Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe Ọdún Kérésìmesì?
Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé ló gbà pé ọdún Kérésìmesì jẹ́ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù Kristi. Àmọ́, ṣé o ti ronú nípa bóyá àwọn Kristẹni ìjímìjí tí wọ́n tiẹ̀ sún mọ́ Jésù dáadáa náà ṣayẹyẹ ọdún Kérésìmesì? Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ìbí? Tá a bá wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, ó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣayẹyẹ Kérésìmesì.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kò síbi kankan nínú Bíbélì tó sọ pé Jésù tàbí àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ míì ṣe ọjọ́ ìbí wọn. Àwọn méjì péré ni Bíbélì sọ nípa wọn pé wọ́n ṣe ọjọ́ ìbí. Àmọ́ àwọn méjèèjì kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà Ọlọ́run tó ṣe Bíbélì, nǹkan burúkú sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20; Máàkù 6:21) Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé, àwọn Kristẹni ìjímìjí gbà pé “àṣà ìbọ̀rìṣà ni ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí” jẹ́, wọn ò sì fara mọ́ ọn.
Ọjọ́ wo gan-an ni wọ́n bí Jésù?
Bíbélì ò sọ ọjọ́ náà pàtó tí wọ́n bí Jésù. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà tí McClintock àti Strong ṣe sọ pé: “Ọjọ́ tí wọ́n bí Kristi kò sí nínú Májẹ̀mú Tuntun, ó dájú pé kò sí àkọsílẹ̀ rẹ̀ níbì kankan.” Ó sì dájú pé tí Jésù bá fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, á ti rí i dájú pé wọ́n mọ ọjọ́ tí wọ́n bí òun.
Ìkejì ni pé kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jésù tàbí ìkankan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ọdún Kérésìmesì. Bí àpẹẹrẹ, ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé, “inú ìwé Chronograph tí Philocalus ṣe” ni wọ́n ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan ọdún Kérésìmesì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọdún 336 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe ìwé náà, ó sì jẹ́ ìwé ọdọọdún àwọn ará Róòmù. Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Bíbélì ni wọ́n ṣe ìwé yìí, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù ti kúrò láyé. Èyí ló mú kí McClintock àti Strong sọ pé “Ọlọ́run ò fọwọ́ sí ṣíṣe ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì, kò sì sí nínú Májẹ̀mú Tuntun.” *
Kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí?
Jésù tó jẹ́ Olùkọ́ Ńlá sọ ohun tó fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe, gbogbo rẹ̀ ló sì wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ṣíṣe ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì kò sí lára wọn. Bó ṣe jẹ́ pé olùkọ́ kan ò ní fẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe ju ìtọ́ni tó bá fún wọn lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jésù kò ṣe fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ” nínú Ìwé Mímọ́.—1 Kọ́ríńtì 4:6.
Lọ́wọ́ kejì, ohun pàtàkì kan wà táwọn Kristẹni ìjímìjí mọ̀ dáadáa, ìyẹn ni ṣíṣe Ìrántí Ikú Jésù. Jésù fúnra rẹ̀ sọ ìgbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ á máa ṣe é àti bí wọ́n á ṣe máa ṣe é. Ìtọ́ni tó fún wọn yìí àti ọjọ́ náà gan-an tó kú wà ní àkọ́sílẹ̀ nínú Bíbélì.—Lúùkù 22:19; 1 Kọ́ríńtì 11:25.
Bá a ṣe ti rí i, ayẹyẹ ọjọ́ ìbí làwọn tó ń ṣe ọdún Kérésìmesì ń ṣe, àwọn Kristẹni ìjímìjí kò sì lọ́wọ́ sí àṣà ìbọ̀rìṣà yẹn. Síwájú sí i, kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó sọ pé Jésù tàbí ẹnì kankan ṣe ọdún Kérésìmesì. Fún àwọn ìdí yìí, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn Kristẹni kárí ayé ti pinnu pé àwọn kò ní lọ́wọ́ sí ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì ní tàwọn.
^ ìpínrọ̀ 6 Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ibi tí àṣà Kérésìmesì ti wá, wo àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . . Kí Lohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ọdún Kérésì?” nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2014, ó tún wà lórí ìkànnì www.mr1310.com/yo.