Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

A máa ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ṣe ìjọsìn ìdílé. O lè lo àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí láti fi dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ṣe ìjọsìn ìdílé:

  • Múra ìpàdé sílẹ̀. O lè fi àwọn orin tá a máa kọ nípàdé dánra wò, kó o sì rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín pé kí wọ́n múra ìdáhùn kan sílẹ̀.

  • Ka ìtàn Bíbélì kan. Lẹ́yìn náà, ya àwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn yẹn tàbí kó o ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o kọ́.

  • Ka àdúrà tẹ́nì kan gbà nínú Bíbélì, kó o sì wo bíyẹn ṣe lè jẹ́ kí àdúrà ẹ sunwọ̀n sí i.

  • Wo fídíò kan tí ètò Ọlọ́run ṣe, lẹ́yìn náà kó o sọ ohun tó o kọ́ níbẹ̀ fáwọn ẹlòmíì tàbí kó o ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o kọ́.

  • Múra ohun tó o fẹ́ sọ lóde ìwàásù sílẹ̀, o sì lè fi dánra wò.

  • Kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, kó o sì ṣàṣàrò lórí wọn tàbí kó o sọ ohun táwọn nǹkan yẹn kọ́ ẹ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn. a

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà Lára Àwọn Nǹkan Tó Dá” nínú Ilé Ìṣọ́ March 2023.