipá mú àwọn míì láti ṣe ohun kan náà (Wo ìpínrọ̀ 15)

16, 17. (a) Kí ló fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ará ní Kọ́ríńtì? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe yanjú ọ̀rọ̀ náà, kí la sì rí kọ́?

16 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa fọ̀wọ̀ àwọn míì wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu, pàápàá tí ìpinnu yẹn bá jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn. Nílùú Kọ́ríńtì, àwọn kan máa ń ta ẹran tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi rúbọ sí òrìṣà. Àwọn Kristẹni kan ronú pé: ‘Nígbà tó jẹ́ pé àwọn òrìṣà ò já mọ́ nǹkan kan, ẹ̀rí ọkàn àwọn gbé e láti jẹ àwọn ẹran náà.’ Àmọ́ àwọn Kristẹni míì tí wọ́n bọ àwọn òrìṣà yẹn nígbà kan rí gbà pé jíjẹ irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ dà bí ìgbà téèyàn ń jọ́sìn àwọn òrìṣà náà. Ọ̀rọ̀ yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni tó wà níjọ Kọ́ríńtì. (1 Kọ́r. 8:4, 7) Ọ̀rọ̀ tó gbẹgẹ́ gan-an lọ̀rọ̀ yìí, tí wọn ò bá sì tètè yanjú rẹ̀, ó lè dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ yẹn. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn Kristẹni yẹn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ èrò Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí?

17 Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé yálà èèyàn jẹun tàbí kò jẹun, ìyẹn ò ní kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 8:8) Lẹ́yìn náà, ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí òmìnira tí wọ́n ní “di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn tí ó jẹ́ aláìlera.” (1 Kọ́r. 8:9) Ó wá sọ fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́ pé kí wọ́n má ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn tó yàn láti máa jẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 10:25, 29, 30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn lọ̀rọ̀ náà, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu. Torí náà, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé káwa náà máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará wa nígbà tí wọ́n bá ṣèpinnu, kódà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì?1 Kọ́r. 10:32, 33.

18. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì òmìnira tó o ní?

18 Ẹ̀bùn ńlá ni Jèhófà fún wa nígbà tó fún wa lómìnira, a sì mọyì báwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ ṣe ń darí wa. (2 Kọ́r. 3:17) À ń gbádùn òmìnira yìí gan-an torí pé ó ń jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn yìí, ká máa lò ó lọ́nà tó ń fògo fún Ọlọ́run, ká sì máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n tí wọ́n bá ṣèpinnu.