Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 40

ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi

Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”

Jèhófà “Ń Mú Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn Lára Dá”

“Ó ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá; ó ń di àwọn egbò wọn.”SM. 147:3.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn ṣeré rárá, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe máa ń tù wá nínú tá a bá ní ọgbẹ́ ọkàn àti báwa náà ṣe lè tu àwọn míì nínú.

1. Báwo lọ̀rọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe máa ń rí lára ẹ̀?

 JÈHÓFÀ ń rí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ láyé. Ó mọ ìgbà tínú wa ń dùn àtìgbà tínú wa ò dùn. (Sm. 37:18) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa sìn ín, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a láwọn ìṣòro tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Ohun míì ni pé ó máa ń wu Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́, kó sì tù wá nínú.

2. Kí ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní bó ṣe ń bójú tó wa?

2 Sáàmù 147:3 sọ pé Jèhófà máa ‘ń di egbò’ àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn. Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn. Àmọ́ tá a bá fẹ́ jàǹfààní bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wa, kí ló yẹ ká ṣe? Wo àpèjúwe yìí ná. Dókítà kan tó mọṣẹ́ dáadáa lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti tọ́jú ẹnì kan tó fara pa kára ẹ̀ lè yá. Àmọ́ tí aláìsàn náà bá fẹ́ kára òun yá, ó gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo nǹkan tí dókítà náà bá sọ. Lọ́nà kan náà, tá a bá ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ọkàn wa máa balẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ohun tí Jèhófà sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn, àá sì tún jíròrò bá a ṣe lè fi ìmọ̀ràn yẹn sílò.

JÈHÓFÀ FI DÁ WA LÓJÚ PÉ A ṢEYEBÍYE

3. Kí nìdí táwọn kan fi máa ń rò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan?

3 Ó bani nínú jẹ́ pé nínú ayé tá à ń gbé yìí, àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ fi máa ń ronú pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Helen a sọ pé: “Nínú ìdílé tí mo dàgbà sí, a kì í fìfẹ́ hàn síra wa. Oníjà ni bàbá mi, ojoojúmọ́ ni wọ́n sì máa ń sọ fún wa pé a ò wúlò fún nǹkan kan.” Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Helen ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, wọ́n lè ti hùwà ìkà sí ẹ, kí wọ́n máa ṣàríwísí ẹ ṣáá tàbí kí wọ́n kórìíra ẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún ẹ láti gbà pé ẹnì kan wà tó nífẹ̀ẹ́ ẹ dénú.

4. Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú ní Sáàmù 34:18?

4 Kódà táwọn èèyàn bá ti hùwà ìkà sí ẹ rí, mọ̀ dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, o sì ṣeyebíye lójú ẹ̀. Bíbélì sọ pé ó “wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn.” (Ka Sáàmù 34:18.) Tí “àárẹ̀ bá [bá] ẹ̀mí” ẹ, máa rántí pé Jèhófà rí ohun rere kan lọ́kàn ẹ, ìdí nìyẹn tó fi fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Kò sígbà tí ò ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí pé o ṣeyebíye lójú ẹ̀.

5. Kí la kọ́ nínú bí Jésù ṣe hùwà sáwọn tí wọ́n ń fojú àbùkù wò?

5 Tá a bá wo àpẹẹrẹ Jésù, a máa mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára Jèhófà. Nígbà tí Jésù ń wàásù láyé, ó kíyè sí àwọn tí wọ́n ń fojú àbùkù wò, ó sì ṣàánú wọn. (Mát. 9:9-12) Nígbà tí obìnrin kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an fọwọ́ kan aṣọ Jésù, ó mọ̀ pé ara òun máa yá, torí náà Jésù tù ú nínú, ó sì gbóríyìn fún un torí pé ó nígbàgbọ́. (Máàkù 5:25-34) Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó fìwà jọ Bàbá ẹ̀ láìkù síbì kan. (Jòh. 14:9) Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì ẹ, ó sì ń kíyè sí àwọn ìwà rere tó o ní, ìgbàgbọ́ tó o ní àti bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

6. Kí lo lè ṣe tó o bá ń rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan?

6 Kí lo lè ṣe tó o bá ń rò pé o ò já mọ́ nǹkan kan? Máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ṣeyebíye lójú Jèhófà, kó o sì máa ṣàṣàrò nípa wọn. b (Sm. 94:19) Tọ́wọ́ ẹ ò bá tẹ ohun tó ò ń lé tàbí tó ò lè ṣe tó àwọn ẹlòmíì, má ṣe dá ara ẹ lẹ́bi. Jèhófà ò fẹ́ kó o ṣe ohun tágbára ẹ ò gbé. (Sm. 103:13, 14) Tẹ́nì kan bá hùwà ìkà sí ẹ, ìwọ kọ́ lo jẹ̀bi torí kò yẹ kó hùwà yẹn sí ẹ. Rántí pé Jèhófà máa fìyà jẹ ẹni náà, ó sì máa tù ẹ́ nínú. (1 Pét. 3:12) Sandra tí wọ́n hùwà ìkà sí nígbà tó wà lọ́mọdé sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè máa fi ojú tó fi ń wò mí wo ara mi.”

7. Báwo lo ṣe lè lo àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?

7 Má rò pé Jèhófà ò lè lò ẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àǹfààní ńlá ni pé ò ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ bó o ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. (1 Kọ́r. 3:9) Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí lè mú kó o mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó ń jìyà, ìyẹn á sì mú kó o káàánú wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Jèhófà lo àwọn ará láti ran Helen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́wọ́, òun náà sì ti ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ báyìí. Ó sọ pé: “Jèhófà ti sọ èmi tí mi ò ‘já mọ́ nǹkan kan’ di ẹni tó wúlò, táwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́.” Ní báyìí, aṣáájú-ọ̀nà ni, ó sì ń láyọ̀.

MỌ̀ DÁJÚ PÉ JÈHÓFÀ TI DÁRÍ JÌ Ẹ́

8. Kí ni Jèhófà fi dá wa lójú ní Àìsáyà 1:18?

8 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣì máa ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá kí wọ́n tó ṣèrìbọmi tàbí lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi. Àmọ́, ó yẹ ká rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìdí nìyẹn tó fi pèsè ìràpadà, kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ẹ̀bùn iyebíye ni ìràpadà, Jèhófà sì fẹ́ ká jàǹfààní ẹ̀. Jèhófà fi dá wa lójú pé tá a bá ti “yanjú ọ̀rọ̀” c láàárín àwa àti òun, òun máa dárí jì wá pátápátá. (Ka Àìsáyà 1:18.) Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an torí pé tó bá ti dárí jì wá, ó ti gbàgbé ẹ̀ nìyẹn! Àmọ́ kò gbàgbé àwọn nǹkan rere tá a ti ṣe.—Sm. 103:9, 12; Héb. 6:10.

9. Kí ni ò ní jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn?

9 Tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti dá sẹ́yìn, ńṣe ni kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí àtàwọn nǹkan tó o máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó kábàámọ̀ pé òun ṣenúnibíni tó le gan-an sáwọn Kristẹni, àmọ́ ó mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun. (1 Tím. 1:12-15) Ṣé Pọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn? Ó dájú pé kò ṣe bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ronú mọ́ nípa àwọn nǹkan tó gbé ṣe nígbà tó jẹ́ Farisí táwọn èèyàn ń bọ̀wọ̀ fún. (Fílí. 3:4-8, 13-15) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ó sì ń retí àwọn nǹkan rere tó máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìwọ náà lè ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan sẹ́yìn, àmọ́ ó yẹ kó o gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Torí náà, àwọn nǹkan tá à ń ṣe báyìí ló yẹ ká gbájú mọ́, ká sì máa retí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣèlérí tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú.

10. Kí lo lè ṣe tó o bá ti ṣe ohun tó dun ẹnì kan?

10 Tó o bá ti ṣe ohun tó dun ẹnì kan, ọkàn ẹ lè máa dá ẹ lẹ́bi. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, kó o sì bẹ ẹni náà pé kó má bínú. (2 Kọ́r. 7:11) Bẹ Jèhófà pé kó ran ẹni tó o ṣẹ̀ lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ran ìwọ àtẹni náà lọ́wọ́ láti fara dà á, kí àárín yín sì pa dà gún régé.

11. Kí la kọ́ nínú àpẹẹrẹ wòlíì Jónà? (Wo àwòrán.)

11 Kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe tó o ṣe sẹ́yìn, kó o sì jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ níbikíbi tó bá fẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ wòlíì Jónà. Kàkà kó lọ sílùú Nínéfè tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó lọ, ńṣe ló gba ibòmíì lọ. Jèhófà bá Jónà wí, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe tó ṣe. (Jónà 1:1-4, 15-17; 2:7-10) Jèhófà ò jẹ́ kọ́rọ̀ Jónà sú òun. Ọlọ́run wá fún un láǹfààní pé kó lọ sílùú Nínéfè lẹ́ẹ̀kejì, lótẹ̀ yìí, ó ṣègbọràn láìjáfara. Àmọ́, kò jẹ́ kí àṣìṣe tó ṣe sẹ́yìn mú kó kọ iṣẹ́ tí Jéhòfà gbé fún un.—Jónà 3:1-3.

Lẹ́yìn tí wòlíì Jónà jáde nínú ẹja ńlá yẹn láìfarapa, Jèhófà ní kó pa dà sílùú Nínéfè láti lọ jíṣẹ́ tóun rán an (Wo ìpínrọ̀ 11)


JÈHÓFÀ MÁA Ń FI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ Ẹ̀ TÙ WÁ NÍNÚ

12. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tí ohun kan bá kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa? (Fílípì 4:6, 7)

12 Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ tù wá nínú tí ohun kan bá kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ron àti Carol. Ó bani nínú jẹ́ pé ọmọ wọn ọkùnrin tó ti pé ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39) gbẹ̀mí ara ẹ̀. Wọ́n sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ti dé bá wa, àmọ́ eléyìí ló burú jù. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ò rórun sùn lálẹ́, àmọ́ a máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ bí Fílípì 4:6, 7 ṣe sọ.” (Kà á.) Tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, máa sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. (Sm. 86:3; 88:1) Máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ó sì máa gbọ́ àdúrà ẹ.—Lúùkù 11:9-13.

13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín nìṣó? (Éfésù 3:16)

13 Ṣé o ní ìṣòro kan tó ń mú kó o rẹ̀wẹ̀sì? Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa sìn ín nìṣó. (Ka Éfésù 3:16.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Flora. Òun àti ọkọ ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, àmọ́ ọkọ ẹ̀ dalẹ̀ ẹ̀, wọ́n sì jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún ara wọn. Arábìnrin Flora sọ pé: “Ọkàn mi gbọgbẹ́ gan-an nítorí ohun tó ṣe, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Mo bẹ Jèhófà pé kó fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kí n lè máa fara dà á nìṣó. Níbẹ̀rẹ̀, mo rò pé mi ò ní lè fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, àmọ́ Jèhófà tù mí nínú, ó sì jẹ́ kí n máa sìn ín nìṣó.” Flora gbà pé Ọlọ́run ti ran òun lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì dá a lójú pé ó máa gba òun sílẹ̀ tóun bá tún níṣòro. Ó wá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 119:32 jẹ́ kí n rí bí Jèhófà ṣe ràn mí lọ́wọ́, ó sọ pé: ‘Màá yára rìn ní ọ̀nà àwọn àṣẹ rẹ, torí pé o ti wá àyè fún un nínú ọkàn mi.’”

14. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe táá jẹ́ kó o túbọ̀ ní ẹ̀mí Ọlọ́run?

14 Kí ló yẹ kó o ṣe lẹ́yìn tó o gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀? Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ ní ẹ̀mí Ọlọ́run. Ara ẹ̀ ni pé kó o máa lọ sípàdé déédéé, kó o sì máa wàásù fáwọn èèyàn. Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ kó o lè máa ronú bí Jèhófà ṣe ń ronú. (Fílí. 4:8, 9) Bó o ṣe ń ka Bíbélì, máa kíyè sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó níṣòro, kó o sì ṣàṣàrò nípa bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Ojú Sandra tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú rí màbo torí pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ní. Ó sọ pé: “Ìtàn Jósẹ́fù ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Kò jẹ́ kí ìṣòro tó ní àti bí wọ́n ṣe rẹ́ ẹ jẹ ba àjọṣe òun àti Jèhófà jẹ́.”—Jẹ́n. 39:21-23.

JÈHÓFÀ MÁA Ń LO ÀWỌN ARÁ LÁTI TÙ WÁ NÍNÚ

15. Àwọn wo ló lè tù wá nínú, báwo ni wọ́n sì ṣe lè ṣe é? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Tá a bá ń jìyà, “orísun ìtùnú” làwọn ará máa ń jẹ́ fún wa. (Kól. 4:11) Bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe láti tù wá nínú ni pé wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa, wọ́n sì máa ń wà pẹ̀lú wa. Wọ́n lè ka ẹsẹ Bíbélì kan tó máa tù wá nínú, wọ́n sì lè gbàdúrà pẹ̀lú wa. d (Róòmù 15:4) Nígbà míì, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè rán wa létí ohun tí Jèhófà fẹ́, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa fara dà á nìṣó. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará wa máa ń pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tá a nílò lásìkò ìṣòro.

Àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n ṣeé fọkàn tán máa ń tù wá nínú, wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 15)


16. Kí ló yẹ ká ṣe káwọn ará lè ràn wá lọ́wọ́?

16 Nígbà míì, ó lè gba pé ká sọ fáwọn ará pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, wọ́n sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 17:17) Àmọ́, wọ́n lè má mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa àtohun tá a fẹ́ kí wọ́n ṣe fún wa. (Òwe 14:10) Tí ohun kan bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, sọ fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán. Jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. O lè sọ fún alàgbà kan tàbí méjì tó sún mọ́ ẹ jù lọ. Àwọn arábìnrin kan ti rí i pé ara máa ń tù wọ́n tí wọ́n bá sọ ohun tó ń ṣe wọ́n fún arábìnrin míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.

17. Kí ló lè mú ká má rí ìṣírí gbà, kí la sì lè ṣe láti borí ẹ̀?

17 Má ṣe ya ara ẹ sọ́tọ̀, máa wà pẹ̀lú àwọn ará. Tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o má bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀. Nígbà míì, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lè má mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, wọ́n sì lè sọ ohun tó máa dùn ẹ́. (Jém. 3:2) Má ṣe jẹ́ káwọn nǹkan yẹn mú kó o máa yẹra fún wọn. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Gavin, tó ní ìdààmú ọkàn sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í wù mí kí n bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ tàbí kí n bá wọn ṣe nǹkan.” Síbẹ̀, Gavin ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti máa wà pẹ̀lú àwọn ará, ó sì ṣe é láǹfààní gan-an. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Amy sọ pé: “Nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi, ó máa ń nira fún mi láti fọkàn tán àwọn èèyàn. Àmọ́ mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ó fọkàn tán wọn, ó sì yẹ kémi náà ṣe bẹ́ẹ̀. Mo mọ̀ pé ìyẹn ń múnú Jèhófà dùn, ó sì ń múnú èmi náà dùn.”

JẸ́ KÁWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ ṢÈLÉRÍ MÁA TÙ Ẹ́ NÍNÚ

18. Kí là ń retí lọ́jọ́ iwájú, kí la sì lè ṣe báyìí?

18 Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí gbogbo àìsàn àti ìṣòro tó ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún wa. (Ìfi. 21:3, 4) Tó bá dìgbà yẹn, àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa ò ní “wá sí ọkàn” mọ́. (Àìsá. 65:17) A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa ‘ń di egbò wa,’ kódà ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí. Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ nǹkan táá mára tù ẹ́, torí náà jẹ́ kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa ‘bójú tó ẹ.’—1 Pét. 5:7.

ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Wo àpótí náà “ Jèhófà Mọyì .”

c Tá a bá fẹ́ “yanjú ọ̀rọ̀” láàárín àwa àti Jèhófà, ó yẹ ká fi hàn pé a ti ronú pìwà dà, ká sọ pé kó dárí jì wá, ká má sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó tún yẹ ká lọ bá àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́.—Jém. 5:14, 15.

d Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ẹṣẹ Bíbélì tá a tò sísàlẹ̀ àkòrí náà “Àníyàn” àti “Ìtùnú” nínú ìwé náà, Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́.