Ìlànà Bíbélì Wúlò Títí Láé
ÀPẸẸRẸ KAN RÈÉ: Ká sọ pé o lọ sí ilé tí wọ́n ń kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n kó síbẹ̀ ti níhò lára, wọ́n ti gbó, àwọn kan sì ti bà jẹ́ tán. Àwọn apá kan lára wọn tún ti sọnù. Àmọ́, ọ̀kan wà lára wọn tí kò sí nǹkan kan tó ṣe é; gbogbo nǹkan tó wà lára rẹ̀ ṣì wà bí wọ́n ṣe ṣe é. O wá bi ẹni tó ń mú ẹ rìn yíká ibẹ̀ pé: “Ṣé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe eléyìí ni tó fi yàtọ̀ sí àwọn tó kù?” Ẹni náà dáhùn pé: “Rárá o! Kódà òun ló ti wà ṣáájú àwọn tó kù, wọ́n ò sì tíì tún un ṣe látìgbà tí wọ́n ti ṣe é.” O wá bi ẹni náà pé: “Ṣé wọ́n tọ́jú ẹ̀ pa mọ́ síbì kan ni?” Ó ní: “Rárá, òun gan-an ni òjò àti oòrùn ti pa jù lọ lára wọn. Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyànkéèyàn tiẹ̀ ti ń wá bí wọ́n ṣe máa bà á jẹ́.” Ó wá ń yà ẹ́ lẹ́nu pé, ‘Kí tiẹ̀ ni wọ́n fi ṣe é ná?’
Bíbélì ló dà bí nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yẹn. Ìwé tó ti wà tipẹ́ ni, òun sì ni ìwé tó pẹ́ jù lọ láyé. Lóòótọ́, àwọn ìwé àtijọ́ míì náà wà. Ṣùgbọ́n bíi tàwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tó ti bàjẹ́ tán yẹn, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé àfọwọ́kọ ló ti bàjẹ́ tán torí pé wọ́n ti pẹ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí wọ́n sọ nípa sáyẹ́ǹsì nígbà yẹn ti yàtọ̀ sí òye tuntun àtàwọn ẹ̀rí tó dájú tó wà báyìí. Ohun tí wọ́n sọ nípa ìlera ti wá léwu gan-an láti tẹ̀ lé báyìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé àtijọ́ kan ṣì wà lẹ́yọ-ẹyọ bí wọ́n ṣe kọ wọ́n; àwọn apá kan lára wọn sì ti sọnù tàbí kí wọ́n ti bà jẹ́ gan-an.
Àmọ́, Bíbélì yàtọ̀ ní tiẹ̀. Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn tí wọ́n ti kọ ọ́, síbẹ̀ kò sí nǹkan kan tó ṣe é. Àwọn kan ti gbìyànjú gan-an láti pa Bíbélì run, wọ́n dáná sun ún, wọ́n fòfin dè é, wọ́n sì ní kì í ṣe ìwé gidi. Síbẹ̀ àwọn ohun tí Bíbélì sọ kò yí pa dà. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ń lóye àwọn nǹkan tuntun, àmọ́ ìyẹn ò sọ Bíbélì di ìwé tí kò bóde mu mọ́, torí pé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Wo àpótí tí àkòrí Ṣé Bíbélì Bá Àkókò Wa Mu Àbí Kò Wúlò Mọ́ Rárá?”
rẹ̀ jẹ́ “ÀWỌN ÌLÀNÀ ÌWÀ RERE TÁ A NÍLÒ LÓDE ÒNÍ
O lè máa ronú pé, ‘Ṣé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣì wúlò nínú ayé ọ̀làjú tá à ń gbé báyìí?’ Láti rí ìdáhùn, bi ara rẹ pé: ‘Ìṣòro wo ló burú jù lọ táwọn èèyàn ń dojú kọ lóde òní? Èwo ló ń bani lẹ́rù jù lọ?’ Ó ṣeé ṣe kó o ronú kan ogun, bíba àyíká jẹ́, ìwà ọ̀daràn tàbí kíkó owó jẹ. Ní báyìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlànà díẹ̀ látinú Bíbélì. Bó o ṣe ń ronú lórí wọn, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ayé yìí máa dáa ju báyìí lọ táwọn èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí?’
JẸ́ ÈÈYÀN ÀLÁÁFÍÀ
“Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run.” (Mátíù 5:9) “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
JẸ́ ALÁÀÁNÚ, MÁA DÁRÍ JINI
“Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mátíù 5:7) “Ẹ máa bá a lọ ní fífara dàá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà * ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.
KÍ GBOGBO Ẹ̀YÀ WÀ NÍṢỌ̀KAN
“Láti ara ọkùnrin kan ni [Ọlọ́run] sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:26) “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
TÍTÚN ILẸ̀ AYÉ ṢE
“Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Ọlọ́run máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.
YẸRA FÚN OJÚKÒKÒRÒ ÀTI ÌṢEKÚṢE
‘Ẹ máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.’ (Lúùkù 12:15) “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.”—Éfésù 5:3.
JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ ÀTI ÒṢÌṢẸ́ KÁRA
“A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára.”—Éfésù 4:28.
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ LÁTI MÁA RAN ÀWỌN ALÁÌNÍ LỌ́WỌ́
“Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) “Máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.”—Jákọ́bù 1:27.
Kì í ṣe pé Bíbélì kàn mẹ́nu ba àwọn ìlànà ìwà rere yẹn. Ó tún kọ́ wa bá a ṣe lè fọwọ́ pàtàkì mú wọn àti bá a ṣe lè máa fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Tí èèyàn púpọ̀ sí i bá ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí
ṣèwà hù, ṣé ìyẹn kò ní jẹ́ kí ìṣòro tó burú jù lọ táwa èèyàn ń dojú kọ dín kù? Torí náà, àwọn ìlànà Bíbélì ṣì bóde mu gan-an, bíi ti ìgbà tí wọ́n kọ ọ́! Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí?BÍ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ṢE LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ BÁYÌÍ
Ọkùnrin kan tó gbọ́n jù lọ láyé sọ pé: “A fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Mátíù 11:19) Ṣéwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá ẹnì kan gbọ́n, àfi kẹ́ni náà máa hùwà ọgbọ́n. Torí náà, o lè máa ronú pé, ‘Tí Bíbélì bá wúlò tóyẹn lóòótọ́, ṣé kò yẹ kó ran èmi náà lọ́wọ́ nígbèésí ayé mi? Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tí mo ní?’ Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
Nǹkan ń lọ dáadáa fún Delphine, * ó sì níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́. Àmọ́, nǹkan yí pa dà fún un lójijì, ó sì pàdánù ọ̀pọ̀ nǹkan. Ọmọbìnrin rẹ̀ ló kọ́kọ́ kú. Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ fi í sílẹ̀. Iṣẹ́ tún bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀, owó ò sì wọlé fún un dáadáa mọ́. Ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan dojú rú fún mi, kò sọ́mọ mọ́, kò sí ọkọ, kò tún sílé. Ó dà bí i pé mo kàn ń gbáyé lásán ni, mi ò sì nírètí kankan.”
Delphine wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, Síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun Sáàmù 90:10.
aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.”—Bíbélì ran Delphine lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan nira fún un yìí. Ara sì tù ú gan-an. Bí a ṣe máa rí i nínú àwọn àpilẹ̀kọ mẹ́ta tó kù, ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé Bíbélì ti ran àwọn lọ́wọ́ lọ́nà tó pọ̀ gan-an nígbà táwọn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ lásìkò ìṣòro. Wọ́n ti rí i pé ńṣe ni Bíbélì dà bí ohun ìṣẹ̀ǹbáyé irú èyí tá a fi ṣàpèjúwe níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Kò dà bí ọ̀pọ̀ ìwé tó máa ń gbó tí kì í sì í bóde mu mọ́. Ṣé torí pé ohun èlò kan tó yàtọ̀ ni wọ́n fi ṣe Bíbélì ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, kì í ṣe ti àwa èèyàn lásán?—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti rí i pé ẹ̀mí àwa èèyàn kì í gùn, a sì máa ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Tó o bá ní ìṣòro tó ń bá ẹ fínra, ọ̀dọ̀ ta lo máa ń lọ kó o lè rí ìtùnú, ìrànlọ́wọ́ àti ìmọ̀ràn tó wúlò?
Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà mẹ́ta tí Bíbélì lè gbà ṣe ẹ́ láǹfààní nígbèésí ayé rẹ. Ó máa kọ́ ẹ bó o ṣe lè
-
yẹra fún ìṣòro tó bá ṣeé ṣe.
-
yanjú wàhálà nígbà tó bá wáyé.
-
fara da àwọn ipò nǹkan tí kò ṣeé yí pa dà.
A máa sọ̀rọ̀ lórí kókó mẹ́ta yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kù.
^ ìpínrọ̀ 10 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.
^ ìpínrọ̀ 24 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn mẹ́ta tó tẹ̀ lé e.