Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé lóòótọ́ ni pé láyé àtijọ́ àwọn kan máa ń fún èpò sínú oko ẹlòmíì?

Ìwé Digest tí Olú Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Justinian kọ lọ́dún 1468 rèé, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ òfin àti ẹjọ́ láyé àtijọ́

NÍNÚ Mátíù 13:24-26, Jésù sọ pé: “Ìjọba ọ̀run wá dà bí ọkùnrin kan tí ó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì tún fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà, ó sì lọ. Nígbà tí ewé ọ̀gbìn náà rú jáde, tí ó sì mú èso jáde, nígbà náà ni àwọn èpò fara hàn pẹ̀lú.” Àwọn òǹkọ̀wé kan sọ pé bóyá nirú ohun tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yìí máa ń ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìwé òfin ilẹ̀ Róòmù fi hàn pé irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀.

Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: ‘Òfin Róòmù sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́nì kan bá fún èpò sóko olóko torí pé ó fẹ́ gbẹ̀san. Ti pé òfin wà fún irú nǹkan báyìí fi hàn pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa ni.’ Alastair Kerr tó jẹ́ onímọ̀ nípa òfin sọ pé ní ọdún 533 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Justinian tẹ ìwé kan tó pè ní Digest jáde. Ìwé náà jẹ́ àkópọ̀ àwọn òfin ilẹ̀ Róòmù àtàwọn àkọsílẹ̀ látinú àwọn ẹjọ́ kan tí wọ́n ti dá sẹ́yìn láàárín ọdún 100 sí 250 Sànmánì Kristẹni. Nínú ìwé náà (ìyẹn Digest, 9.2.27.14), adájọ́ kan tó ń jẹ́ Ulpian tọ́ka sí ẹjọ́ kan tí àgbà òṣèlú ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Celsus dá ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì. Nínú ẹjọ́ yẹn, ẹnì kan fún èpò sínú oko ẹlòmíì, èpò náà sì fún àwọn irúgbìn náà pa. Ìwé Digest náà sọ ẹjọ́ tí wọ́n máa dá tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé, èyí á sì jẹ́ kí olóko náà lè gba ìtanràn lọ́wọ́ ọ̀daràn náà.

Torí náà, ó ṣe kedere pé ìwà burúkú yìí máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń ṣàkóso. Èyí fi hàn pé ohun tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.

Báwo ni agbára táwọn Róòmù fún ilé ẹjọ́ àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe pọ̀ tó?

NÍGBÀ yẹn, abẹ́ àkóso ìlú Róòmù ni àgbègbè Jùdíà wà. Gómìnà tó jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù ló ń ṣàkóso àgbègbè náà, ó sì láwọn ọmọ ogun tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀. Ohun tó jà jù nínú iṣẹ́ gómìnà yìí ni pé kí owó orí máa wọlé déédéé fún ìlú Róòmù, kó sì tún rí i dájú pé àgbègbè náà tòrò. Kí àlàáfíà lè wà, àwọn aláṣẹ Róòmù máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá rúfin tàbí tó ń da ìlú rú, wọn kì í sì fàyè gba ìwàkiwà. Tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ó tẹ́ wọn lọ́rùn kí àwọn àgbààgbà ìlú náà máa bójú tó àwọn ọ̀ràn tó bá jẹyọ níbẹ̀.

Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù ń gbẹ́jọ́ lọ́wọ́

Sànhẹ́dírìn ni ilé ẹjọ́ àwọn Júù tó ga jù lọ, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti máa ń bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ òfin àwọn Júù. Àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké míì sì wà káàkiri àgbègbè Jùdíà. Àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù kì í sábà dá sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹjọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ẹni tàbí ti ìwà ọ̀daràn, àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké yìí ló máa ń bójú tó wọn. Àmọ́, àwọn ilé ẹjọ́ yìí kò láṣẹ láti dájọ́ ikú fún ọ̀daràn torí pé àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù nìkan ló lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn kò tẹ̀ lé ìlànà yẹn nígbà tí wọ́n gbẹ́jọ́ Sítéfánù torí pé lẹ́yìn tí wọ́n gbẹ́jọ́ rẹ̀ tán, àwọn náà ló tún ṣètò báwọn èèyàn ṣe sọ ọ́ lókùúta pa.​—Ìṣe 6:8-15; 7:54-60.

Torí náà, ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù lágbára gan-an. Síbẹ̀, ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Emil Schürer sọ pé, “Ó níbi tágbára wọn mọ, torí pé àwọn aláṣẹ ìlú Róòmù lè gbé ìgbésẹ̀ nígbàkigbà láìfi tiwọn pè tí wọ́n bá rí i pé àwọn kan fẹ́ rú òfin ìjọba Róòmù.” Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gágun kan tó ń jẹ́ Kíláúdíù Lísíà gba àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa á.​—⁠ṣe 23:​26-30.