Kí Nìdí Tí Ìkórìíra Fi Pọ̀ Láyé?
Kí nìdí tọ́pọ̀ èèyàn fi lẹ́mìí ìkórìíra káàkiri ayé? Ká lè rí ìdáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí ìkórìíra jẹ́, bí ìkórìíra ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ àti bó ṣe máa ń tàn káàkiri.
Kí Ni Ìkórìíra?
Ìkórìíra túmọ̀ sí pé kínú máa bí ẹnì kan gan-an sáwọn ẹ̀yà kan tàbí àwùjọ èèyàn kan débi pé kò ní fẹ́ gbọ́ ohunkóhun nípa wọn, kò ní fẹ́ rí wọn, kò sì ní fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú wọn rárá.
BÁWO NI ÌKÓRÌÍRA ṢE MÁA Ń BẸ̀RẸ̀?
Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń mú káwọn èèyàn lẹ́mìí ìkórìíra. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé kì í ṣohun tẹ́nì kan ṣe ló mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀, àmọ́ ohun tó mú kí wọ́n kórìíra ẹ̀ ni ìlú tàbí ẹ̀yà tó ti wá. Wọ́n lè ka àwọn tó wá láti ìlú tàbí ẹ̀yà náà sí èèyàn burúkú tàbí èèyàn eléwu tí ò lè yíwà pa dá. Wọ́n tún lè máa wò wọ́n bí ẹni tí kò yẹ láwùjọ tàbí ẹni tó máa ń dá wàhálà sílẹ̀. Nígbà míì sì rèé, ohun tójú àwọn kan ti rí báwọn èèyàn ṣe kórìíra wọn ti mú káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ìkà sáwọn míì.
BÁWO NI ÌKÓRÌÍRA ṢE MÁA Ń TÀN KÁÀKIRI?
Nígbà míì, àwọn kan máa ń kórìíra àwọn tí wọn ò tiẹ̀ rí rí. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ohun tí kò dáa tí tẹbí-tọ̀rẹ́ ń sọ nípa àwọn ẹ̀yà kan tàbí àwọn ará ìlú kan lẹnì kan gbà gbọ́ tóun náà sì wá kórìíra wọn. Bí ìkórìíra ṣe máa ń tàn kálẹ̀ nìyẹn, tí wọ́n á sì máa fojú èèyàn burúkú wo gbogbo àwọn ará ìlú tàbí ẹ̀yà kan.
Ní báyìí tá a ti mọ bí ìkórìíra ṣe máa ń yára tàn kálẹ̀, a lè wá rí ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń kórìíra àwọn míì. Tá a bá fẹ́ kí ìkórìíra tán pátápátá láyé, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ bí ẹ̀mí ìkórìíra ṣe wọ ayé. Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ìkórìíra ṣe bẹ̀rẹ̀.
BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ BÍ ÌKÓRÌÍRA ṢE BẸ̀RẸ̀
Ọ̀DỌ̀ ÀWA ÈÈYÀN KỌ́ NI ÌKÓRÌÍRA TI BẸ̀RẸ̀. Ìkórìíra bẹ̀rẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì kan ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Áńgẹ́lì yẹn la wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù. “Apààyàn ni . . . nígbà tó bẹ̀rẹ̀” ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀. “Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́,” torí náà ó ṣì n bá a nìṣó láti mú káwọn èèyàn máa kórìíra ara wọn, kí wọ́n sì máa bínú síra wọn burúkú burúkú. (Jòhánù 8:44; 1 Jòhánù 3:11, 12) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni ibi ni Sátánì, ó máa ń bínú gan-an, ìkà ni, ó sì jẹ́ ọ̀dájú.—Jóòbù 2:7; Ìfihàn 12:9, 12, 17.
ÀÌPÉ ÀTI Ẹ̀ṢẸ̀ LÓ MÚ KÁWỌN ÈÈYÀN LẸ́MÌÍ ÌKÓRÌÍRA. Àpẹẹrẹ Sátánì ni Ádámù ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ tẹ̀ lé. Bó ṣe di pé gbogbo èèyàn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé nìyẹn. (Róòmù 5:12) Ẹ̀mí ìkórìíra ló mú kí Kéènì tó jẹ́ àkọ́bí Ádámù pa Ébẹ́lì àbúrò ẹ̀. (1 Jòhánù 3:12) Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì wà lónìí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, tí wọ́n sì jẹ́ olójú àánú. Àmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, àìmọye èèyàn ló jẹ́ onímọ-tara-ẹni-nìkan, onílara àti agbéraga.—2 Tímótì 3:1-5.
Ẹ̀TANÚ Ń MÚ KÍ ÌKÓRÌÍRA GBILẸ̀. Onírúurú ìwà burúkú ló kún ọwọ́ àwọn èèyàn láyé yìí, èyí sì túbọ̀ ń jẹ́ kí ẹ̀mí ìkórìíra máa gbilẹ̀. Lára àwọn ìwà burúkú náà ni ìwà ọ̀dájú, ẹ̀tanú, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ọ̀rọ̀ àbùkù àti ìwà ọ̀daràn. Ohun tó sì fà á ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù.—1 Jòhánù 5:19.
Àmọ́, ohun tó ń fa ìkórìíra nìkan kọ́ ni Bíbélì sọ fún wa, ó tún sọ ohun tó máa yanjú ìṣòro náà.