Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kí A Nífẹ̀ẹ́ . . . ní Ìṣe àti Òtítọ́”

“Kí A Nífẹ̀ẹ́ . . . ní Ìṣe àti Òtítọ́”

“Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”​—1 JÒH. 3:18.

ORIN: 72, 124

1. Ìfẹ́ wo ló ga jù, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ÌFẸ́ tá a gbé karí ìlànà, ìyẹn a·gaʹpe, ni ìfẹ́ tó ga jù. Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run sì ni ìfẹ́ yìí ti wá. (1 Jòh. 4:7) Yàtọ̀ sí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ yìí ti wá, ó tún fi ẹ̀bùn yìí jíǹkí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ yìí máa ń mú ká lọ́yàyà, ká sì kóni mọ́ra, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi í hàn ni pé ká máa lo ara wa fáwọn míì. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé ìfẹ́ a·gaʹpe “kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n, ohun téèyàn bá ṣe ló máa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́.” Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn tàbí tí wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí wa, inú wa máa dùn, àá láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì nítumọ̀.

2, 3. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa?

2 Kí Jèhófà tó dá àwa èèyàn ló ti nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, kó tó dá Ádámù àti Éfà ló ti ṣe ilẹ̀ ayé lọ́nà tó máa dùn ún gbé fún wa. Àwọn nǹkan tó dá síbẹ̀ fi hàn pé ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa títí láé, kì í kàn ṣe pé ká máa gbébẹ̀. Torí tiwa ni Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe fún àǹfààní ara rẹ̀. Ó tún fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́ ní ti pé ó dá wa ká lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè.

3 Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà fi ìfẹ́ tó ga jù lọ hàn sí wa. Ó pèsè ìràpadà fáwọn àtọmọdọ́mọ wọn torí ó mọ̀ pé àwọn kan lára wọn máa nífẹ̀ẹ́ òun, wọ́n á sì ṣe ohun tó tọ́. (Jẹ́n. 3:15; 1 Jòh. 4:10) Kódà, látìgbà tí Jèhófà ti ṣèlérí pé Olùgbàlà kan máa rà wá pa dà ló ti gbà pé òun ti rà wá pa dà. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo tó ṣeyebíye kó lè rà wá pa dà. (Jòh. 3:16) A mà dúpẹ́ o, fún ìfẹ́ tó ga tí Jèhófà fi hàn sí wa yìí!

4. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àwa èèyàn aláìpé lè fìfẹ́ hàn?

4 A máa ń fìfẹ́ hàn torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún máa ń jẹ́ kó nira fún wa láti fìfẹ́ hàn, síbẹ̀ a lè fìfẹ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, Ébẹ́lì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nígbà tó fi èyí tó dáa jù nínú ẹran ọ̀sìn rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà. (Jẹ́n. 4:​3, 4) Bákan náà, Nóà fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn ní ti pé ọ̀pọ̀ ọdún ló fi kìlọ̀ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò tẹ́tí sí i. (2 Pét. 2:5) Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí Ábúráhámù fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó fi hàn pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló gbawájú lọ́kàn òun, kì í ṣe ìfẹ́ tòun. (Ják. 2:21) Ẹ jẹ́ káwa náà fara wé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí, ká máa fìfẹ́ hàn bí kò bá tiẹ̀ rọrùn fún wa.

ÌYÀTỌ̀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN ÌFẸ́ TÒÓTỌ́ ÀTI ÌFẸ́ ÀGÀBÀGEBÈ

5. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́?

5 Bíbélì fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ ká fi hàn “ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:18) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó burú tá a bá sọ fún ẹnì kan pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Rárá o! (1 Tẹs. 4:18) Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ìfẹ́ wa ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́ orí ahọ́n, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni náà nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, tí Kristẹni kan bá nílò àwọn nǹkan bí oúnjẹ, aṣọ àtàwọn ohun ìgbẹ́mìíró míì, a gbọ́dọ̀ ràn án lọ́wọ́, kì í ṣe ká kàn kí i pẹ̀lẹ́. (Ják. 2:​15, 16) Bákan náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wa, a ò kàn ní máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ‘rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde fún ìkórè,’ kàkà bẹ́ẹ̀ àá máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.​—Mát. 9:38.

6, 7. (a) Irú ìfẹ́ wo ni “ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè”? (b) Sọ àpẹẹrẹ àwọn tó fi ìfẹ́ àgàbàgebè hàn.

6 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé a gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ “ní ìṣe àti òtítọ́.” Torí náà, ìfẹ́ tá a ní gbọ́dọ̀ wà “láìsí àgàbàgebè.” (Róòmù 12:9; 2 Kọ́r. 6:6) Ìyẹn túmọ̀ sí pé a ò lè máa sọ pé à ń fìfẹ́ hàn tó sì jẹ́ pé ojú ayé lásán là ń ṣe. Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ìfẹ́ tòótọ́ lè ní àgàbàgebè nínú?’ Kò sóhun tó jọ ọ́. Ká sòótọ́, tí ìfẹ́ bá ti ní àgàbàgebè nínú, kì í ṣe ìfẹ́ rárá, gbàrọgùdù lásán ni.

7 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn kan tó ní ìfẹ́ tí kò dénú. Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì ṣe bí ẹni pé ire Éfà lòun ń wá, àmọ́ ohun tó ṣe fi hàn pé onímọtara-ẹni-nìkan àti alágàbàgebè ni. (Jẹ́n. 3:​4, 5) Nígbà ayé Dáfídì, Áhítófẹ́lì fi hàn pé ọ̀rẹ́ ojú lásán lòun ń bá Dáfídì ṣe. Àmọ́ torí ohun tó máa rí gbà, ó kẹ̀yìn sí Dáfídì nígbà tí Ábúsálómù gba ìjọba. (2 Sám. 15:31) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn tó ń dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ máa ń lo “ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in àti ọ̀rọ̀ ìyinni” bí ẹni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tó wà lọ́kàn wọn.​—Róòmù 16:​17, 18.

8. Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

8 Ìfẹ́ àgàbàgebè tàbí ìfẹ́ ẹ̀tàn kò dáa torí pé ó yàtọ̀ pátápátá sí ìfẹ́ tòótọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń jẹ́ ká ní. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ lè tan àwọn èèyàn jẹ, àmọ́ a ò lè fi tan Jèhófà jẹ láé. Kódà, Jésù sọ pé “ìyà mímúná jù lọ” ló máa jẹ àwọn alágàbàgebè. (Mát. 24:51) Ó dájú pé kò sí ìkankan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó máa fẹ́ jẹ́ alágàbàgebè. Síbẹ̀ ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ìfẹ́ tí mo ní sáwọn èèyàn dénú, àbí ojú ayé ni mò ń ṣe? Ṣé kì í ṣe torí nǹkan tí màá rí gbà ni mo ṣe ń ṣe bíi pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn?’ Ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́sàn-án tá a lè gbà fi hàn pé “ìfẹ́ tí kò ní àgàbàgebè” la ní.

BÁ A ṢE LÈ FI ÌFẸ́ HÀN “NÍ ÌṢE ÀTI ÒTÍTỌ́”

9. Tá a bá ní ìfẹ́ tòótọ́, kí la máa ṣe?

9 Máa fayọ̀ sìn bí àwọn èèyàn ò tiẹ̀ rí ẹ. Ó yẹ kí inú wa máa dùn láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa “ní ìkọ̀kọ̀,” kódà bí kò bá tiẹ̀ sẹ́ni tó mọ ohun tá à ń ṣe. (Ka Mátíù 6:​1-4.) Èyí yàtọ̀ sóhun tí Ananíà àti Sáfírà ṣe. Torí pé wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn máa kan sárá sí wọn, wọ́n bù mọ́ ọrẹ tí wọ́n ṣe, wọ́n sì jìyà ìwà àgàbàgebè tí wọ́n hù náà. (Ìṣe 5:​1-10) Àmọ́ ìfẹ́ tòótọ́ máa mú ká fayọ̀ sin àwọn ará wa bí kò bá tiẹ̀ sẹ́ni tó yìn wá tàbí tó rí ohun tá a ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arákùnrin tó ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí. Wọn kì í pe àfíyèsí sí ara wọn, kí wọ́n wá máa sọ pé àwọn làwọn ṣe tibí ṣe tọ̀hún.

10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?

10 Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kó o sì máa bọlá fáwọn èèyàn. (Ka Róòmù 12:10.) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nígbà tó ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbayì. (Jòh. 13:​3-5, 12-15) Ó yẹ káwa náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ká sì ṣe tán láti sin àwọn ẹlòmíì. Kódà, àwọn àpọ́sítélì ò fi bẹ́ẹ̀ lóye kókó yìí àfìgbà tí wọ́n rí ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Jòh. 13:7) Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ torí bá a ṣe kàwé tó, torí àwọn ohun tá a ní tàbí torí àwọn àǹfààní tá a ní nínú ètò Jèhófà. (Róòmù 12:3) Tí wọ́n bá ń yin ẹnì kan, kò yẹ ká máa jowú, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló yẹ ká máa bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ yọ̀ kódà tá a bá tiẹ̀ rò pé ó yẹ kí wọ́n yin àwa náà fún ipa tá a kó nínú iṣẹ́ náà.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá?

11 Máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá. Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará torí pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń gbéni ró. (Éfé. 4:29) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ rí i pé a gbóríyìn fún wọn látọkàn wá. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ṣe là ń gbé wọn gẹṣin aáyán, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká fún wọn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní. (Òwe 29:5) Tá a bá ń gbóríyìn fún ẹnì kan níṣojú rẹ̀ àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ láìdáa lẹ́yìn, ìwà àgàbàgebè là ń hù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó dáa. (1 Kọ́r. 11:2) Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí ohun tí wọ́n ṣe ò fi dáa, kò sì kàn wọ́n lábùkù.​—1 Kọ́r. 11:​20-22.

Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ni pé ká máa ran àwọn ará wa tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Báwo la ṣe lè máa gba àwọn ará lálejò tìfẹ́tìfẹ́?

12 Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò. Jèhófà sọ pé ká lawọ́ sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Ka 1 Jòhánù 3:17.) Síbẹ̀, kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ torí ohun tá a máa rí gbà lọ́wọ́ wọn. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Àwọn wo ni mo máa ń gbà lálejò? Ṣé àwọn tó sún mọ́ mi àbí àwọn tó gbajúmọ̀ àtàwọn tí mo lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn ni mo máa ń gbà lálejò? Ṣé mo máa ń lawọ́ sáwọn ará tá ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ra àtàwọn tí kò ní lọ́wọ́?’ (Lúùkù 14:​12-14) Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ká sọ pé ìṣòro bá Kristẹni kan torí pé ó ṣèpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Ṣé wàá ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Tàbí kẹ̀, kí ni wàá ṣe tẹ́nì kan tó o gbà lálejò kò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ? Ó yẹ ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.” (1 Pét. 4:9) Tó o bá ń ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, wàá láyọ̀ torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe lò ń ṣe.​—Ìṣe 20:35.

13. (a) Àwọn wo ló máa gba pé ká ṣe sùúrù fún? (b) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe fáwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lera nípa tẹ̀mí?

13 Ẹ máa ṣèrànwọ́ fáwọn aláìlera nípa tẹ̀mí. Bíbélì rọ̀ wá pé “ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” Ọwọ́ tá a bá fi mú ìmọ̀ràn yìí ló máa sọ bóyá a nífẹ̀ẹ́ àbí a ò nífẹ̀ẹ́. (1 Tẹs. 5:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ tí ìgbàgbọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára tẹ́lẹ̀ ti wá di alágbára nípa tẹ̀mí, síbẹ̀, àwọn ará wa kan wà tó gba pé ká máa ṣe sùúrù fún wọn, ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn láìdáwọ́ dúró. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tá a bá ń fi Bíbélì gbà wọ́n níyànjú, tá a bá jọ lọ sóde ẹ̀rí tàbí tá à ń wáyè tẹ́tí sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, dípò tá a fi máa ka àwọn ará kan sí aláìlera, tá a sì máa ka àwọn míì sí alágbára nípa tẹ̀mí, ó yẹ ká mọ̀ pé gbogbo wa la níbi tá a dáa sí àti ibi tá a kù sí. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òun láwọn àìlera tòun tàbí àwọn ibi tóun kù sí. (2 Kọ́r. 12:​9, 10) Torí náà, gbogbo wa pátá la lè ran ara wa lọ́wọ́ lẹ́nì kìíní kejì.

14. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa?

14 Máa wá àlàáfíà. Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa, kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni wọ́n ṣì wá lóye tàbí wọ́n ṣàìdáa sí wa. (Ka Róòmù 12:​17, 18.) A lè yanjú ọ̀rọ̀ yẹn tá a bá bẹ ẹni náà pé kó má bínú, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ wá látọkàn. Bí àpẹẹrẹ, dípò kó o sọ pé, “Ẹn-ẹn, má bínú,” ṣe ló yẹ kó o gbà pé o jẹ̀bi, kó o sì bẹ onítọ̀hún pé, “Jọ̀ọ́ má bínú ohun tí mo sọ.” Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn tọkọtaya máa wá àlàáfíà. Kò yẹ kí wọ́n máa ṣe bíi pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn níta, àmọ́ kí wọ́n wá máa bára wọn yan odì nínú ilé, tàbí kí wọ́n máa bú ara wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa lu ara wọn.

15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la ti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá?

15 Máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, ó yẹ ká dárí jì í, ká sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà tán síbẹ̀. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa fara dà á ‘fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́, kí á máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.’ Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa dárí ji àwọn tí kò mọ̀ pé àwọn ṣẹ̀ wá. (Éfé. 4:​2, 3) Tó bá jẹ́ lóòótọ́ la dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a ò ní máa ronú nípa ohun tí wọ́n ṣe sí wa, torí pé ìfẹ́ kì í “kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́r. 13:​4, 5) Tá a bá ń di àwọn ará wa sínú, àárín wa ò ní gún, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sì lè bà jẹ́. (Mát. 6:​14, 15) Bákan náà, a lè fi hàn pé lóòótọ́ la ti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá tá a bá ń gbàdúrà fún wọn.​—Lúùkù 6:​27, 28.

16. Báwo ló ṣe yẹ ká máa lo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní nínú ètò Jèhófà?

16 Máa fi ara rẹ jìn fáwọn míì. Tá a bá gba àwọn iṣẹ́ kan nínú ètò Jèhófà, ṣe ló yẹ ká lo àǹfààní yìí láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará, ká má sì “máa wá àǹfààní ti ara [wa], bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́r. 10:24) Bí àpẹẹrẹ, ní àwọn àpéjọ wa, àwọn alábòójútó èrò ti máa ń wà níbẹ̀ káwọn ará tó bẹ̀rẹ̀ sí í dé. Wọn kì í lo àǹfààní yẹn láti wá àyè tó dáa jù fún ara wọn àti ìdílé wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ọ̀pọ̀ wọn máa ń jókòó síbi tí àyè bá ti ṣí sílẹ̀ lápá ibi tí wọ́n yàn wọ́n sí. Bí wọ́n ṣe ń fi ara wọn jìn yìí fi hàn pé wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́, wọn ò sì mọ tara wọn nìkan. Ọ̀nà wo lo lè gbà fara wé wọn?

17. Tí Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará lóòótọ́, kí ló máa ṣe?

17 Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá tẹ́nì kan ò mọ̀, má sì pa dà sídìí rẹ̀ mọ́. Àwọn Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ torí pé wọn ò fẹ́ kí ojú ti àwọn tàbí torí kí wọ́n má bàa já àwọn míì kulẹ̀. (Òwe 28:13) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fìfẹ́ hàn, torí pé ó máa ṣàkóbá fún ẹni náà àtàwọn míì. Kódà, ó lè má jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìjọ, ó sì lè ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. (Éfé. 4:30) Bí Kristẹni kan tó dẹ́ṣẹ̀ bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará lóòótọ́, á sọ ohun tó ṣe fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́.​—Ják. 5:​14, 15.

18. Báwo ni ìfẹ́ ti ṣe pàtàkì tó?

18 Ìfẹ́ ni ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù. (1 Kọ́r. 13:13) Òun ló ń jẹ́ káwọn èèyàn dá wa mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn Jésù ni wá àti pé à ń fara wé Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. (Éfé. 5:​1, 2) Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Bí èmi kò bá ní ìfẹ́, èmi kò jámọ́ nǹkan kan.’ (1 Kọ́r. 13:2) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi hàn pé a ní ìfẹ́, kì í ṣe “ní ọ̀rọ̀” nìkan bí kò ṣe “ní ìṣe àti òtítọ́” pẹ̀lú.