ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Tó O Bá Ní Ìdààmú Ọkàn
“Ìdààmú ńlá ló bá mi.”—1 SÁM. 1:15.
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ìkìlọ̀ Jésù?
NÍGBÀ tí Jésù ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí . . . àníyàn ìgbésí ayé má bàa di ẹrù pa ọkàn yín,” ìyẹn ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu àtàwọn nǹkan míì tó ń kó ìrònú báni. (Lúùkù 21:34) Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí ìkìlọ̀ yẹn? Ìdí ni pé gbogbo wa la máa kojú àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú bá aráyé.
2. Àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú báni wo làwọn ará wa kan ń kojú?
2 Nígbà míì, ìṣòro tá a ní lè ju ẹyọ kan lọ. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ John * ní àrùn multiple sclerosis tó máa ń jẹ́ kí iṣan ara le gbagidi. Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, ìyàwó rẹ̀ tún fi í sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún (19) tí wọ́n ti ṣègbéyàwó. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì náà tún fi Jèhófà sílẹ̀. Àpẹẹrẹ àwọn míì tó tún kojú ìṣòro ni tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Bob àti Linda. Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn méjèèjì, bó ṣe di pé wọn ò rówó ilé san mọ́ nìyẹn, tí wọ́n sì kó jáde. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àyẹ̀wò tún fi hàn pé Linda ní àrùn ọkàn tó lè ṣekú pa á nígbàkigbà, yàtọ̀ síyẹn àwọn sẹ́ẹ̀lì tó ń gbógun ti àrùn lára rẹ̀ ti daṣẹ́ sílẹ̀.
3. Kí ni Fílípì 4:6, 7 jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
3 Ó dá wa lójú pé Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ àti Ẹlẹ́dàá wa mọ bí àwọn ìṣòro wa ṣe ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. (Ka Fílípì 4:6, 7.) Bíbélì jẹ́ ká mọ ìṣòro tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan kojú. Ó tún jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro náà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.
“ẸNI TÓ MÁA Ń MỌ NǸKAN LÁRA BÍI TIWA NI ÈLÍJÀ”
4. Àwọn ìṣòro wo ni Èlíjà kojú, kí ló sì dá a lójú nípa Jèhófà?
4 Àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ rárá ni Èlíjà ṣiṣẹ́ wòlíì nílẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà yẹn, Áhábù tó jẹ́ aláìṣòótọ́ ló ń jọba. Ó tún wá fẹ́ Jésíbẹ́lì ayaba burúkú tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Ṣe làwọn méjèèjì mú kí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jọ́sìn Báálì, wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Jèhófà. Ọlọ́run ló yọ Èlíjà, wọn ò bá gbẹ̀mí òun náà. Nígbà tí ìyàn tún mú nílẹ̀ yẹn, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn sì mú kó là á já. (1 Ọba 17:2-4, 14-16) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn wòlíì Báálì àtàwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ta kò ó, ó gbára lé Jèhófà. Ó rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà pé kí wọ́n jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo. (1 Ọba 18:21-24, 36-38) Ó dá Èlíjà lójú dáadáa pé Jèhófà ń dáàbò bo òun, ó sì ń ran òun lọ́wọ́ láwọn àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ yẹn.
5-6. Bó ṣe wà nínú 1 Àwọn Ọba 19:1-4, báwo ni nǹkan ṣe rí lára Èlíjà, báwo sì ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
5 Ka 1 Àwọn Ọba 19:1-4. Ẹ̀rù ba Èlíjà nígbà tí Ayaba Jésíbẹ́lì sọ pé òun máa gbẹ̀mí ẹ̀. Torí náà, Èlíjà sá lọ sí agbègbè Bíá-ṣébà. Ìdààmú ọkàn bá a débi pé ó sọ fún Jèhófà pé ó sàn “kí òun kú.” Kí ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé Èlíjà kì í ṣe ẹni pípé, “ẹni tó máa ń mọ nǹkan lára bíi tiwa” lòun náà. (Jém. 5:17) Yàtọ̀ síyẹn, ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn tó rìn ti mú kó rẹ̀ ẹ́, kò sì lókun mọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó máa ronú pé gbogbo ìsapá òun láti mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn Jèhófà ti já sásán àti pé òun nìkan lòun ń sin Jèhófà. (1 Ọba 18:3, 4, 13; 19:10, 14) Bí nǹkan ṣe rí lára Èlíjà lè yà wá lẹ́nu, àmọ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀ yé Jèhófà, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀.
6 Jèhófà ò bá Èlíjà wí torí pé ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fún un lókun. (1 Ọba 19:5-7) Nígbà tó yá, Jèhófà fìfẹ́ tún èrò Èlíjà ṣe, ó sì jẹ́ kó rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó. Jèhófà wá sọ fún un pé àwọn ẹgbẹ̀rún méje (7,000) míì ṣì wà ní Ísírẹ́lì tí wọn ò jọ́sìn Báálì. (1 Ọba 19:11-18) Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí mú kí Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń RÀN WÁ LỌ́WỌ́
7. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́?
7 Ṣé àwọn ìṣòro kan wà tó ń bá ẹ fínra? Ọkàn wa máa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára Èlíjà. Àpẹẹrẹ Èlíjà jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ tiwa náà yé Jèhófà, ó sì lóye àwọn ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè. Ó mọ ibi tágbára wa kù sí, ó mọ ohun tá à ń rò lọ́kàn àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. (Sm. 103:14; 139:3, 4) Táwa náà bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti Èlíjà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa.—Sm. 55:22.
8. Báwo ni Jèhófà ṣe máa mú kó o fara da ìdààmú ọkàn?
8 Ìdààmú lè mú kéèyàn ṣinú rò, ó sì lè mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, rántí pé Jèhófà ò ní dá ẹ dá a, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara dà á. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Jèhófà rọ̀ ẹ́ pé kó o sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún òun, òun sì máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ fún ìrànlọ́wọ́. (Sm. 5:3; 1 Pét. 5:7) Torí náà, máa gbàdúrà lemọ́lemọ́ sí Jèhófà nípa àwọn ìṣòro tó o ní. Òótọ́ ni pé Jèhófà ò ní bá ẹ sọ̀rọ̀ bó ṣe bá Èlíjà sọ̀rọ̀, àmọ́ á bá ẹ sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì á tù ẹ́ nínú wọ́n á sì mú kó o nírètí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ máa fún ẹ níṣìírí.—Róòmù 15:4; Héb. 10:24, 25.
9. Báwo làwọn ọ̀rẹ́ gidi ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
9 Jèhófà sọ fún Èlíjà pé kó yan Èlíṣà láti máa bá a ṣiṣẹ́. Ohun tí Jèhófà ṣe yìí jẹ́ kí Èlíjà rí ẹni táá ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí nǹkan bá tojú sú u. Lọ́nà kan náà, táwa náà bá ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún ọ̀rẹ́ tó ṣe é finú hàn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ á dúró tì wá nígbà ìṣòro, á sì jẹ́ ká lè fara dà á. (2 Ọba 2:2; Òwe 17:17) Tó bá dà bíi pé kò sẹ́ni tó o lè finú hàn, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ táá fún ẹ níṣìírí, táá sì dúró tì ẹ́.
10. Báwo ni àpẹẹrẹ Èlíjà ṣe jẹ́ ká nírètí, báwo sì lohun tó wà nínú Àìsáyà 40:28, 29 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
10 Jèhófà ran Èlíjà lọ́wọ́ láti fara da ìdààmú ọkàn tó ní, ìyẹn sì mú kó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àpẹẹrẹ Èlíjà fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ ká nírètí. Nígbà míì, a lè kojú ìṣòro tó le gan-an, tó ń kó ìdààmú ọkàn bá wa, tó sì ń tán wa lókun. Síbẹ̀, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, á fún wa lókun ká lè máa sìn ín nìṣó.—Ka Àìsáyà 40:28, 29.
HÁNÀ, DÁFÍDÌ ÀTI “ÁSÁFÙ” GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ
11-13. Kí ló kó ìdààmú ọkàn bá mẹ́ta lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
11 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì náà kojú ìṣòro tó le gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Hánà ò rọ́mọ bí, ìyẹn sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá a, yàtọ̀ síyẹn, 1 Sám. 1:2, 6) Ìṣòro yìí kó ìdààmú ọkàn bá a débi pé ó sunkún títí, kò sì lè jẹun.—1 Sám. 1:7, 10.
orogún rẹ̀ ń mú ayé sú u. (12 Àwọn ìgbà kan wà tí Ọba Dáfídì náà ní ìdààmú ọkàn. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó kó ìdààmú ọkàn bá a. Àkọ́kọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a torí àwọn àṣìṣe tó ṣe. (Sm. 40:12) Yàtọ̀ síyẹn, Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i, ohun tó sì fa ikú Ábúsálómù nìyẹn. (2 Sám. 15:13, 14; 18:33) Kò tán síbẹ̀ o, ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ dalẹ̀ rẹ̀. (2 Sám. 16:23–17:2; Sm. 55:12-14) Ọ̀pọ̀ lára àwọn sáàmù tí Dáfídì kọ jẹ́ ká rí bí ìrẹ̀wẹ̀sì ṣe bò ó mọ́lẹ̀, síbẹ̀ ó tún jẹ́ ká rí bó ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Sm. 38:5-10; 94:17-19.
13 Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, onísáàmù kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara àwọn èèyàn burúkú. Ó ṣeé ṣe kí onísáàmù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ásáfù tó wá látinú ẹ̀yà Léfì, tó sì ṣiṣẹ́ sìn nínú “ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.” Bí onísáàmù yìí ṣe rí i tí àwọn ẹni burúkú ń gbádùn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà mú kí nǹkan sú u débi pé kò láyọ̀ mọ́. Kódà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni èrè wà nínú bóun ṣe ń sin Ọlọ́run.—Sm. 73:2-5, 7, 12-14, 16, 17, 21.
14-15. Kí ni àpẹẹrẹ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?
14 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a jíròrò tán yìí gbára lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n gbàdúrà sí i taratara nípa ìṣòro tí wọ́n ní. Wọ́n tú ọkàn wọn jáde sí Jèhófà, wọ́n sì jẹ́ kó mọ bí ìṣòro náà ṣe rí lára wọn. Láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n ní sí, wọn ò yé lọ sílé Jèhófà láti jọ́sìn.—1 Sám. 1:9, 10; Sm. 55:22; 73:17; 122:1.
15 Jèhófà fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe 1 Sám. 1:18) Dáfídì ní tiẹ̀ sọ pé: “Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀, àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.” (Sm. 34:19) Onísáàmù yẹn sì sọ pé Jèhófà ti “di ọwọ́ ọ̀tún [òun] mú,” ó sì ń fìfẹ́ tọ́ òun sọ́nà. Ó wá sọ pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Mo ti fi Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ṣe ibi ààbò mi.” (Sm. 73:23, 24, 28) Kí la rí kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yìí? Nígbà míì, àwọn ìṣòro lè pin wá lẹ́mìí, kí wọ́n sì kó ìdààmú ọkàn bá wa. Àmọ́, a lè fara dà á tá a bá ń ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́, tá à ń gbàdúrà sí i láìjẹ́ kó sú wa, tá a sì ń pa àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ mọ́.—Sm. 143:1, 4-8.
rí lára ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó sì gbọ́ àdúrà wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mú kí ọkàn Hánà balẹ̀. (GBÁRA LÉ JÈHÓFÀ KÓ O LÈ ṢÀṢEYỌRÍ
16-17. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká jìnnà sáwọn ará? (b) Kí lá mú ká jèrè okun pa dà?
16 Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tá a rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ìyẹn ni pé kò yẹ ká jìnnà sí Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. (Òwe 18:1) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Nancy tó ní ẹ̀dùn ọkàn tó le gan-an nígbà tí ọkọ rẹ̀ fi í sílẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ọjọ́ míì wà tí mi ò ní fẹ́ rí ẹnikẹ́ni tí mi ò sì ní fẹ́ bá èèyàn sọ̀rọ̀. Àmọ́, bí mo ṣe ń fẹ́ láti dá wà máa ń mú kí inú mi túbọ̀ bà jẹ́ sí i.” Nǹkan yí pa dà nígbà tí Nancy bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn míì tó níṣòro lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mo máa ń tẹ́tí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ ohun tó ń bá wọn fínra. Mo wá rí i pé bí mo ṣe túbọ̀ ń ran àwọn míì lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni mò ń gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro mi.”
17 A lè jèrè okun pa dà tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé wa. Tá a bá ń pésẹ̀ sípàdé déédéé, ṣe la túbọ̀ ń jẹ́ kí Jèhófà di ‘olùrànlọ́wọ́ àti olùtùnú’ wa. (Sm. 86:17) Láwọn ìpàdé wa, Jèhófà máa ń fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn ìpàdé wa tún máa ń jẹ́ ká lè “fún ara wa ní ìṣírí” lẹ́nì kìíní kejì. (Róòmù 1:11, 12) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sophia sọ pé: “Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ ló ràn mí lọ́wọ́. Mi ò fọ̀rọ̀ lílọ sípàdé ṣeré rárá torí pé mo máa ń rí ìṣírí gbà níbẹ̀. Mo ti rí i pé bí mo ṣe túbọ̀ ń lo ara mi lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti fara da àwọn ìṣòro mi.”
18. Tá a bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí ni Jèhófà máa fún wa?
18 Nígbàkigbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ẹ jẹ́ ká rántí pé láìpẹ́ Jèhófà máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìdààmú ọkàn kúrò. Àmọ́, kì í ṣèyẹn nìkan, ní báyìí ó ń fún wa ní “agbára” táá mú ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìdààmú ọkàn èyíkéyìí tá a bá ní.—Fílí. 2:13.
19. Ìdánilójú wo ló wà nínú Róòmù 8:37-39?
19 Ka Róòmù 8:37-39. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú kó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ní ìdààmú ọkàn lọ́wọ́? Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bá a ṣe lè fara wé Jèhófà ká sì fìfẹ́ ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ní ìdààmú ọkàn.
ORIN 44 Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
^ ìpínrọ̀ 5 Téèyàn bá ní ìdààmú ọkàn tí kò sì lọ bọ̀rọ̀, ó lè jẹ́ kéèyàn ṣàárẹ̀ kó sì rẹ̀wẹ̀sì. Báwo ni Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? A máa rí bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tóun náà ní ìdààmú ọkàn. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì tó yíjú sí Jèhófà nígbà tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn.
^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
^ ìpínrọ̀ 53 ÀWÒRÁN: Áńgẹ́lì Jèhófà rọra jí Èlíjà lójú oorun, ó sì fún un ní búrẹ́dì àti omi.
^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Onísáàmù kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ásáfù gbádùn kó máa ṣàkọsílẹ̀ orin kó sì máa kọrin pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì míì.